Ẹ̀KỌ́ 94
Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Jésù Gba Ẹ̀mí Mímọ́
Ọjọ́ mẹ́wàá (10) lẹ́yìn tí Jésù pa dà sí ọ̀run, àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ gba ẹ̀mí mímọ́. Ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni lèyí ṣẹlẹ̀, ọ̀pọ̀ ìlú sì làwọn èèyàn ti wá sí Jerúsálẹ́mù láti wá ṣe àjọyọ̀. Nǹkan bí ọgọ́fà (120) àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kóra jọ sínú yàrá òkè kan. Lójijì, ohun ìyanu kan ṣẹlẹ̀. Ńṣe lohun kan tó dà bí iná dúró sórí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù, gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ oríṣiríṣi èdè. Ariwo tó ń dún bí ìgbà tí ìjì ń jà sì kún inú ilé náà.
Àwọn èrò tó wá sí Jerúsálẹ́mù gbọ́ ariwo yìí, wọ́n sì sáré wá sílé náà kí wọ́n lè mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Ńṣe lẹnu ya gbogbo wọn nígbà tí wọ́n rí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n ń sọ oríṣiríṣi èdè. Wọ́n sọ pé: ‘Ṣebí Gálílì làwọn èèyàn yìí ti wá, báwo ló ṣe wá jẹ́ tí wọ́n ń sọ oríṣiríṣi èdè?’
Lẹ́yìn náà, Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì tó kù dúró níwájú àwọn èrò náà. Pétérù wá ṣàlàyé fún wọn nípa báwọn ọ̀tá ṣe pa Jésù àti bí Jèhófà ṣe jí i dìde. Pétérù sọ pé: ‘Ní báyìí, Jésù ti wà lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run ní ọ̀run, ó sì ti fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ tó ṣèlérí. Ìdí nìyẹn tẹ́ ẹ fi rí àwọn ìṣẹ́ ìyanu yìí.’
Ọ̀rọ̀ tí Pétérù sọ lọ́jọ́ yẹn wọ àwọn èèyàn náà lọ́kàn, wọ́n wá bi í pé: “Kí ni ká ṣe?” Pétérù dáhùn pé: ‘Ẹ ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ yín, ká sì ṣèrìbọmi fún yín lórúkọ Jésù. Ọlọ́run á sì fún ẹ̀yin náà ní ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́.’ Lọ́jọ́ yẹn, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) èèyàn ló ṣèrìbọmi. Látìgbà yẹn làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ti bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i ní Jerúsálẹ́mù. Ẹ̀mí mímọ́ wá ran àwọn àpọ́sítélì Jésù lọ́wọ́ láti dá ọ̀pọ̀ ìjọ tuntun sílẹ̀ kí wọ́n lè máa kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní gbogbo nǹkan tí Jésù pa láṣẹ.
“Tí o bá ń fi ẹnu rẹ kéde ní gbangba pé Jésù ni Olúwa, tí o sì ní ìgbàgbọ́ nínú ọkàn rẹ pé Ọlọ́run gbé e dìde kúrò nínú ikú, a ó gbà ọ́ là.”—Róòmù 10:9