Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 10
Jèhófà ni Ọba tó ju ọba lọ. Látìbẹ̀rẹ̀ títí dòní, òun ni aláṣẹ àti alágbára tó ga jù lọ, òun náà láá sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀ títí láé. Bí àpẹẹrẹ, ó dáàbò bo Jeremáyà kó má bàa kú. Ó tún gba Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò nínú iná tó ń jó lala, òun náà ló sì gba Dáníẹ́lì lọ́wọ́ àwọn kìnnìún. Jèhófà tún dáàbò bo Ẹ́sítà kó lè gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀. Èyí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà ò ní jẹ́ káwọn èèyàn máa hùwà ìkà títí lọ. Jèhófà fi ìran nípa ère ńlá kan àti igi ńlá kan sọ àsọtẹ́lẹ̀. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà sì jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba Jèhófà máa tó pa àwọn èèyàn burúkú run, òun lá sì máa ṣàkóso gbogbo ayé.