ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • my ìtàn 49
  • Oòrùn Dúró Sójú Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Oòrùn Dúró Sójú Kan
  • Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jóṣúà àti Àwọn Ará Gíbíónì
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Jóṣúà 1:9—“Jẹ́ Onígboyà àti Alágbára”
    Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
  • Ohun Tí Jóṣúà Rántí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ó Fẹ́ Ká Ṣàṣeyọrí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Ìwé Ìtàn Bíbélì
my ìtàn 49
Jóṣúà sọ fún oòrùn pé kó dúró sójú kan

ÌTÀN 49

Oòrùn Dúró Sójú Kan

WO JÓṢÚÀ. Ohun tó ń sọ ni pé: ‘Ìwọ oòrùn, dúró sójú kan!’ Oòrùn náà sì dúró sójú kan lóòótọ́. Ó dúró sójú kan níbẹ̀ ní agbedeméjì òfuurufú fún odidi ọjọ́ kan gbáko. Jèhófà ló mú kó ṣẹlẹ̀! Ṣùgbọ́n jẹ́ ká wo ìdí ẹ̀ tí Jóṣúà fi fẹ́ kí oòrùn sáà máa ràn.

Nígbà tí àwọn ọba búburú márùn-ún ilẹ̀ Kénáánì náà bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ará Gíbéónì jagun, àwọn ará Gíbéónì rán ọkùnrin kan sí Jóṣúà pé kó wá ran àwọn lọ́wọ́. Ó wí pé: ‘Yára wá sọ́dọ̀ wa kíákíá. Gbà wá o! Gbogbo àwọn ọba tó wà ní ìhà òkè ti sọ̀ kalẹ̀ wá láti bá àwa ìránṣẹ́ rẹ jà o.’

Ojú ẹsẹ̀ ni Jóṣúà àti gbogbo àwọn jagunjagun rẹ̀ lọ. Gbogbo òru náà ni wọ́n fi rìn. Nígbà tí wọ́n dé Gíbéónì, ẹ̀rù ba gbogbo jagunjagun àwọn ọba márààrún náà wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ. Ìgbà náà ni Jèhófà mú kí òjò yìnyín ńlá rọ̀ láti òfuurufú, iye àwọn jagunjagun tó kú bí yìnyín ńlá ṣe ń já lù wọ́n náà pọ̀ ju iye tí àwọn jagunjagun Jóṣúà pa lọ.

Jóṣúà rí i pé oòrùn ò ní pẹ́ wọ̀. Ilẹ̀ á ṣú, púpọ̀ nínú jagunjagun àwọn ọba búburú márùn-ún yẹn ló sì máa sá lọ. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí Jóṣúà fi gbàdúrà sí Jèhófà, tó wá sọ pé: ‘Ìwọ oòrùn, dúró sójú kan!’ Bí oòrùn sì ṣe ń ràn láìwọ̀, ó ṣeé ṣe fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti ṣẹ́gun pátápátá.

Àwọn ọba búburú púpọ̀ ló ṣì kù ní ilẹ̀ Kénáánì tí wọ́n kórìíra àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ó gba Jóṣúà àti ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ ní nǹkan bí ọdún mẹ́fà láti ṣẹ́gun àwọn ọba mọ́kànlélọ́gbọ̀n [31] ní ilẹ̀ náà. Nígbà tí wọ́n ṣẹ́gun wọn tán, Jóṣúà rí sí i pé òun pín ilẹ̀ Kénáánì fún àwọn ẹ̀yà tí kò tíì ní ìpínlẹ̀.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún kọjá, nígbà tó yá, Jóṣúà kú ní ẹni àádọ́fà [110] ọdún. Ní gbogbo àkókò tí òun àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ fi wà láàyè, àwọn èèyàn náà ṣe ìgbọràn sí Jèhófà. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ẹni rere wọ̀nyí kú, àwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó burú wọ́n sì kó sínú ìjàngbọ̀n. Ìgbà yìí ni wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run lójú méjèèjì.

Jóṣúà 10:6-15; 12:7-24; 14:1-5; Àwọn Onídàájọ́ 2:8-13.

Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́