ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌSÍKÍẸ́LÌ 24-27
Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Bí Ìlú Tírè Ṣe Máa Pa Run Mú Ká Fọkàn Tán Ọ̀rọ̀ Jèhófà
Bíi Ti Orí Ìwé
Ìwé Ìsíkíẹ́lì sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ pàtó kan nípa bí ìlú Tírè ṣe máa pa run.
Ní àkókò kan lẹ́yìn ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ta ló pa ìlú Tírè tó wà lórí ilẹ̀ run?
Ní ọdún 332 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ta ló fi àwókù ìlú Tírè tó wà lórí ilẹ̀ la ọ̀nà gba àárín omi kọjá, tó sì pa ìlú Tírè tó wà lórí omi run?