APÁ KEJÌ
Ẹ Ti “Sọ Ibi Mímọ́ Mi Di Aláìmọ́”—Ìjọsìn Mímọ́ Di Ẹlẹ́gbin
OHUN TÍ APÁ YÌÍ DÁ LÉ: Júdà àti Jerúsálẹ́mù sọ ara wọn di ẹlẹ́gbin nínú ìwà àti ìjọsìn wọn
Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gan-an, ó sì ṣìkẹ́ wọn bí ohun ìní rẹ̀ “tó ṣeyebíye.” (Ẹ́kís. 19:5, àlàyé ìsàlẹ̀) Àmọ́ ibi ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi san oore tí Jèhófà ṣe fún wọn. Wọ́n sọ tẹ́ńpìlì Jèhófà di ibi ìjọsìn àwọn òrìṣà! Wọ́n ba Jèhófà nínú jẹ́ gan-an, wọ́n sì kó ẹ̀gàn bá a. Kí ló mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì hùwà ìbàjẹ́ tó burú tó báyìí? Kí la rí kọ́ látinú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì nípa bí Jerúsálẹ́mù ṣe máa pa run? Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú àjọṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká?