ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lfb ẹ̀kọ́ 41 ojú ìwé 100-ojú ìwé 101 ìpínrọ̀ 2
  • Dáfídì àti Sọ́ọ̀lù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Dáfídì àti Sọ́ọ̀lù
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí Tí Dáfídì Fi Gbọ́dọ̀ Sá Lọ
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Wọ́n Fi Dáfídì Jọba
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • ‘Ìgbọràn Sàn Ju Ẹbọ Lọ’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Sámúẹ́lì
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àwọn Míì
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
lfb ẹ̀kọ́ 41 ojú ìwé 100-ojú ìwé 101 ìpínrọ̀ 2
Dáfídì ké pe Sọ́ọ̀lù àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ látorí òkè

Ẹ̀KỌ́ 41

Dáfídì àti Sọ́ọ̀lù

Lẹ́yìn tí Dáfídì pa Gòláyátì, Ọba Sọ́ọ̀lù sọ Dáfídì di ọ̀gá àwọn ọmọ ogun ẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Dáfídì máa ń lọ jagun tó sì máa ń ṣẹ́gun. Ìyẹn mú káwọn èèyàn gba ti Dáfídì gan-an. Tí Dáfídì bá ti ogun dé, àwọn obìnrin máa ń kọrin fún un, wọ́n á sì máa jó. Wọ́n máa ń kọrin pé: ‘Ẹgbẹ̀rún, ẹgbẹ̀rún ni Sọ́ọ̀lù pa lójú ogun, àmọ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá mẹ́wàá ni Dáfídì pa ní tiẹ̀!’ Sọ́ọ̀lù wá bẹ̀rẹ̀ sí í jowú Dáfídì, ó sì ń wá ọ̀nà láti pa Dáfídì.

Dáfídì mọ bí wọ́n ṣe máa ń fi háàpù kọrin gan-an. Lọ́jọ́ kan tí Dáfídì ń fi háàpù kọrin fún Sọ́ọ̀lù, ńṣe ni Sọ́ọ̀lù ju ọ̀kọ̀ tó wà lọ́wọ́ ẹ̀ lu Dáfídì kó lè pa á. Àmọ́ Dáfídì yẹ̀ ẹ́, ọ̀kọ̀ náà sì gún ògiri. Lẹ́yìn ìyẹn, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Sọ́ọ̀lù tún wá bó ṣe máa pa Dáfídì. Nígbà tó yá, Dáfídì sá lọ, ó sì sá pa mọ́ sínú aginjù.

Dáfídì mú ọ̀kọ̀ Sọ́ọ̀lù nígbà tó ń sùn

Ni Sọ́ọ̀lù bá kó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àwọn ọmọ ogun, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá Dáfídì kiri. Sọ́ọ̀lù wọ inú ihò kan tó wà nínú àpáta, inú ihò yẹn sì ni Dáfídì àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ sá pa mọ́ sí. Àwọn ọmọ ogun Dáfídì sọ fún Dáfídì pé: ‘Wò ó, ọwọ́ ẹ ti ba Sọ́ọ̀lù báyìí.’ Dáfídì wá rọra lọ sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù, ó sì gé díẹ̀ lára aṣọ tó wọ̀. Sọ́ọ̀lù ò tiẹ̀ mọ̀ rárá. Àmọ́, inú Dáfídì ò dùn pé òun gé aṣọ Sọ́ọ̀lù torí ó gbà pé ńṣe nìyẹn fi hàn pé òun ò bọ̀wọ̀ fún ọba tí Jèhófà yàn. Torí náà, kò jẹ́ káwọn ọmọ ogun rẹ̀ pa Sọ́ọ̀lù. Dáfídì wá pe Sọ́ọ̀lù, ó sì jẹ́ kó mọ̀ pé òun ò bá ti pa á, àmọ́ òun ò ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣé Sọ́ọ̀lù máa yíwà pa dà, tó sì máa dẹ̀yìn lẹ́yìn Dáfídì?

Kò ṣe bẹ́ẹ̀ o. Ńṣe ni Sọ́ọ̀lù tún ń wá bó ṣe máa pa Dáfídì. Lóru ọjọ́ kan, Dáfídì àti Ábíṣáì tó jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n Dáfídì rọra yọ́ lọ síbi tí Sọ́ọ̀lù àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ wà. Ábínérì tó máa ń ṣọ́ ọba pàápàá ti sùn. Ábíṣáì wá sọ pé: ‘Ọwọ́ tẹ Sọ́ọ̀lù! Jẹ́ kí n pa á dà nù.’ Àmọ́ Dáfídì sọ fún un pé: ‘Jèhófà máa jẹ Sọ́ọ̀lù níyà. Jẹ́ ká mú ọ̀kọ̀ rẹ̀ ká sì gbé ìkòkò omi ẹ̀, ká máa lọ.’

Dáfídì wá gun orí òkè kan tó wà nítòsí, ó ń wo Sọ́ọ̀lù àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ láti ibẹ̀. Ó wá ké sí Ábínérì pé: ‘Ábínérì, kí ló dé tó ò ṣe iṣẹ́ ẹ bí iṣẹ́, ṣebí ọba ló yẹ kó o máa ṣọ́? Ó dáa, ọ̀kọ̀ àti ìkòkò omi ọba dà?’ Sọ́ọ̀lù dá ohùn Dáfídì mọ̀, ó wá sọ pé: ‘Tó bá jẹ́ pé o fẹ́ pa mí ni, wàá ti pa mí, àmọ́ o ò ṣe bẹ́ẹ̀. Mo gbà pé ìwọ lo máa di ọba Ísírẹ́lì lẹ́yìn mi.’ Bí Sọ́ọ̀lù ṣe pa dà sáàfin ẹ̀ nìyẹn. Àmọ́, kì í ṣe gbogbo ẹbí Sọ́ọ̀lù ló kórìíra Dáfídì.

“Tó bá ṣeé ṣe, nígbà tó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ló wà, ẹ wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo èèyàn. Ẹ má ṣe fúnra yín gbẹ̀san, ẹ̀yin olùfẹ́, àmọ́ ẹ fàyè sílẹ̀ fún ìrunú.”​—Róòmù 12:18, 19

Ìbéèrè: Kí ló dé tí Sọ́ọ̀lù fi fẹ́ pa Dáfídì? Kí nìdí tí Dáfídì ò fi pa Sọ́ọ̀lù?

1 Sámúẹ́lì 16:14-23; 18:5-16; 19:9-12; 23:19-29; 24:1-15; 26:1-25

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́