Ẹ̀KỌ́ 88
Wọ́n Mú Jésù
Jésù àtàwọn àpọ́sítélì ẹ̀ rìn gba àárín àwọn òkè tó wà ní Kídírónì kọjá, wọ́n sì lọ sí Òkè Ólífì. Òru ni, òṣùpá sì mọ́lẹ̀ yòò. Nígbà tí wọ́n dé ọgbà Gẹ́tísémánì, Jésù sọ fún wọn pé: ‘Ẹ dúró síbí, kẹ́ ẹ sì máa ṣọ́nà.’ Jésù wá rìn wọnú ọgbà náà, ó sì kúnlẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú ìdààmú ńlá ni Jésù wà, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ.” Jèhófà wá rán áńgẹ̀lì kan sí i láti fún un lókun. Nígbà tí Jésù pa dà sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì, ó rí àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọ́n ń sùn. Ó wá sọ fún wọn pé: ‘Ẹ dìde! Kì í ṣe àsìkò yìí ló yẹ kẹ́ ẹ máa sùn! Àkókò ti tó báyìí tí wọ́n máa fi mí lé àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́.’
Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn Júdásì dé, òun ló sì ṣáájú àwọn èrò tí wọ́n kó idà àti igi dání. Ó mọ ibi tí wọ́n ti máa rí Jésù, torí pé Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ sábà maá ń wá síbẹ̀. Júdásì ti sọ fáwọn ọmọ ogun yẹn pé òun máa fi Jésù hàn wọ́n láàárín àwọn àpọ́sítélì. Bí wọ́n ṣe dé báyìí, ọ̀dọ̀ Jésù ló lọ tààràtà, ó sì sọ pé: ‘Mo kí ẹ́ o, Olùkọ́,’ ó sì fẹnu kò ó lẹ́nu. Jésù wá sọ fún un pé: ‘Júdásì, ò ń fẹnu kò mí lẹ́nu kí wọ́n lè mú mi, àbí?’
Jésù sún mọ́ iwájú, ó sì bi àwọn èrò náà pé: “Ta lẹ̀ ń wá?” Wọ́n sọ pé: “Jésù ará Násárẹ́tì ni.” Ó wá sọ fún wọn pé: “Èmi ni.” Bó ṣe sọ bẹ́ẹ̀, àwọn èrò náà sún mọ́ ẹ̀yìn, wọ́n sì ṣubú lulẹ̀. Jésù tún bi wọ́n pé: “Ta lẹ̀ ń wá?” Wọ́n sì tún sọ pé: “Jésù ará Násárẹ́tì ni.” Jésù wá sọ fún wọn pé: ‘Mo ti sọ fún yín pé èmi ni. Ẹ jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn mi máa lọ.’
Nígbà tí Pétérù rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó fa idà kan yọ, ó sì gé etí Málíkọ́sì, ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ àlùfáà àgbà. Àmọ́, Jésù fọwọ́ kan etí ọkùnrin náà, ó sì wò ó sàn. Jésù wá sọ fún Pétérù pé: ‘Dá idà rẹ pa dà, torí pé tó o bá ń fi idà jà, idà ni wọ́n máa fi pa ìwọ náà.’ Bí àwọn ọmọ ogun ṣe mú Jésù nìyẹn, wọ́n so ọwọ́ ẹ̀, àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ sì sá lọ. Àwọn èrò náà mú Jésù lọ sọ́dọ̀ Ánásì olórí àlùfáà. Ánásì béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè lọ́wọ́ Jésù, ó sì rán an lọ sọ́dọ̀ Káyáfà Àlùfáà Àgbà. Àmọ́, kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn àpọ́sítélì?
“Ẹ máa ní ìpọ́njú nínú ayé, àmọ́ ẹ mọ́kàn le! Mo ti ṣẹ́gun ayé.”—Jòhánù 16:33