ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lfb ẹ̀kọ́ 91 ojú ìwé 212-ojú ìwé 213 ìpínrọ̀ 1
  • Jésù Jíǹde

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jésù Jíǹde
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọlọ́run Rántí Ọmọ Rẹ̀
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Jésù Jíǹde
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Ọlọ́run Ti Jí Jésù Dìde, Ibojì Rẹ̀ sì Ti Ṣófo!
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Jesu Walaaye!
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
Àwọn Míì
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
lfb ẹ̀kọ́ 91 ojú ìwé 212-ojú ìwé 213 ìpínrọ̀ 1
Ó ya àwọn obìnrin kan lẹ́nu pé ibojì Jésù ṣófo

Ẹ̀KỌ́ 91

Jésù Jíǹde

Lẹ́yìn tí Jésù kú, ọkùnrin olówó kan tó ń jẹ́ Jósẹ́fù gba àṣẹ lọ́wọ́ Pílátù láti gbé òkú Jésù kúrò lórí òpó igi náà. Ó wá fi aṣọ tó dáa di òkú Jésù, ó sì fi èròjà tó ń ta sánsán sí i, lẹ́yìn náà ló wá tẹ́ Jésù sínú ibojì, ó sì yí òkúta ńlá kan dí ẹnu ibojì náà. Àwọn olórí àlùfáà wá sọ fún Pílátù pé: ‘Ẹ̀rù ń bà wá pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lè wá jí òkú ẹ̀ gbé kí wọ́n sì sọ pé ó ti jíǹde.’ Torí náà, Pílátù sọ fún wọn pé: ‘Ẹ dí ibojì náà, kẹ́ ẹ sì fi àwọn ẹ̀ṣọ́ síbẹ̀.’

Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, àwọn obìnrin kan wá sí ibojì náà láàárọ̀ kùtù, wọ́n sì rí i pé wọ́n ti yí òkúta ńlá tó dí ẹnu ibojì náà kúrò. Nígbà tí wọ́n wọnú ibojì náà, áńgẹ́lì kan sọ fún wọn pé: ‘Ẹ má bẹ̀rù. Jésù ti jíǹde. Ẹ lọ sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n lọ pàdé ẹ̀ ní Gálílì.’

Màríà Magidalénì sáré lọ wá Pétérù àti Jòhánù. Ó wá sọ fún wọn pé: ‘Ẹnì kan ti wá gbé òkú Jésù o!’ Ni Pétérù àti Jòhánù bá sáré lọ sí ibojì náà. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, wọn ò bá òkú Jésù níbẹ̀, wọ́n wá pa dà sílé wọn.

Nígbà tí Màríà pa dà sí ibojì náà, ó rí áńgẹ́lì méjì nínú ibẹ̀, ó wá sọ fún wọn pé: ‘Mi ò mọ ibi tí wọ́n gbé Olúwa mi lọ.’ Lẹ́yìn náà, ó rí ọkùnrin kan, ó sì rò pé ẹni tó ń ṣọ́ ọgbà ni. Ó wá sọ fẹ́ni náà pé: ‘Ẹ jọ̀ọ́ sà, ẹ sọ ibi tẹ́ ẹ gbé òkú Jésù lọ fún mi.’ Àmọ́ bí ọkùnrin náà ṣe sọ pé, “Màríà!” Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Màríà mọ̀ pé Jésù ni. Ló bá pariwo pé: “Olùkọ́!” ó sì dì mọ́ ọn. Jésù wá sọ fún un pé: ‘Lọ sọ fáwọn arákùnrin mi pé o ti rí mi.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Màríà sáré lọ bá àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù, ó sì sọ fún wọn pé òun ti rí Jésù.

Lọ́jọ́ yẹn, àwọn ọmọlẹ́yìn méjì ń rìnrìn àjò láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Ẹ́máọ́sì. Ṣàdédé ni ọkùnrin kan dara pọ̀ mọ́ wọn nínú ìrìn àjò náà, ó sì béèrè pé kí ni wọ́n ń sọ. Àwọn ọmọlẹ́yìn náà dá a lóhùn pé: ‘Ṣé o ò tíì gbọ́ ni? Àwọn olórí àlùfáà pa Jésù níjẹta. Àmọ́ a gbọ́ táwọn obìnrin kan ń sọ pé ó ti jíǹde!’ Ni ọkùnrin yìí bá bi wọ́n pé: ‘Ṣé ẹ gba ohun táwọn wòlíì sọ gbọ́? Wọ́n ní Kristi máa kú ṣùgbọ́n ó máa jíǹde.’ Lẹ́yìn ìyẹn, ọkùnrin náà ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ fún wọn. Nígbà tí wọ́n dé Ẹ́máọ́sì, àwọn ọmọlẹ́yìn náà sọ fún ọkùnrin yẹn pé kó wá báwọn jẹun. Nígbà tí ọkùnrin náà gbàdúrà sórí búrẹ́dì tí wọ́n fẹ́ jẹ ni wọ́n wá mọ̀ pé Jésù ni. Bó ṣe pòórá láàárín wọn nìyẹn.

Àwọn ọmọlẹ́yìn méjèèjì wá sáré lọ sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fáwọn àpọ́sítélì níbi tí wọ́n kóra jọ sí ní Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí wọ́n wà nínú ilé kan níbẹ̀, Jésù yọ sí gbogbo wọn lójijì. Ńṣe ló dà bíi pé wọ́n ń lálàá. Jésù sọ fún wọn pé: ‘Ẹ wo ọwọ́ mi, ẹ fọwọ́ kàn mí. Ìwé Mímọ́ ti sọ pé Kristi máa jíǹde.’

“Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tó ń wá sọ́dọ̀ Baba àfi nípasẹ̀ mi.”​—Jòhánù 14:6

Ìbéèrè: Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn obìnrin kan lọ sí ibojì Jésù? Kí ló ṣẹlẹ̀ lójú ọ̀nà Ẹ́máọ́sì?

Mátíù 27:57–28:10; Máàkù 15:42–16:8; Lúùkù 23:50–24:43; Jòhánù 19:38–20:23

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́