Ẹ̀KỌ́ 33
Rúùtù àti Náómì
Nígbà kan tí kò sí oúnjẹ nílẹ̀ Ísírẹ́lì, ọmọ Ísírẹ́lì kan tó ń jẹ́ Náómì kó lọ sílẹ̀ Móábù. Òun àti ọkọ ẹ̀ àtàwọn ọmọkùnrin ẹ̀ méjì ni wọ́n jọ lọ. Nígbà tó yá, ọkọ Náómì kú. Àwọn ọmọ ẹ̀ sì fẹ́ Rúùtù àti Ópà tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Móábù. Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ọmọ Náómì méjèèjì náà kú.
Nígbà tí Náómì gbọ́ pé oúnjẹ ti wà nílẹ̀ Ísírẹ́lì, ó pinnu pé òun máa pa dà sílé. Rúùtù àti Ópà sì tẹ̀ lé e, àmọ́ bí wọ́n ṣe ń lọ, Náómì sọ fún wọn pé: ‘Ìyàwó dáadáa lẹ jẹ́ fáwọn ọmọ mi, ẹ sì ṣe dáadáa sí èmi náà. Mo fẹ́ kẹ́yin méjèèjì tún pa dà lọ́kọ. Torí náà, ẹ pa dà sí Móábù.’ Àwọn obìnrin náà sọ pé: ‘Màmá, a fẹ́ràn yín gan-an! A ò fẹ́ fi yín sílẹ̀.’ Àmọ́, Náómì ń sọ fún wọn ṣáá pé kí wọ́n pa dà. Nígbà tó yá, Ópà pa dà, ó sì ku Rúùtù nìkan. Náómì wá sọ fún un pé: ‘Ópà ti ń pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn ẹ̀ àti ọlọ́run ẹ̀. Máa tẹ̀ lé e lọ, kó o sì pa dà sílé ìyá ẹ.’ Àmọ́ Rúùtù sọ pé: ‘Mi ò ní pa dà lẹ́yìn yín. Àwọn èèyàn yín á di èèyàn mi, Ọlọ́run yín á sì di Ọlọ́run mi.’ Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára Náómì nígbà tí Rúùtù sọ̀rọ̀ yìí?
Àkókò tí wọ́n ń kórè ọkà báálì ni Rúùtù àti Náómì dé Ísírẹ́lì. Lọ́jọ́ kan, Rúùtù lọ sóko ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Bóásì kó lè lọ kó àwọn ọkà tó já bọ́ nígbà tí wọ́n ń kórè. Ọmọ Ráhábù ni Bóásì, ó gbọ́ pé ọmọ ilẹ̀ Móábù ni Rúùtù àti pé fúnra ẹ̀ ló pinnu láti dúró ti ìyá ọkọ ẹ̀. Ó wá sọ fáwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ pé kí wọ́n máa ṣẹ́ ọkà kù fún Rúùtù kó lè rí kó lọ sílé.
Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, Náómì bi Rúùtù pé: ‘Inú oko ta lo ti ṣiṣẹ́ lónìí?’ Rúùtù sọ pé: ‘Oko ọkùnrin kan tí wọ́n ń pè ní Bóásì ni.’ Náómì wá sọ fún un pé: ‘Ìbátan ọkọ mi ni Bóásì. Máa ṣiṣẹ́ lóko ẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́bìnrin tó ń bá a ṣiṣẹ́. Kò sí nǹkan tó máa ṣe ẹ́.’
Oko Bóásì ni Rúùtù ti ṣiṣẹ́ títí tí àkókò ìkórè náà fi kọjá. Bóásì kíyè sí i pé Rúùtù ń ṣiṣẹ́ kára, ó sì ní ìwà tó dáa. Lákòókò yẹn, tí ọkùnrin kan bá kú, tí kò sì ní ọmọkùnrin, ìbátan ẹ̀ ló máa fẹ́ ìyàwó tó fi sílẹ̀. Torí náà, Bóásì fẹ́ Rúùtù. Wọ́n sì bí ọmọkùnrin kan tí wọ́n sọ ní Óbédì. Óbédì ló wá di bàbá bàbá Ọba Dáfídì. Inú àwọn ọ̀rẹ́ Náómì dùn. Wọ́n sọ pé: ‘Jèhófà kọ́kọ́ fún ẹ ní Rúùtù, tó ń tọ́jú ẹ, ní báyìí, ó ti fún ẹ ní ọmọ ọmọ. A yin Jèhófà lógo.’
“Ọ̀rẹ́ kan wà tó ń fà mọ́ni ju ọmọ ìyá lọ.”—Òwe 18:24