APÁ KARÙN-ÚN
‘Èmi Yóò Máa Gbé ní Àárín Àwọn Èèyàn Náà’—Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Pa Dà Bọ̀ Sípò
OHUN TÍ APÁ YÌÍ DÁ LÉ: Àwọn ohun tó wà nínú tẹ́ńpìlì tí Ísíkíẹ́lì rí nínú ìran àti bó ṣe kan ìjọsìn mímọ́
Àwọn ìran tí Jèhófà fi han wòlíì Ìsíkíẹ́lì àti àpọ́sítélì Jòhánù jọra gan-an. Ohun tó wà nínú àwọn ìran yẹn kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì táá mú ká lè sin Jèhófà lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà báyìí, ó sì ń jẹ́ ká lè fojú inú wo bí nǹkan ṣe máa rí nínú Párádísè, lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.