Ẹ̀KỌ́ 31
Jóṣúà àti Àwọn Ará Gíbíónì
Gbogbo ìlú tó kù ní Kénáánì ló gbọ́ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Jẹ́ríkò. Àwọn ọba ìlú tó kù wá sọ pé àwọn jọ máa bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jà. Ṣùgbọ́n àwọn ará Gíbíónì ṣe ohun tó yàtọ̀ sí tàwọn tó kù. Wọ́n wọ aṣọ tó ti gbó lọ sọ́dọ̀ Jóṣúà, wọ́n ní: ‘Ọ̀nà jíjìn la ti wá. A ti gbọ́ nípa Jèhófà àti gbogbo ohun tó ṣe fún yín ní Íjíbítì àti ní Móábù. A fẹ́ kẹ́ ẹ ṣèlérí fún wa pé ẹ ò ní bá wa jagun, àá sì di ìránṣẹ́ yín.’
Jóṣúà gba ohun tí wọ́n sọ, ó sì ṣèlérí fún wọn. Àmọ́, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, ó gbọ́ pé irọ́ làwọn èèyàn náà pa fóun. Àṣé ilẹ̀ Kénáánì tó wà nítòsí ni wọ́n ti wá. Jóṣúà wá béèrè lọ́wọ́ àwọn ará Gíbíónì yìí pé: ‘Kí ló dé tẹ́ ẹ fi parọ́ fún wa?’ Wọ́n dáhùn pé: ‘Ẹ̀rù ló bà wá! A mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run yín ń jà fún yín. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ má pa wá.’ Torí ìlérí tí Jóṣúà ti ṣe fún wọn tẹ́lẹ̀, kò pa wọ́n.
Kò pẹ́ sígbà yẹn làwọn ọba Kénáánì márùn-ún àtàwọn ọmọ ogun wọn wá halẹ̀ mọ́ àwọn ará Gíbíónì. Jóṣúà àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ sì lọ dáàbò bo àwọn ará Gíbíónì. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìjà ní kùtùkùtù àárọ̀ ọjọ́ kejì. Báwọn ará Kénáánì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ nìyẹn. Gbogbo ibi tí wọ́n ń sá gbà ni Jèhófà ti ń rọ yìnyín tó dà bí òkúta lé wọn lórí. Lẹ́yìn ìyẹn, Jóṣúà gbàdúrà pé kí Jèhófà mú kí oòrùn dúró sójú kan. Kí nìdí tó fi ní kí Jèhófà ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí oòrùn ò dúró sójú kan rí? Ìdí ni pé ó dá a lójú pé kò sóhun tí Jèhófà ò lè ṣe. Oòrùn sì dúró fún odindi ọjọ́ kan gbáko títí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ṣẹ́gun àwọn ọba Kénáánì àtàwọn ọmọ ogun wọn.
“Kí ọ̀rọ̀ yín, ‘Bẹ́ẹ̀ ni’ jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, kí ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́’ yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́, torí ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà ni ohun tó bá ju èyí lọ ti wá.”—Mátíù 5:37