APÁ KẸTA
‘Màá Kó Yín Jọ’—Ọlọ́run Ṣèlérí Pé Wọ́n Á Tún Pa Dà Ṣe Ìjọsìn Mímọ́
OHUN TÍ APÁ YÌÍ DÁ LÉ: Àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì nípa bí nǹkan ṣe máa pa dà bọ̀ sípò
Ísírẹ́lì ti fọ́n ká, ìpẹ̀yìndà ti kẹ̀yìn wọn síra. Wọ́n ń jìyà ìwàkiwà wọn; wọ́n sọ ìjọsìn mímọ́ di ẹlẹ́gbin, wọ́n sì kó ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run. Ní gbogbo àkókò tó dà bíi pé kò sọ́nà àbáyọ yìí, Jèhófà mú kí Ìsíkíẹ́lì sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan tó fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Jèhófà lo àwọn àfiwé ọ̀rọ̀ tó ń wọni lọ́kàn àtàwọn ìran tó yani lẹ́nu gan-an láti fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà nígbèkùn níṣìírí, títí kan gbogbo àwọn tó ń fojú sọ́nà láti rí bí ìjọsìn mímọ́ ṣe máa pa dà bọ̀ sípò.