APÁ KÌÍNÍ
“Ọ̀run Ṣí Sílẹ̀”
OHUN TÍ APÁ YÌÍ DÁ LÉ: Ìran nípa ibi tí Jèhófà gúnwà sí
Kò sí èèyàn tó lè rí Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè kó sì wà láàyè. (Ẹ́kís. 33:20) Àmọ́, Jèhófà fi àwọn ìran kan han Ìsíkíẹ́lì tó jẹ́ ká mọ apá ti ọ̀run lára ètò Rẹ̀. Bí àwọn ìran yìí ṣe jẹ́ ká ní ìbẹ̀rù tó yẹ, bẹ́ẹ̀ náà ló jẹ́ ká túbọ̀ mọyì àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tá a ní láti máa sin Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà.