Ẹ̀KỌ́ 71
Jèhófà Dáàbò Bo Jésù
Àwọn ilẹ̀ kan wà lápá ìlà oòrùn ilẹ̀ Ísírẹ́lì táwọn èèyàn ibẹ̀ gbà pé ìràwọ̀ lè darí àwọn. Lálẹ́ ọjọ́ kan, àwọn ọkùnrin kan láti Ìlà Oòrùn rí ohun tó dà bí ìràwọ̀ tó mọ́lẹ̀ yòò tó ń lọ lójú ọ̀run, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé e. “Ìràwọ̀” náà darí wọn lọ sí Jerúsálẹ́mù. Àwọn ọkùnrin náà wá ń béèrè lọ́wọ́ àwọn èèyàn pé: ‘Ibo ni ọmọ tí wọ́n bí tó máa di ọba àwọn Júù wà? A fẹ́ forí balẹ̀ fún un.’
Nígbà tí Hẹ́rọ́dù ọba Jerúsálẹ́mù gbọ́ nípa ọba tuntun yìí, ọkàn ẹ̀ ò balẹ̀ rárá. Ó wá béèrè lọ́wọ́ àwọn olórí àlùfáà pé: ‘Ìlú wo ni wọ́n ti máa bí ọba náà?’ Wọ́n sọ fún un pé: ‘Àwọn wòlíì sọ pé ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni.’ Torí náà, Hẹ́rọ́dù sọ fáwọn ọkùnrin tó wá láti Ìlà Oòrùn náà pé: ‘Ẹ lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, kẹ́ ẹ sì wá ọmọ náà. Kẹ́ ẹ pa dà wá sọ ibi tó wà fún mi, kí èmi náà lè lọ forí balẹ̀ fún un.’ Àmọ́, irọ́ ló ń pa.
“Ìràwọ̀” náà tún bẹ̀rẹ̀ sí í lọ. Ó sì darí àwọn ọkùnrin náà lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. “Ìràwọ̀” náà wá dúró sórí ilé kan, wọ́n sì wọnú ilé náà. Wọ́n rí Jésù àti Màríà ìyá ẹ̀. Wọ́n forí balẹ̀ fún ọmọ náà, wọ́n sì fún un láwọn ẹ̀bùn wúrà àti oje igi tùràrí àti òjíá. Ṣé Jèhófà ló darí àwọn ọkùnrin yìí lọ sọ́dọ̀ Jésù? Rárá o.
Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, Jèhófà sọ fún Jósẹ́fù lójú àlá pé: ‘Hẹ́rọ́dù fẹ́ pa Jésù. Mú ìyàwó ẹ àti ọmọ ẹ, kẹ́ ẹ sì sá lọ sílẹ̀ Íjíbítì. Dúró síbẹ̀ títí dìgbà tí mo bá sọ fún ẹ pé kò séwu mọ́.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jósẹ́fù àti ìdílé ẹ̀ fibẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì lọ sílẹ̀ Íjíbítì.
Jèhófà ti kìlọ̀ fáwọn ọkùnrin tó wá láti Ìlà Oòrùn yẹn pé wọn ò gbọ́dọ̀ pa dà sọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù. Inú bí Hẹ́rọ́dù gan-an nígbà tó rí i pé àwọn ọkùnrin yẹn ò pa dà wá. Torí pé kò ṣeé ṣe fún un láti mọ ibi tí Jésù wà, ó pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo ọmọkùnrin tó wà lọ́jọ́ orí Jésù nílùú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Àmọ́, wọn ò rí Jésù pa torí pé ó ti wà lọ́nà jíjìn nílẹ̀ Íjíbítì.
Nígbà tó yá, Hẹ́rọ́dù kú. Jèhófà wá sọ fún Jósẹ́fù pé: ‘Ní báyìí, o lè pa dà sílùú ẹ.’ Bí Jósẹ́fù, Màríà àti Jésù ṣe pa dà sílẹ̀ Ísírẹ́lì nìyẹn, wọ́n sì ń gbé nílùú Násárẹ́tì.
“Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tó ti ẹnu mi jáde máa rí . . . , ó sì dájú pé ohun tí mo rán an pé kó ṣe máa yọrí sí rere.”—Àìsáyà 55:11