Ẹ̀KỌ́ 38
Jèhófà Sọ Sámúsìn Di Alágbára
Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í bọ òrìṣà. Torí náà, Jèhófà gba àwọn Filísínì láyè láti máa ṣàkóso ilẹ̀ wọn. Àmọ́ àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ọ̀kan lára wọn ni Mánóà. Òun àti ìyàwó ẹ̀ ò rọ́mọ bí. Lọ́jọ́ kan, Jèhófà rán áńgẹ́lì kan sí ìyàwó Mánóà. Áńgẹ́lì náà sọ fún un pé: ‘O máa bí ọmọkùnrin kan. Òun ló máa gba Ísírẹ́lì lọ́wọ́ àwọn Filísínì. Násírì ló sì máa jẹ́.’ Ṣé o mọ àwọn tí wọ́n ń pè ní Násírì? Àwọn ni wọ́n máa ń ṣe iṣẹ́ pàtàkì fún Jèhófà. Wọn ò sì gbọ́dọ̀ gé irun orí wọn.
Nígbà tí wọ́n bí ọmọ náà, Mánóà sọ ọ́ ní Sámúsìn. Nígbà tí Sámúsìn dàgbà, Jèhófà sọ ọ́ di alágbára. Sámúsìn lè fi ọwọ́ lásán pa kìnnìún. Ọjọ́ kan tiẹ̀ wà tó nìkan pa ọgbọ̀n (30) lára àwọn Filísínì. Àwọn Filísínì kórìíra ẹ̀ gan-an, wọ́n sì ń wá bí wọ́n ṣe máa pa á. Lálẹ́ ọjọ́ kan tí Sámúsìn lọ sùn sílùú Gásà, àwọn Filísínì lọ dúró dè é sí ẹnubodè ìlú náà kí wọ́n lè pa á tílẹ̀ bá mọ́. Àmọ́ láàárín òru, Sámúsìn dìde lọ sí ẹnubodè ìlú náà, ó fa géètì ẹ̀ yọ lára ògiri. Ó wá gbé e lé èjìká ẹ̀, ó sì rìn lọ sórí òkè Hébúrónì!
Lọ́jọ́ kan, àwọn Filísínì lọ bá ọ̀rẹ́bìnrin Sámúsìn, tó ń jẹ́ Dẹ̀lílà, wọ́n sọ fún un pé: ‘A máa san owó ńlá fún ẹ tó o bá lè bá wa wádìí ibi tí Sámúsìn ti ń rí agbára ẹ̀. A fẹ́ mú un ká sì jù ú sẹ́wọ̀n.’ Owó yẹn wọ Dẹ̀lílà lójú, ó sì gbà láti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́. Àmọ́, Sámúsìn ò kọ́kọ́ sọ ìdí agbára ẹ̀ fún un. Síbẹ̀ Dẹ̀lílà bẹ Sámúsìn títí tó fi gbà láti sọ fún un. Ó ní: ‘Wọn ò tíì gé irun orí mi rí, torí pé Násírì ni mí. Tí mo bá gé e, mi ò ní lágbára mọ́.’ Ẹ ò rí i pé àṣìṣe ńlá ni Sámúsìn ṣe tó fi sọ ìdí agbára ẹ̀ fún Dẹ̀lílà, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Dẹ̀lílà ti sọ fáwọn Filísínì pé: ‘Mo ti mọ ìdí agbára ẹ̀!’ Dẹ̀lílà mú kí Sámúsìn sùn lórí itan ẹ̀, ẹnì kan sì gé irun orí Sámúsìn. Dẹ̀lílà wá pariwo pé: ‘Sámúsìn, àwọn Filísínì ti dé!’ Sámúsìn fò dìde, àmọ́ kò lágbára mọ́. Àwọn Filísínì wá gbá a mú, wọ́n yọ ojú ẹ̀ méjèèjì, wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n.
Lọ́jọ́ kan, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Filísínì pé jọ sílé òrìṣà wọn, ìyẹn Dágónì. Wọ́n ń kígbe pé: ‘Ọlọ́run wa ti jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ Sámúsìn! Ẹ mú un jáde! Ẹ jẹ́ kó wá ṣeré fún wa.’ Wọ́n mú un dúró sáàárín òpó méjì, wọ́n sì n fi ṣe yẹ̀yẹ́. Sámúsìn wá gbàdúrà pé: ‘Jèhófà, jọ̀ọ́ fún mi lágbára lẹ́ẹ̀kan sí i.’ Lákòókò yìí, irun Sámúsìn ti bẹ̀rẹ̀ sí í gùn. Ó wá fi gbogbo agbára ẹ̀ ti òpó ilé náà. Ilé náà wó lulẹ̀, ó sì pa gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ títí kan Sámúsìn.
“Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.”—Fílípì 4:13