Ẹ̀KỌ́ 96
Jésù Yan Sọ́ọ̀lù
Ìlú Tásù ni wọ́n bí Sọ́ọ̀lù sí, ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù sì ni. Farisí tó mọ Òfin àwọn Júù dáadáa ni, ó sì kórìíra àwọn Kristẹni. Ńṣe ló máa ń mú àwọn Kristẹni jáde nílé wọn, táá sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n. Kódà, ó wà pẹ̀lú àwọn ìkà èèyàn tó sọ Sítéfánù lókùúta títí tó fi kú.
Ó wu Sọ́ọ̀lù pé kó tún lọ fìyà jẹ àwọn Kristẹni láwọn ìlú míì yàtọ̀ sí Jerúsálẹ́mù. Ó wá sọ fún àlùfáà àgbà pé kó jẹ́ kí òun lọ sílùú Damásíkù kóun lè lọ fìyà jẹ àwọn Kristẹni tó wà níbẹ̀. Bí Sọ́ọ̀lù ṣe sún mọ́ ìlú náà, ìmọ́lẹ̀ kan ṣàdédé tàn yòò níbi tó dúró sí, bó ṣe ṣubú sílẹ̀ nìyẹn. Ó wá gbọ́ tí ohùn kan sọ pé: ‘Sọ́ọ̀lù, kí ló dé tó ò ń ta kò mí?’ Sọ́ọ̀lù dáhùn pé: ‘Ta ló ń bá mi sọ̀rọ̀?’ Ohùn náà sọ pé: ‘Èmi ni Jésù. Wọnú ìlú Damásíkù, ibẹ̀ ni wàá ti mọ nǹkan tó yẹ kó o ṣe.’ Nígbà tí Sọ́ọ̀lù dìde, kò ríran mọ́, wọ́n sì fà á lọ́wọ́ wọ inú ìlú náà.
Kristẹni olóòótọ́ kan wà nílùú Damásíkù tó ń jẹ́ Ananáyà. Jésù sọ fún un nínú ìran pé: ‘Lọ sílé Júdásì tó wà ní ojú ọ̀nà tí wọ́n ń pè ní Títọ́, kó o sì lọ bá Sọ́ọ̀lù níbẹ̀.’ Ananáyà wá sọ pé: ‘Olúwa, mo ti gbọ́ nípa ọkùnrin yìí! Òun ló ń ju àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ sẹ́wọ̀n!’ Àmọ́ Jésù sọ fún un pé: ‘Lọ bá a, torí mo ti yàn án láti wàásù ìhìn rere fún ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.’
Nígbà tí Ananáyà rí Sọ́ọ̀lù, ó sọ fún un pé: ‘Sọ́ọ̀lù, arákùnrin mi, Jésù ló rán mi láti wá la ojú ẹ.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí í ríran. Ó wá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù, ó sì di ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀. Sọ́ọ̀lù ṣèrìbọmi, òun náà sì di Kristẹni. Látìgbà yẹn ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù nínú sínágọ́gù pẹ̀lú àwọn Kristẹni míì. Fojú inú wo bí ẹnu ṣe máa ya àwọn Júù nígbà tí wọ́n rí i tí Sọ́ọ̀lù ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Jésù. Wọ́n ń sọ pé: ‘Àbẹ́ ò rí nǹkan! Ṣebí ọkùnrin yìí ló máa ń fìyà jẹ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù?’
Ọdún mẹ́ta ni Sọ́ọ̀lù fi wàásù fáwọn tó ń gbé nílùú Damásíkù. Àmọ́ àwọn Júù kórìíra Sọ́ọ̀lù, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa á. Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn gbọ́ pé àwọn Júù fẹ́ pa Sọ́ọ̀lù, wọ́n dáàbò bò ó kó lè fi ìlú náà sílẹ̀ láìséwu. Wọ́n gbé e sínú apẹ̀rẹ̀, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kálẹ̀ láti ojú ihò kan lára ògiri kó lè sá lọ.
Nígbà tí Sọ́ọ̀lù dé Jerúsálẹ́mù, ó gbìyànjú láti lọ bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà níbẹ̀. Àmọ́ ẹ̀rù ń ba àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà. Ọkàn lára wọn tó ń jẹ́ Bánábà wá mú Sọ́ọ̀lù wá sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì, ó sì sọ fún wọn pé kí wọ́n má bẹ̀rù Sọ́ọ̀lù mọ́ torí ó ti yí pa dà. Sọ́ọ̀lù wá bẹ̀rẹ̀ sí í fìtara wàásù ìhìn rere pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Nígbà tó yá, a wá mọ̀ ọ́n sí Pọ́ọ̀lù.
“Kristi Jésù wá sí ayé láti gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ là. Èmi sì ni ẹni àkọ́kọ́ lára wọn.”—1 Tímótì 1:15