Ẹ̀KỌ́ 62
Ìjọba Kan Tó Dà Bí Igi Ńlá
Lálẹ́ ọjọ́ kan, Nebukadinésárì lá àlá kan tó bà á lẹ́rù gidigidi. Ó wá pe àwọn amòye ẹ̀ pé kí wọ́n wá sọ ìtumọ̀ àlá náà fún òun. Àmọ́ kò sẹ́ni tó mọ ìtumọ̀ ẹ̀. Níkẹyìn, ọba sọ àlá náà fún Dáníẹ́lì.
Nebukadinésárì sọ fún Dáníẹ́lì pé: ‘Mo rí igi ńlá kan lójú àlá. Igi náà ga débi pé ó kan ọ̀run. Kò síbi téèyàn wà láyé tí kò ní rí i. Ó ní ewé tó rẹwà àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso. Àwọn ẹranko máa ń sinmi lábẹ́ rẹ̀, àwọn ẹyẹ sì máa ń kọ́ ìtẹ́ wọn sórí àwọn ẹ̀ka ẹ̀. Áńgẹ́lì kan wá sọ̀ kalẹ̀ látọ̀run. Ó sọ pé: “Ẹ gé igi náà lulẹ̀, ẹ gé àwọn ẹ̀ka ẹ̀ kúrò. Àmọ́ ẹ fi kùkùté igi náà sílẹ̀ pẹ̀lú gbòǹgbò ẹ̀ nínú ilẹ̀, kẹ́ ẹ sì fi ọ̀já irin àti bàbà dè é. Kí ọkàn ẹ̀ yí pa dà kúrò ní ti èèyàn, ká sì fún un ní ọkàn ẹranko, kí ìgbà méje sì kọjá lórí ẹ̀. Káwọn èèyàn tó wà láàyè lè mọ̀ pé Ẹni Gíga Jù Lọ ni Alákòóso nínú ìjọba aráyé, ẹni tó bá wù ú ló sì ń gbé e fún.” ’
Jèhófà wá fi ohun tí àlá náà túmọ̀ sí han Dáníẹ́lì. Ẹ̀rù sì ba Dáníẹ́lì gan-an nígbà tó mọ ìtumọ̀ àlá náà. Ó sọ pé: ‘Áà ọba, ì bá dáa ká ní àwọn ọ̀tá yín ni àlá náà dá lé lórí, àmọ́ ẹ̀yin ló dá lé. Ẹ̀yin ni igi tí wọ́n gé lulẹ̀ náà. Ìjọba máa bọ́ lọ́wọ́ yín, ẹ sì máa jẹ koríko bíi tàwọn ẹranko inú igbó. Àmọ́ bí áńgẹ́lì náà ṣe sọ pé kí wọ́n fi gbòǹgbò igi náà sílẹ̀, èyí fi hàn pé ẹ ṣì máa pa dà di ọba.’
Ọdún kan lẹ́yìn náà, Nebukadinésárì ń rìn lórí òkè ààfin ẹ̀, ó sì ń wo bí ìlú Bábílónì ṣe lẹ́wà tó. Ó sọ pé: ‘Ẹ wo ìlú ńlá tí mo fọwọ́ ara mi kọ́. Mo ti di èèyàn ńlá!’ Bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ohùn kan láti ọ̀run sọ fún un pé: ‘Nebukadinésárì! A ti gba ìjọba lọ́wọ́ ẹ.’
Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni orí ẹ̀ dà rú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bí ẹranko inú igbó. Èyí mú kí wọ́n lé e kúrò láàfin, ó sì lọ ń bá àwọn ẹranko gbé nínú igbó. Irun Nebukadinésárì wá gùn gan-an, èékánná ẹ̀ sì dà bíi ti ẹyẹ àṣá.
Lẹ́yìn ọdún méje, orí Nebukadinésárì pé pa dà, Jèhófà sì mú kó pa dà di ọba Bábílónì. Nebukadinésárì wá sọ pé: ‘Mo yin Jèhófà Ọba ọ̀run lógo. Ní báyìí mo ti wá mọ̀ pé Jèhófà ni Alákòóso. Ó máa ń rẹ àwọn agbéraga wálẹ̀, ó sì máa ń fi ẹni tó bá wù ú jẹ ọba.’
“Ìgbéraga ló ń ṣáájú ìparun, ẹ̀mí ìgbéraga ló sì ń ṣáájú ìkọ̀sẹ̀.”—Òwe 16:18