ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jy orí 8 ojú ìwé 24
  • Wọ́n Sá Lọ Mọ́ Ọba Burúkú Kan Lọ́wọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n Sá Lọ Mọ́ Ọba Burúkú Kan Lọ́wọ́
  • Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àsálà Kuro Lọwọ Òǹrorò Kan
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Ó Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ̀, Ó Pèsè fún Wọn, Ó sì Ní Ìfaradà
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Ó Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ̀, Ó Pèsè fún Wọn, Ó sì Lo Ìfaradà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ó Gba Ìtọ́sọ́nà Àtọ̀runwá
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
jy orí 8 ojú ìwé 24
Ọba Hẹ́rọ́dù pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo ọmọkùnrin ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù

ORÍ 8

Wọ́n Sá Lọ Mọ́ Ọba Burúkú Kan Lọ́wọ́

MÁTÍÙ 2:13-23

  • WỌ́N GBÉ JÉSÙ SÁ LỌ SÍ ÍJÍBÍTÌ

  • JÓSẸ́FÙ KÓ ÌDÍLÉ RẸ̀ LỌ SÍ NÁSÁRẸ́TÌ

Jósẹ́fù jí Màríà lójú oorun, ọ̀rọ̀ pàtàkì kan wà tó gbọ́dọ̀ tètè sọ fún un. Áńgẹ́lì Jèhófà ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ sí Jósẹ́fù lójú àlá ni, ó sì sọ fún un pé: “Dìde, mú ọmọ kékeré náà àti ìyá rẹ̀, kí o sì sá lọ sí Íjíbítì, kí o dúró síbẹ̀ títí màá fi bá ọ sọ̀rọ̀, torí Hẹ́rọ́dù ti fẹ́ máa wá ọmọ kékeré náà kiri kó lè pa á.”—Mátíù 2:13.

Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jósẹ́fù àti Màríà gbé ọmọ wọn, wọ́n sì fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ lóru yẹn. Ohun tí wọ́n ṣe yẹn dáa gan-an torí Hẹ́rọ́dù ti mọ̀ pé ṣe ni àwọn awòràwọ̀ náà tan òun. Ó ní kí wọ́n pa dà wá jábọ̀ fún òun, àmọ́ wọn ò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ tí wọ́n fi pa dà sílùú wọn. Orí Hẹ́rọ́dù wá kanrin! Kó lè rí Jésù pa, ó pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún méjì sísàlẹ̀ tó wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti agbègbè rẹ̀. Ohun tí àwọn awòràwọ̀ tó wá láti Ìlà Oòrùn sọ ló fi mọ̀ pé Jésù ò tíì lè ju ọmọ ọdún méjì lọ.

Ọmọ ogun kan fẹ́ já ọmọ gbà lọ́wọ́ ìyá rẹ̀

Ẹ ò rí i pé ohun tí Hẹ́rọ́dù ṣe yìí burú jáì! A ò mọ iye àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n pa. Àmọ́, bí àwọn ìyá tó fojú sunkún ọmọ wọn yìí ṣe ń sun ẹkún kíkorò mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan ṣẹ, ìyẹn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run gbẹnu wòlíì Jeremáyà sọ.—Jeremáyà 31:15.

Ní gbogbo àkókò yẹn, Jósẹ́fù àti ìdílé rẹ̀ ti sá lọ sí Íjíbítì, ibẹ̀ ni wọ́n sì ń gbé. Nígbà tó wá di alẹ́ ọjọ́ kan, áńgẹ́lì Jèhófà tún yọ sí Jósẹ́fù lójú àlá. Ó sọ fún un pé: “Dìde, mú ọmọ kékeré náà àti ìyá rẹ̀, kí o sì lọ sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì, torí àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí ọmọ kékeré náà ti kú.” (Mátíù 2:20) Jósẹ́fù wá gbà pé àwọn lè pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ àwọn. Èyí mú kí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì míì ṣẹ, ìyẹn ni pé Ọlọ́run pe Ọmọ rẹ̀ jáde ní Íjíbítì.—Hósíà 11:1.

Ó jọ pé ohun tó wà lọ́kàn Jósẹ́fù ni kí òun àti ìdílé òun máa gbé ní Jùdíà, tó ṣeé ṣe kó má jìnnà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí wọ́n ń gbé kó tó di pé wọ́n sá lọ sí Íjíbítì. Àmọ́, ó gbọ́ pé Ákíláọ́sì, ọmọ Hẹ́rọ́dù ló ń jọba ní Jùdíà, bẹ́ẹ̀ sì rèé ọmọ yìí burú gan-an. Torí náà, Ọlọ́run tún kìlọ̀ fún Jósẹ́fù lójú àlá. Bó ṣe di pé Jósẹ́fù àti ìdílé rẹ̀ rìnrìn àjò lọ sápá àríwá nìyẹn, wọ́n kúrò níbi tí ẹ̀sìn Júù ti rinlẹ̀ gan-an, wọ́n sì dúró sílùú Násárẹ́tì ní agbègbè Gálílì. Àdúgbò yìí ni Jésù dàgbà sí, ìyẹn sì mú àsọtẹ́lẹ̀ míì ṣẹ tó sọ pé: “A máa pè é ní ará Násárẹ́tì.”—Mátíù 2:23.

  • Nígbà tí àwọn awòràwọ̀ náà ò pa dà wá, kí ni Ọba Hẹ́rọ́dù ṣe, báwo sì ni Jósẹ́fù àti Màríà ṣe dáàbò bo Jésù?

  • Nígbà tí Jósẹ́fù àti ìdílé rẹ̀ kúrò ní Íjíbítì, kí nìdí tí wọn ò fi pa dà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù?

  • Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì wo ló ṣẹ lásìkò yìí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́