Ẹ̀KỌ́ 97
Kọ̀nílíù Gba Ẹ̀mí Mímọ́
Ọ̀gágun Róòmù kan wà nílùú Kesaríà tó ń jẹ́ Kọ̀nílíù. Èèyàn pàtàkì ni, àwọn Júù sì bọ̀wọ̀ fun un gan-an bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe Júù. Ó lawọ́ gan-an, ó sì máa ń ran àwọn tálákà lọ́wọ́. Kọ̀nílíù gba Jèhófà gbọ́, ó sì máa ń gbàdúrà sí i déédéé. Lọ́jọ́ kan, áńgẹ́lì kan fara han Kọ̀nílíù, ó sì sọ fún un pé: ‘Ọlọ́run ti gbọ́ àdúrà ẹ. Torí náà, rán àwọn èèyàn lọ sílùú Jópà níbi tí Pétérù ń gbé, kó o sì ránṣẹ́ sí i pé kó wá sọ́dọ̀ ẹ.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Kọ̀nílíù rán àwọn ọkùnrin mẹ́ta sílùú Jópà. Ìlú Jópà sì jìn tó nǹkan bí ọgbọ̀n (30) máìlì sí Kesaríà.
Láàárín àkókò yẹn nílùú Jópà, Pétérù rí ìran kan. Nínú ìran yẹn, ó rí àwọn ẹran táwọn Júù ò gbọ́dọ̀ jẹ, ó wá gbọ́ tí ohùn kan sọ fún un pé kó jẹ ẹ́. Pétérù kọ̀, ó ní: ‘Mi ò jẹ ẹran aláìmọ́ rí láyé mi.’ Lẹ́yìn náà, ohùn yẹn sọ fún un pé: ‘Má pe àwọn ẹran yìí ní aláìmọ́, torí pé Ọlọ́run ti sọ wọ́n di mímọ́.’ Ohùn yẹn tún wá sọ fún Pétérù pé: ‘Àwọn ọkùnrin mẹ́ta wà lẹ́nu ọ̀nà ẹ. Tẹ̀ lé wọn.’ Pétérù lọ sẹ́nu ọ̀nà, ó rí àwọn ọkùnrin náà, ó sì béèrè ohun tí wọ́n fẹ́. Wọ́n dáhùn pé: ‘Ọ̀gágun Róòmù kan tó ń jẹ́ Kọ̀nílíù ló rán wa wá. Ó sì ní kó o wá sílé òun ní Kesaríà.’ Pétérù gba àwọn ọkùnrin náà lálejò, wọ́n sì sun ilé ẹ̀ mọ́jú. Nígbà tó di ọjọ́ kejì, Pétérù bá àwọn ọkùnrin náà lọ sí Kesaríà, àwọn arákùnrin kan láti Jópà sì tẹ̀ lé e.
Bí Kọ̀nílíù ṣe rí Pétérù, ńṣe ló tẹrí ba fún un. Àmọ́ Pétérù sọ fún un pé: ‘Dìde! Èèyàn bí i tìẹ lèmi náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwa Júù kì í wọlé àwọn tí kì í ṣe Júù, Ọlọ́run sọ fún mi pé kí n wá sílé ẹ. Jọ̀ọ́, kí nìdí tó o fi ránṣẹ́ sí mi?’
Kọ̀nílíù dá Pétérù lóhùn pé: ‘Lọ́jọ́ mẹ́rin sẹ́yìn, mò ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, áńgẹ́lì kan wá sọ fún mi pé kí n ránṣẹ́ sí ẹ. Jọ̀ọ́, sọ̀rọ̀ Jèhófà fún wa.’ Pétérù sọ pé: ‘Mo ti wá rí i pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú. Gbogbo àwọn tó bá fẹ́ sìn ín ló máa ń tẹ́wọ́ gbà.’ Pétérù wá kọ́ wọn ní ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Jésù. Lẹ́yìn náà, ẹ̀mí mímọ́ bà lé Kọ̀nílíù àtàwọn tó wà pẹ̀lú ẹ̀, wọ́n sì ṣèrìbọmi.
“Ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tó bá bẹ̀rù [Ọlọ́run] tó sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ ni ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.”—Ìṣe 10:35