Ẹ̀KỌ́ 17
Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Yéni
1 Kọ́ríńtì 14:9
KÓKÓ PÀTÀKÌ: Ṣàlàyé ọ̀rọ̀ rẹ lọ́nà tó fi máa yé àwọn tí ò ń bá sọ̀rọ̀.
BÓ O ṢE LÈ ṢE É:
Ṣàyẹ̀wò ohun tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ dáadáa. Jẹ́ kí ohun tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yé ẹ débi pé wàá lè fi ọ̀rọ̀ ara rẹ ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà tó rọrùn.
Lo àwọn gbólóhùn tí kò gùn àtàwọn ọ̀rọ̀ tó rọrùn. Òótọ́ ni pé kò sóhun tó burú nínú kí èèyàn lo gbólóhùn gígùn, àmọ́ ọ̀rọ̀ ṣókí ni kó o fi ṣàlàyé àwọn kókó pàtàkì.
Ṣàlàyé ohun tí kò yé àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ. Tó bá ṣeé ṣe, má ṣe lo àwọn ọ̀rọ̀ tí kò ní yé àwọn tí ò ń bá sọ̀rọ̀. Tó bá pọn dandan láti lo irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ tàbí tí o fẹ́ dárúkọ ẹnì kan nínú Bíbélì táwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ àbí o fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa òṣùwọ̀n kan tí wọ́n ń lò láyé àtijọ́ tàbí àṣà àtijọ́ kan, rí i pé o ṣàlàyé rẹ̀.