ORÍ 39
Ọlọ́run Rántí Ọmọ Rẹ̀
JÉSÙ sunkún nígbà tí Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ kú. Ǹjẹ́ o rò pé ó dun Jèhófà pẹ̀lú nígbà tí Jésù jìyà tó sì kú?— Bíbélì sọ pé àwọn nǹkan kan lè ṣẹlẹ̀ tó lè ‘mú kí inú Ọlọ́run bà jẹ́’ àní kí ó tilẹ̀ ‘dùn ún’ pàápàá.—Sáàmù 78:40, 41; Jòhánù 11:35.
Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo bí ìrora Jèhófà yóò ṣe pọ̀ tó bí ó ṣe ń wo Ọmọ rẹ̀ nígbà tó kú?— Ó dá Jésù lójú pé Ọlọ́run ò ní gbàgbé òun. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tí ó sọ kẹ́yìn kí ó tó kú ni pé: “Baba, ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.”—Lúùkù 23:46.
Ó dá Jésù lójú pé òun máa ní àjíǹde, pé Ọlọ́run ò ní fi òun sílẹ̀ nínú “Hédíìsì,” ìyẹn inú ibojì. Lẹ́yìn tí Ọlọ́run jí Jésù dìde, àpọ́sítélì Pétérù fa ọ̀rọ̀ tí a ti kọ sínú Bíbélì nípa Jésù yọ, ó sọ pé: ‘A kò fi í sílẹ̀ sínú Hédíìsì, bẹ́ẹ̀ ni ẹran ara rẹ̀ kò rí ìdíbàjẹ́.’ (Ìṣe 2:31; Sáàmù 16:10) Bẹ́ẹ̀ ni o, òkú Jésù kò pẹ́ nínú ibojì débi tí yóò fi díbàjẹ́, ìyẹn ni pé kò jẹrà kí ó sì máa rùn.
Ṣáájú kí Jésù tó kú pàápàá ló ti sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé òun ò ní wà ní ipò òkú fún ìgbà pípẹ́. Ó ṣàlàyé fún wọn pé a ó ‘pa òun, a ó sì gbé òun dìde ní ọjọ́ kẹta.’ (Lúùkù 9:22) Nítorí náà, ká sòótọ́, kò yẹ kí ó ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lẹ́nu nígbà tí Jésù jíǹde. Àmọ́ kí ló ṣẹlẹ̀?— Jẹ́ ká wò ó ná.
Nǹkan bí aago mẹ́ta ọ̀sán ọjọ́ Friday ni Olùkọ́ Ńlá náà kú lórí òpó igi oró. Jósẹ́fù, ọlọ́rọ̀ kan tó jẹ́ ara àjọ Sànhẹ́dírìn, jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù níkọ̀kọ̀. Nígbà tó gbọ́ pé Jésù kú, ó lọ sọ́dọ̀ Pílátù ará Róòmù tó jẹ́ gómìnà wọn. Ó lọ tọrọ àyè láti gbé òkú Jésù sọ̀ kalẹ̀ kúrò lórí òpó náà láti lọ sin ín. Lẹ́yìn náà, Jósẹ́fù gbé òkú Jésù lọ sínú ọgbà kan níbi tí ibojì kan wà, ìyẹn ibi tí wọ́n máa ń tẹ́ òkú sí.
Lẹ́yìn tí wọ́n gbé òkú náà sínú ibojì, wọ́n yí òkúta ńlá kan dí ẹnu ọ̀nà rẹ̀. Wọ́n dí ẹnu ibojì náà pa. Ó ti wá di ọjọ́ kẹta wàyí, èyí tí í ṣe ọjọ́ Sunday. Àfẹ̀mọ́jú ni, ibi gbogbo ṣì ṣókùnkùn. Àwọn ọkùnrin kan wà níbi ibojì náà wọ́n ń ṣọ́ ọ. Àwọn olórí àlùfáà ló ní kí wọ́n máa ṣọ́ ọ. Ǹjẹ́ o mọ ìdí rẹ̀?—
Àwọn àlùfáà náà ti gbọ́ pé Jésù ní òun yóò jíǹde. Nítorí náà, wọ́n fi àwọn èèyàn ṣọ́ ibojì rẹ̀ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ má bàa lọ jí òkú rẹ̀ gbé, kí wọ́n wá sọ pé Jésù ti jíǹde. Àmọ́ lójijì ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mì tìtì. Ìmọ́lẹ̀ kan dédé mọ́lẹ̀ yàà láàárín òkùnkùn yẹn. Áńgẹ́lì Jèhófà ló dé! Ẹ̀rù ba àwọn ọmọ ogun náà tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ò fi lè mira rárá. Áńgẹ́lì náà lọ síbi òkúta náà ó sì yí i kúrò. Ibojì náà ti ṣófo!
Kí nìdí tí ibojì yìí fi ṣófo? Kí ló ti ṣẹlẹ̀ níbẹ̀?
Dájúdájú, ohun tí àpọ́sítélì Pétérù sọ lẹ́yìn náà ló ti ṣẹlẹ̀, ó ní: “Jésù yìí ni Ọlọ́run jí dìde.” (Ìṣe 2:32) Ọlọ́run jí Jésù dìde, ó sì fún un ní ara mìíràn bí irú èyí tí ó ní tẹ́lẹ̀ kí ó tó wá sórí ilẹ̀ ayé. Ọlọ́run jí i dìde pẹ̀lú ara tẹ̀mí, irú èyí tí àwọn áńgẹ́lì ní. (1 Pétérù 3:18) Nítorí náà, bí Jésù bá fẹ́ kí àwọn èèyàn rí òun, àfi kí ó gbé ẹran ara wọ̀. Ṣé ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́?— Ẹ jẹ́ kí á wò ó ná.
Oòrùn ń yọ bọ̀ wàyí. Àwọn ọmọ ogun tó ń ṣọ́ ibojì náà ti sá kúrò níbẹ̀. Màríà Magidalénì àti àwọn obìnrin mìíràn tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń bọ̀ níbi ibojì náà. Wọ́n ń bá ara wọn sọ ọ́ pé: ‘Ta ni yóò bá wa yí òkúta ńlá náà kúrò?’ (Máàkù 16:3) Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n débi ibojì náà, a ti yí òkúta náà kúrò ní ẹnu rẹ̀. Ibojì náà sì ṣófo! Òkú Jésù kò sí níbẹ̀ mọ́! Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Màríà Magidalénì sáré lọ pe àwọn kan lára àwọn àpọ́sítélì Jésù.
Àwọn obìnrin yòókù dúró síbi ẹnu ọ̀nà ibojì náà. Wọ́n ń ṣe kàyéfì pé: ‘Ibo ni ó ṣeé ṣe kí ara Jésù wà?’ Lójijì, àwọn ọkùnrin méjì tí aṣọ wọn ń kọ mànà yọ sí wọn. Àwọn áńgẹ́lì ni! Wọ́n sọ fún àwọn obìnrin náà pé: ‘Kí ló dé tí ẹ̀ ń wá Jésù kiri níhìn-ín? Ó ti jíǹde. Ẹ tètè lọ sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀.’ Eré ayọ̀ tí àwọn obìnrin náà ń sá lọ sílé ga! Bí wọ́n ṣe ń lọ wọ́n pàdé ọkùnrin kan. Ǹjẹ́ o mọ onítọ̀hún?—
Jésù ni, ó ti gbé ẹran ara èèyàn wọ̀! Òun náà tún sọ fún àwọn obìnrin náà pé: ‘Ẹ lọ sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi.’ Inú àwọn obìnrin náà dùn gidigidi. Kíá, wọ́n ti dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn wọ́n sì sọ fún wọn pé: ‘Jésù ti jíǹde! A fojú wa rí i!’ Màríà pẹ̀lú ti sọ fún Pétérù àti Jòhánù pé ibojì Jésù ṣófo. Àwọn náà wá síbẹ̀ láti wá wò ó, gẹ́gẹ́ bí o ṣe rí i níhìn-ín. Wọ́n ń yẹ aṣọ tí wọ́n fi di òkú Jésù wò, ohun tó ṣẹlẹ̀ kò yé wọn. Wọ́n ń rò ó pé Jésù mà lè ti jíǹde lóòótọ́ o.
Kí ló ṣeé ṣe kí Pétérù àti Jòhánù máa rò lọ́kàn?
Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ sí i lọ́jọ́ Sunday yẹn, Jésù fara han méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó ń rìn lọ sí ọ̀nà abúlé kan tó ń jẹ́ Ẹ́máọ́sì. Ó ṣẹlẹ̀ pé Jésù wá bá wọn rìn wọ́n sì jọ ń sọ̀rọ̀ lọ, ṣùgbọ́n wọn ò mọ̀ pé òun ni nítorí pé kì í ṣe ara kan náà tí ó ní tẹ́lẹ̀ ni wọ́n rí. Ìgbà tí Jésù gbàdúrà nígbà tó fẹ́ bá wọn jẹun pọ̀ ni wọ́n ṣẹ̀sẹ̀ mọ̀ pé òun ni. Inú àwọn ọmọ ẹ̀yìn yìí wá dùn débi pé eré lẹlẹ ni wọ́n bá dé Jerúsálẹ́mù tó jìnnà gan-an sí wọn! Bóyá kò pẹ́ lẹ́yìn tiwọn yìí ni Jésù fara han Pétérù láti jẹ́ kó mọ̀ pé òun ti jíǹde.
Ó sì ṣẹlẹ̀ pé ní alẹ́ ọjọ́ Sunday yìí kan náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn púpọ̀ kóra jọ sínú yàrá kan. Wọ́n ti ilẹ̀kùn ibẹ̀. Lójijì wọ́n dédé rí Jésù láàárín wọn nínú yàrá náà! Wọ́n wá mọ̀ dájú pé Olùkọ́ Ńlá náà ti jíǹde lóòótọ́. Inú wọn mà dùn gan-an ni o!—Mátíù 28:1-15; Lúùkù 24:1-49; Jòhánù 19:38–20:21.
Fún ogójì ọjọ́ ni Jésù fi ń gbé oríṣiríṣi ara èèyàn wọ̀ láti fara han àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, kí wọ́n lè mọ̀ pé òun ti jíǹde. Lẹ́yìn náà, ó kúrò ní orí ilẹ̀ ayé, ó padà sọ́dọ̀ Bàbá rẹ̀ ní ọ̀run. (Ìṣe 1:9-11) Láìpẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún gbogbo èèyàn pé Ọlọ́run ti jí Jésù dìde kúrò nínú ikú. Kódà nígbà tí àwọn àlùfáà nà wọ́n tí wọ́n sì pa òmíràn nínú wọn, wọn ò dákẹ́ ìwàásù wọn. Wọ́n mọ̀ pé bí àwọn bá kú Ọlọ́run yóò rántí àwọn gẹ́lẹ́ bí ó ṣe rántí Ọmọ rẹ̀.
Nígbà àyájọ́ àjíǹde Jésù, kí ni o rò pé ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ronú nípa rẹ̀? Ṣùgbọ́n kí ni ìwọ máa ń ronú nípa rẹ̀?
Áà, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù àtijọ́ yìí mà yàtọ̀ pátápátá sí ọ̀pọ̀ èèyàn òde òní o! Ní àwọn apá ibì kan ní ayé òde òní, ohun tí àwọn kàn máa ń ronú nípa rẹ̀ nígbà àyájọ́ àjíǹde Jésù ni ehoro àti ẹyin tí a pa láró tí wọ́n fi ń ṣe ayẹyẹ ọdún àjíǹde. Ṣùgbọ́n Bíbélì kò sọ ohunkóhun nípa fífi ehoro tàbí ẹyin ṣe ọdún àjíǹde. Ọ̀rọ̀ bí a ṣe lè máa sin Ọlọ́run ni Bíbélì sọ.
A lè ṣe bíi ti àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, kí á máa sọ fún àwọn èèyàn pé Ọlọ́run ṣe ohun ìyanu nígbà tó jí Ọmọ rẹ̀ dìde. Kò sídìí fún wa láti máa bẹ̀rù, àní bí àwọn èèyàn bá tilẹ̀ sọ pé àwọn yóò pa wá. Bí a bá kú, Jèhófà yóò rántí wa yóò sì jí wa dìde àní bí ó ṣe jí Jésù dìde.
Ǹjẹ́ kò dùn mọ́ wa láti mọ̀ pé Ọlọ́run rántí àwọn tó ń sìn ín, àti pé yóò jí wọn dìde látinú ipò òkú?— Bí a bá mọ èyí, ó yẹ kí ó mú wa fẹ́ láti mọ ọ̀nà tí a lè gbà máa mú inú Ọlọ́run dùn. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé a lè mú inú Ọlọ́run dùn lóòótọ́?— Jẹ́ ká wá sọ̀rọ̀ nípa ìyẹn wàyí.
Ó yẹ kí ìgbàgbọ́ tí a ní pé Jésù jíǹde mú kí a ní ìrètí tí ó dájú, kí ìgbàgbọ́ wa sì lágbára. Jọ̀wọ́ ka Ìṣe 2:22-36; 4:18-20; àti 1 Kọ́ríńtì 15:3-8, 20-23.