Abala Àwọn Ọ̀dọ́
Ọlọ́run Kì Í Ṣe Ojúsàájú
Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sí ariwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ bí àwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bí ohun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.
Àwọn tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn: Kọ̀nílíù, Pétérù
Àkópọ̀: Pétérù tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọlọ́run tí kì í ṣe ojúṣàájú, ó sì wàásù fún Kọ̀nílíù tó jẹ́ Kèfèrí.
1 KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA ÌṢE 10:1-35, 44-48.
Ṣàpèjúwe bí o ṣe rò pé Kọ̀nílíù ṣe rí.
․․․․․
Kí lo kíyè sí nínú ohùn Kọ̀nílíù nígbà tó ń bá áńgẹ́lì náà sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà ní ẹsẹ 3 sí 6?
․․․․․
Irú ìjíròrò wo lo rò pé ó wáyé láàárín Kọ̀nílíù àtàwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ bí ẹsẹ 7 àti 8 ṣe fi hàn?
․․․․․
2 ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.
Kí nìdí tí àpèjúwe tí Ọlọ́run fún Pétérù ní ẹsẹ 10 sí 16 fi gbéṣẹ́? (Ojútùú: Rántí pé Júù ni Pétérù, gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ 14 ṣe fi hàn.)
․․․․․
Irú ànímọ́ wo lo rí nínú Kọ̀nílíù ní ẹsẹ 25? Kí nìdí tí irú ànímọ́ yẹn fi ṣọ̀wọ́n lára àwọn tó wà nírú ipò yẹn? (Ojútùú: Ka ẹsẹ 1.)
․․․․․
Lo àwọn ìwé ìwádìí míì tó o mọ̀ láti fi ṣèwádìí nípa iye àwọn tó máa ń wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ítálì tí Kọ̀nílíù jẹ́ ọ̀gá wọn.
․․․․․
Kí nìdí tí ìyípadà Kọ̀nílíù yìí fi gbàfiyèsí tó bẹ́ẹ̀?
․․․․․
3 MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .
Lílo àpèjúwe lọ́nà tó gbéṣẹ́.
․․․․․
Bí Ọlọ́run kì í ti í ṣe ojúsàájú.
․․․․․
Bí o kò ṣe ní ṣe ojúsàájú.
․․․․․
4 KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?
․․․․․
BÍ O KÒ BÁ NÍ BÍBÉLÌ, LỌ KÀ Á LÓRÍ ÌKÀNNÌ WA, www.watchtower.org