Ẹ̀KỌ́ 47
Jèhófà Fún Èlíjà Lókun
Nígbà tí Jésíbẹ́lì gbọ́ ohun tí Èlíjà ṣe fáwọn wòlíì Báálì, inú bí i gan-an. Ó wá ránṣẹ́ sí Èlíjà pé: ‘Tó bá máa fi dọ̀la, ìwọ náà á ti kú bí àwọn wòlíì Báálì tó o pa.’ Àyà Èlíjà wá bẹ̀rẹ̀ sí í já, bó ṣe sá lọ sí aṣálẹ̀ nìyẹn. Ó ti rẹ̀ ẹ́ gan-an, ó wá ń sinmi lábẹ́ igi kan, ó sì gbàdúrà sí Jèhófà pé: ‘Jèhófà, wàhálà yìí ti pọ̀ jù, jẹ́ kí n kú.’ Ló bá sùn lọ lábẹ́ igi náà.
Bí Èlíjà ṣe ń sùn, áńgẹ́lì kan rọra jí i, ó sì sọ fún un pé: ‘Dìde, wá jẹun.’ Èlíjà rí búrẹ́dì kan lórí òkúta tó gbóná, ó sì tún rí ìgò omi kan. Ó jẹun, ó mu, ó sì pa dà sùn. Nígbà tó yá, áńgẹ́lì náà tún jí i, ó sì sọ fún un pé: ‘Jẹun, kó o lè lókun, torí pé ibi tó ò ń lọ jìn.’ Torí náà, Èlíjà tún jẹun sí i. Lẹ́yìn ìyẹn, Èlíjà rìn fún ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru títí tó fi dé Òkè Hórébù. Nígbà tó débẹ̀, ó wọnú ihò àpáta kan, ó sì sùn síbẹ̀. Jèhófà wá bá a sọ̀rọ̀, ó ní: ‘Kí lò ń ṣe níbí, Èlíjà?’ Èlíjà sọ pé: ‘Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti pa ẹ́ tì, wọ́n fọ́ àwọn pẹpẹ rẹ, wọ́n sì ti pa àwọn wòlíì rẹ. Ìyẹn nìkan kọ́ o, wọ́n ti fẹ́ pa èmi náà báyìí.’
Jèhófà wá sọ fún un pé: ‘Lọ dúró sórí òkè yìí.’ Nígbà tó débẹ̀, atẹ́gùn kan kọ́kọ́ fẹ́ lórí òkè yẹn. Lẹ́yìn náà, ilẹ̀ mì, iná sì bẹ̀rẹ̀ sí í jó. Níkẹyìn, Èlíjà gbọ́ ohùn kan tó rọra ń sọ̀rọ̀. Ó wá fi aṣọ bojú, ó sì jáde nínú ihò àpáta náà. Jèhófà wá bi í pé kí nìdí tó o fi sá lọ? Èlíjà sọ pé: ‘Èmi nìkan ló kù.’ Àmọ́, Jèhófà sọ fún un pé: ‘Ìwọ nìkan kọ́ ló kù. Ẹgbẹ̀rún méje (7,000) èèyàn ló ṣì wà ní Ísírẹ́lì tó ń jọ́sìn mi. Torí náà, lọ kó o sì yan Èlíṣà ṣe wòlíì dípò rẹ.’ Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Èlíjà lọ ṣe ohun tí Jèhófà ní kó ṣe. Ṣé o rò pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá ṣe ohun tó fẹ́ kó o ṣe? Bẹ́ẹ̀ ni, ó máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ní báyìí, jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lásìkò tí òjò kò fi rọ̀ yẹn.
“Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, àmọ́ nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ̀ ń tọrọ fún Ọlọ́run.”—Fílípì 4:6