ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • my ìtàn 108
  • Lójú Ọ̀nà Damásíkù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lójú Ọ̀nà Damásíkù
  • Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jésù Yan Sọ́ọ̀lù
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Onínúnibíni Rí Ìmọ́lẹ̀ Ńlá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ǹjẹ́ Àwọn Tó Ń Ṣe Ohun Búburú Lè Yí Padà?
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Iṣẹ́ Ìwàásù Mú Kí Wọ́n Ṣe Inúnibíni sí Sọ́ọ̀lù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Ìwé Ìtàn Bíbélì
my ìtàn 108
Bí wọ́n ṣe ń lọ sí Damásíkù, iná kan tàn sí Sọ́ọ̀lù lójú, ó sì ṣubú lulẹ̀

ÌTÀN 108

Lójú Ọ̀nà Damásíkù

ṢÓ O mọ ẹni tó wà nílẹ̀ẹ́lẹ̀ yìí? Sọ́ọ̀lù ni. Ṣó o rántí, òun ló ń bá àwọn tó sọ Sítéfánù lókùúta pa ṣọ́ ẹ̀wù wọn. Wo ìmọ́lẹ̀ tó ń tàn yanran yẹn! Kí ló ń ṣẹlẹ̀?

Lẹ́yìn tí wọ́n pa Sítéfánù, ọ̀gá ni Sọ́ọ̀lù jẹ́ lára àwọn tó ń wá àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kiri kí wọ́n bàa lè ṣe wọ́n léṣe. Ó ń wá wọn láti ojúlé dé ojúlé, á wá fà wọ́n lọ, á sì jù wọ́n sẹ́wọ̀n. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn sá lọ sáwọn ìlú míì wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kéde “ìhìn rere” níbẹ̀. Àmọ́, Sọ́ọ̀lù tún lọ sáwọn ìlú míì láti wá àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kàn. Ọ̀nà Damásíkù ló forí lé báyìí. Àmọ́, lójú ọ̀nà, ohun ìyanu tó ṣẹlẹ̀ rèé:

Lójijì, ìmọ́lẹ̀ láti ojú ọ̀run tàn yí Sọ́ọ̀lù ká. Òun lò ń wò tó ṣubú lulẹ̀ nínú àwòrán yìí. Ohùn kan sì ké sí i pé: ‘Sọ́ọ̀lù, Sọ́ọ̀lù! Kí ló dé tó ò ń pa mí lára?’ Àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú Sọ́ọ̀lù rí ìmọ́lẹ̀ náà wọ́n sì gbọ́ ohùn, ṣùgbọ́n wọn ò lóye nǹkan tí ohùn náà ń sọ.

Sọ́ọ̀lù wá béèrè pé: ‘Ìwọ ta ni, Olúwa?’

Ohùn náà fèsì pé: ‘Èmi ni Jésù ẹni tí ò ń pa lára.’ Jésù sọ èyí nítorí pé nígbà tí Sọ́ọ̀lù bá ń pa àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lára, ó máa ń ṣe Jésù bí ẹni pé òun gan-an ni Sọ́ọ̀lù ń pa lára.

Sọ́ọ̀lù wá béèrè pé: ‘Kí ni kí n ṣe, Olúwa?’

Jésù sọ́ fún un pé: ‘Dìde kó o lọ sí Damásíkù, ibẹ̀ lẹnì kan á ti sọ ohun tí wàá ṣe fún ẹ.’ Nígbà tí Sọ́ọ̀lù dìde tó lajú rẹ̀, kò lè rí ohunkóhun. Ó ti fọ́jú! Nítorí náà, àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ di ọwọ́ rẹ̀ mú, wọ́n sì mú un lọ sí Damásíkù.

Jésù wá sọ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní Damásíkù pé: ‘Ananíà, dìde. Lọ sí ojú pópó tó ń jẹ́ Títọ́. Ní ilé Júdà, béèrè ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Sọ́ọ̀lù. Mo ti yàn án láti jẹ́ ìránṣẹ́ pàtàkì fún mi.’

Ananíà ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Nígbà tó rí Sọ́ọ̀lù, ó gbé ọwọ́ lé e ó sì wí pé: ‘Olúwa rán mi wá kí ìwọ lè tún ríran kí o sì kún fún ẹ̀mí mímọ́.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ohun kan tó dà bí ìpẹ́ já bọ́ kúrò lójú rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ríran.

Jésù lo Sọ́ọ̀lù ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà láti wàásù fáwọn èèyàn ní oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè. Òun la wá mọ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù báyìí, a ṣì máa kọ́ púpọ̀ nípa rẹ̀ níwájú. Àmọ́, jẹ́ ká kọ́kọ́ wo ohun tí Ọlọ́run rán Pétérù láti ṣe.

Ìṣe 8:1-4; 9:1-20; 22:6-16; 26:8-20.

Àwọn Ìbéèré fún Ìkẹ́kọ̀ọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́