Ẹ̀KỌ́ 79
Jésù Ṣe Ọ̀pọ̀ Iṣẹ́ Ìyanu
Jésù wá sáyé kó lè wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ká lè mọ àwọn ohun tí Jésù máa ṣe tó bá di Ọba Ìjọba yẹn, Jèhófà fún un ní ẹ̀mí mímọ́ kó lè ṣe iṣẹ́ ìyanu. Gbogbo àìsàn ni Jésù lè wò. Gbogbo ibi tó bá wà làwọn aláìsàn ti máa ń bẹ̀ ẹ́ pé kó ran àwọn lọ́wọ́, gbogbo wọn ló sì máa ń wò sàn. Àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn adití ń gbọ́ràn, àwọn arọ ń rìn, kódà Jésù lé ẹ̀mí èṣù jáde lára àwọn èèyàn. Tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé etí aṣọ Jésù lásán ni wọ́n fọwọ́ kàn, ara wọn máa yá. Gbogbo ibi tí Jésù bá ń lọ làwọn èèyàn máa ń tẹ̀ lé e lọ. Kódà, nígbà tí Jésù fẹ́ dá wà, àwọn èèyàn ò fi í sílẹ̀, síbẹ̀ kò lé wọn.
Nígbà kan, àwọn èèyàn gbé arọ kan wá sílé tí Jésù wà. Àmọ́, èrò pọ̀ nínú ilé náà débi pé kò sọ́nà láti wọlé. Torí náà, wọ́n dá ihò sí orí ilé náà, wọ́n sì sọ ọkùnrin náà kalẹ̀ síbi tí Jésù wà. Jésù wá sọ fún ọkùnrin náà pé: ‘Dìde, kó o sì máa rìn.’ Nígbà táwọn èèyàn rí i pé ọkùnrin náà ti ń rìn, ẹnu yà wọ́n gan-an.
Jésù tún lọ sínú abúlé kan, ó sì rí àwọn ọkùnrin mẹ́wàá tó jẹ́ adẹ́tẹ̀. Àwọn ọkùnrin náà dúró sí ọ̀ọ́kán, wọ́n sì ń pariwo pé: ‘Jésù, ṣàánú wa!’ Nígbà yẹn, òfin ò gba àwọn adẹ́tẹ̀ láyè láti sún mọ́ àwọn míì. Jésù wá sọ fáwọn ọkùnrin náà pé kí wọ́n lọ sí tẹ́ńpìlì bí Òfin Jèhófà ṣe sọ pé káwọn adẹ́tẹ̀ máa ṣe tí ara wọn bá ti yá. Bí wọ́n ṣe ń lọ síbẹ̀, ara gbogbo wọn yá. Nígbà tí ọ̀kan lára wọn rí i pé ara òun ti yá, ó pa dà wá dúpẹ́ lọ́wọ́ Jésù, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo. Àbí ẹ ò rí nǹkan, nínú àwọn mẹ́wàá tí Jésù wò sàn, ẹyọ kan péré ló pa dà wá dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀.
Obìnrin kan tún wà tó ti ń ṣàìsàn fún ọdún méjìlá (12), ó sì ń wá ìwòsàn lójú méjèèjì. Obìnrin náà wá sáàárín èrò níbi tí Jésù wà, ó sì fọwọ́ kan etí aṣọ ẹ̀. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ara ẹ̀ yá. Lẹ́yìn náà, Jésù sọ pé: “Ta ló fọwọ́ kàn mí?” Àyà obìnrin náà já gan-an, àmọ́ ó wá sọ́dọ̀ Jésù, ó sì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún un. Jésù wá sọ̀rọ̀ tó fọkàn ẹ̀ balẹ̀, ó sọ pé: ‘Ọmọbìnrin, máa lọ ní àlàáfíà.’
Lẹ́yìn ìyẹn, ọkùnrin kan tí orúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Jáírù bẹ Jésù pé: ‘Jọ̀ọ́ wá sílé mi, ọmọbìnrin mi ń ṣàìsàn tó le gan-an.’ Àmọ́, kí Jésù tó dé ilé Jáírù, ọmọ náà ti kú. Nígbà tó débẹ̀, ó rí i tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sunkún. Jésù wá sọ fún wọn pé: ‘Ẹ má sunkún mọ́, ó kàn ń sùn ni.’ Ó wá mú ọwọ́ ọmọ náà dání, ó sì sọ pé: “Ọmọ, dìde!” Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ọmọ náà dìde, Jésù sì sọ fáwọn òbí ẹ̀ pé kí wọ́n fún un lóúnjẹ. Ó dájú pé inú àwọn òbí ẹ̀ máa dùn gan-an!
‘Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ àti agbára yàn án, ó sì lọ káàkiri ilẹ̀ náà, ó ń ṣe rere, ó sì ń wo gbogbo àwọn tí Èṣù ń ni lára sàn, torí pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.’—Ìṣe 10:38