ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 7A
Àwọn Orílẹ̀-èdè Tó Yí Jerúsálẹ́mù Ká
n. 650 sí 300 Ṣ.S.K.
DÉÈTÌ ÌṢẸ̀LẸ̀ (GBOGBO DÉÈTÌ JẸ́ ṢÁÁJÚ SÀNMÁNÌ KRISTẸNI)
620: Bábílónì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso Jerúsálẹ́mù
Nebukadinésárì fi ọba Jerúsálẹ́mù sábẹ́ àkóso ara rẹ̀
617: Ìgbà àkọ́kọ́ tí Bábílónì mú àwọn èèyàn lẹ́rú láti Jerúsálẹ́mù
Wọ́n mú àwọn alákòóso, àwọn jagunjagun tó lákíkanjú àtàwọn oníṣẹ́ ọ̀nà lọ sí Bábílónì
607: Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run
Wọ́n dáná sun ìlú náà àti tẹ́ńpìlì rẹ̀
Lẹ́yìn 607: Tírè, ti orí ilẹ̀
Nebukadinésárì gbógun ti Tírè fún ọdún mẹ́tàlá (13). Ó ṣẹ́gun Tírè orí ilẹ̀, àmọ́ Tírè orí omi ò tíì pa run
602: Ámónì àti Móábù
Nebukadinésárì gbógun ja Ámónì àti Móábù
588: Bábílónì ṣẹ́gun Íjíbítì
Nebukadinésárì gbógun ja Íjíbítì ní ọdún kẹtàdínlógójì (37) ìjọba rẹ̀
332: Tírè, ti orí omi
Àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Gíríìsì tí Alẹkisáńdà Ńlá jẹ́ olórí wọn, pa Tírè orí omi run
332 tàbí ṣáájú: Filísíà
Alẹkisáńdà ṣẹ́gun Gásà, olú ìlú àwọn Filísínì
Àwọn ibi tó wà lórí Àwòrán Ilẹ̀
GÍRÍÌSÌ
ÒKUN ŃLÁ
(ÒKUN MẸDITARÉNÍÀ)
TÍRÈ
Sídónì
Tírè
Samáríà
Jerúsálẹ́mù
Gásà
FILÍSÍÀ
ÍJÍBÍTÌ
BÁBÍLÓNÌ
ÁMÓNÌ
MÓÁBÙ
ÉDÓMÙ