ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àwọn Onídàájọ́ 13
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àwọn Onídàájọ́

      • Áńgẹ́lì kan wá sọ́dọ̀ Mánóà àti ìyàwó rẹ̀ (1-23)

      • Wọ́n bí Sámúsìn (24, 25)

Àwọn Onídàájọ́ 13:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 2:11, 19; 10:6
  • +Joṣ 13:1-3; Ond 10:7

Àwọn Onídàájọ́ 13:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 15:20, 33; 19:41, 48
  • +Jẹ 49:16
  • +Ond 16:31
  • +Jẹ 30:22, 23

Àwọn Onídàájọ́ 13:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 18:10; 1Sa 1:20; Lk 1:11, 13

Àwọn Onídàájọ́ 13:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 6:2, 3; Lk 1:15
  • +Le 11:26, 27

Àwọn Onídàájọ́ 13:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “látinú ilé ọmọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 6:2, 5
  • +Ond 2:16; 13:1; Ne 9:27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ojú ìwé 1708

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2005, ojú ìwé 25

Àwọn Onídàájọ́ 13:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 13:17, 18

Àwọn Onídàájọ́ 13:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “látinú ilé ọmọ.”

Àwọn Onídàájọ́ 13:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2015, ojú ìwé 3

    8/15/2013, ojú ìwé 16

Àwọn Onídàájọ́ 13:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 13:3

Àwọn Onídàájọ́ 13:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 13:8

Àwọn Onídàájọ́ 13:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 13:4

Àwọn Onídàájọ́ 13:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 6:2, 3
  • +Le 11:26, 27

Àwọn Onídàájọ́ 13:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 18:5, 7; Ond 6:18, 19; Heb 13:2

Àwọn Onídàájọ́ 13:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 32:29; Ond 13:6

Àwọn Onídàájọ́ 13:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2013, ojú ìwé 10

Àwọn Onídàájọ́ 13:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 6:22, 23

Àwọn Onídàájọ́ 13:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 33:20; Jo 1:18

Àwọn Onídàájọ́ 13:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 13:16

Àwọn Onídàájọ́ 13:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 11:32

Àwọn Onídàájọ́ 13:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 3:9, 10; 6:34; 11:29; 1Sa 11:6
  • +Ond 18:11, 12
  • +Joṣ 15:20, 33

Àwọn míì

Oníd. 13:1Ond 2:11, 19; 10:6
Oníd. 13:1Joṣ 13:1-3; Ond 10:7
Oníd. 13:2Joṣ 15:20, 33; 19:41, 48
Oníd. 13:2Jẹ 49:16
Oníd. 13:2Ond 16:31
Oníd. 13:2Jẹ 30:22, 23
Oníd. 13:3Jẹ 18:10; 1Sa 1:20; Lk 1:11, 13
Oníd. 13:4Nọ 6:2, 3; Lk 1:15
Oníd. 13:4Le 11:26, 27
Oníd. 13:5Nọ 6:2, 5
Oníd. 13:5Ond 2:16; 13:1; Ne 9:27
Oníd. 13:6Ond 13:17, 18
Oníd. 13:10Ond 13:3
Oníd. 13:12Ond 13:8
Oníd. 13:13Ond 13:4
Oníd. 13:14Nọ 6:2, 3
Oníd. 13:14Le 11:26, 27
Oníd. 13:15Jẹ 18:5, 7; Ond 6:18, 19; Heb 13:2
Oníd. 13:17Jẹ 32:29; Ond 13:6
Oníd. 13:21Ond 6:22, 23
Oníd. 13:22Ẹk 33:20; Jo 1:18
Oníd. 13:23Ond 13:16
Oníd. 13:24Heb 11:32
Oníd. 13:25Ond 3:9, 10; 6:34; 11:29; 1Sa 11:6
Oníd. 13:25Ond 18:11, 12
Oníd. 13:25Joṣ 15:20, 33
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àwọn Onídàájọ́ 13:1-25

Àwọn Onídàájọ́

13 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà,+ Jèhófà sì fi wọ́n lé àwọn Filísínì+ lọ́wọ́ fún ogójì (40) ọdún.

2 Láàárín àkókò yìí, ọkùnrin ará Sórà+ kan wà, ó wá látinú ìdílé àwọn ọmọ Dánì,+ Mánóà+ ni orúkọ rẹ̀. Ìyàwó rẹ̀ yàgàn, kò sì bímọ kankan.+ 3 Nígbà tó yá, áńgẹ́lì Jèhófà fara han obìnrin náà, ó sì sọ fún un pé: “Wò ó, àgàn ni ọ́, o ò bímọ. Àmọ́ o máa lóyún, o sì máa bí ọmọkùnrin kan.+ 4 Rí i pé o ò mu wáìnì tàbí ohunkóhun tó ní ọtí,+ má sì jẹ ohun àìmọ́ kankan.+ 5 Wò ó! O máa lóyún, o sì máa bí ọmọkùnrin kan, abẹ kankan ò gbọ́dọ̀ kàn án lórí,+ torí Násírì Ọlọ́run ni ọmọ náà máa jẹ́ látìgbà tí o bá ti bí i,* òun ló sì máa ṣáájú láti gba Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Filísínì.”+

6 Obìnrin náà wá lọ sọ fún ọkọ rẹ̀ pé: “Èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ kan wá sọ́dọ̀ mi, ó rí bí áńgẹ́lì Ọlọ́run tòótọ́, ó ń bani lẹ́rù gidigidi. Mi ò béèrè ibi tó ti wá lọ́wọ́ rẹ̀, kò sì sọ orúkọ rẹ̀ fún mi.+ 7 Àmọ́ ó sọ fún mi pé, ‘Wò ó! O máa lóyún, o sì máa bí ọmọkùnrin kan. Má mu wáìnì tàbí ohunkóhun tó ní ọtí, má sì jẹ ohun àìmọ́ kankan, torí Násírì Ọlọ́run ni ọmọ náà máa jẹ́ látìgbà tí o bá ti bí i* títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.’”

8 Mánóà bẹ Jèhófà, ó sì sọ pé: “Jọ̀ọ́, Jèhófà. Jẹ́ kí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ tí o ṣẹ̀ṣẹ̀ rán wá tún pa dà wá, kó sọ fún wa ohun tí a máa ṣe nípa ọmọ tí a máa bí.” 9 Ọlọ́run tòótọ́ wá fetí sí Mánóà, áńgẹ́lì Ọlọ́run tòótọ́ sì pa dà wá bá obìnrin náà nígbà tó jókòó sínú oko; Mánóà ọkọ rẹ̀ kò sí lọ́dọ̀ rẹ̀. 10 Obìnrin náà yára sáré lọ sọ fún ọkọ rẹ̀ pé: “Wò ó! Ọkùnrin tó wá bá mi lọ́jọ́sí tún fara hàn mí.”+

11 Mánóà dìde, ó sì tẹ̀ lé ìyàwó rẹ̀. Ó wá bá ọkùnrin náà, ó sì sọ fún un pé: “Ṣé ìwọ ni ọkùnrin tó bá ìyàwó mi sọ̀rọ̀?” Ó fèsì pé: “Èmi ni.” 12 Mánóà bá sọ pé: “Kó rí bí o ṣe sọ! Báwo ni ìgbésí ayé ọmọ náà ṣe máa rí, iṣẹ́ wo ló sì máa ṣe?”+ 13 Áńgẹ́lì Jèhófà dá Mánóà lóhùn pé: “Kí ìyàwó rẹ yẹra fún gbogbo ohun tí mo sọ fún un.+ 14 Kó má jẹ ohunkóhun tó wá látara èso àjàrà, kó má mu wáìnì tàbí ohunkóhun tó ní ọtí,+ kó má sì jẹ ohun àìmọ́ kankan.+ Kó máa tẹ̀ lé gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún un.”

15 Mánóà sọ fún áńgẹ́lì Jèhófà pé: “Jọ̀ọ́, dúró, jẹ́ ká se ọmọ ewúrẹ́ kan fún ọ.”+ 16 Àmọ́ áńgẹ́lì Jèhófà sọ fún Mánóà pé: “Tí mo bá dúró, mi ò ní jẹ oúnjẹ rẹ; àmọ́ tó bá wù ọ́ láti rú ẹbọ sísun sí Jèhófà, o lè rú u.” Mánóà ò mọ̀ pé áńgẹ́lì Jèhófà ni. 17 Mánóà wá sọ fún áńgẹ́lì Jèhófà pé: “Kí ni orúkọ rẹ,+ ká lè bọlá fún ọ tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ?” 18 Àmọ́ áńgẹ́lì Jèhófà sọ fún un pé: “Kí ló dé tí o fi ń béèrè orúkọ mi, nígbà tí o rí i pé àgbàyanu ni?”

19 Mánóà wá mú ọmọ ewúrẹ́ náà àti ọrẹ ọkà, ó sì fi wọ́n rúbọ lórí àpáta sí Jèhófà. Ọkùnrin náà ń ṣe ohun ìyanu kan, bí Mánóà àti ìyàwó rẹ̀ ṣe ń wò ó. 20 Bí ọwọ́ iná náà ṣe ń ròkè lọ sí ọ̀run látorí pẹpẹ, áńgẹ́lì Jèhófà gba inú ọwọ́ iná tó ń jó látorí pẹpẹ náà lọ sókè bí Mánóà àti ìyàwó rẹ̀ ṣe ń wò ó. Wọ́n sì dojú bolẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 21 Áńgẹ́lì Jèhófà ò sì fara han Mánóà àti ìyàwó rẹ̀ mọ́. Ìgbà yẹn ni Mánóà wá mọ̀ pé áńgẹ́lì Jèhófà ni.+ 22 Mánóà wá sọ fún ìyàwó rẹ̀ pé: “Ó dájú pé a máa kú, torí Ọlọ́run ni a rí.”+ 23 Àmọ́ ìyàwó rẹ̀ sọ fún un pé: “Tó bá jẹ́ pé Jèhófà fẹ́ pa wá ni, kò ní gba ẹbọ sísun+ àti ọrẹ ọkà lọ́wọ́ wa, kò ní fi gbogbo nǹkan yìí hàn wá, kò sì ní sọ ìkankan nínú nǹkan wọ̀nyí fún wa.”

24 Lẹ́yìn náà, obìnrin náà bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ ọ́ ní Sámúsìn;+ bí ọmọ náà ṣe ń dàgbà, Jèhófà ń bù kún un. 25 Nígbà tó yá, ẹ̀mí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í darí rẹ̀+ ní Mahane-dánì,+ láàárín Sórà àti Éṣítáólì.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́