ORIN 145
Ọlọ́run Ṣèlérí Párádísè
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jèhófà ṣe ìlérí fún wa
Páyé máa di Párádísè.
Kristi ló máa jẹ́ alákòóso,
Kò ní síkú àtẹ̀ṣẹ̀ mọ́.
(ÈGBÈ)
Ayé yóò di Párádísè.
Pẹ̀lú ‘gbàgbọ́, ó dájú pé
Ó máa rí bẹ́ẹ̀. Jésù yóò ṣeé,
Torí pó máa ńṣe ìfẹ́ Jáà.
2. Kò ní pẹ́ mọ́ nínú ayé yìí,
Jésù yóò jí òkú dìde.
Jésù ti sọ pé: ‘Ìwọ yóò wà
Pẹ̀lú mi ní Párádísè.’
(ÈGBÈ)
Ayé yóò di Párádísè.
Pẹ̀lú ‘gbàgbọ́, ó dájú pé
Ó máa rí bẹ́ẹ̀. Jésù yóò ṣeé,
Torí pó máa ńṣe ìfẹ́ Jáà.
3. Jésù ṣèlérí Párádísè.
Ìṣàkóso rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀.
Ọpẹ́ ni fún Jèhófà Ọba,
Títí ayé laó máa dúpẹ́.
(ÈGBÈ)
Ayé yóò di Párádísè.
Pẹ̀lú ‘gbàgbọ́, ó dájú pé
Ó máa rí bẹ́ẹ̀. Jésù yóò ṣeé,
Torí pó máa ńṣe ìfẹ́ Jáà.
(Tún wo Mát. 5:5; 6:10; Jòh. 5:28, 29.)