ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lff ẹ̀kọ́ 5
  • Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Bíbélì Ti Wá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Bíbélì Ti Wá
  • Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
  • KÓKÓ PÀTÀKÌ
  • ṢÈWÁDÌÍ
  • Ṣé Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Ìròyìn Ayọ̀ Ti Wá Lóòótọ́?
    Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
  • Bí O Ṣe Lè Mọ Ohun Tí Ọlọrun Ń Béèrè
    Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
  • Ṣé Bíbélì Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ṣé Bíbélì Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì
Àwọn Míì
Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
lff ẹ̀kọ́ 5
Ẹ̀kọ́ 5. Ọkùnrin kan ń ka Bíbélì nínú mọ́tò.

Ẹ̀KỌ́ 05

Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Bíbélì Ti Wá

Bíi Ti Orí Ìwé
Bíi Ti Orí Ìwé
Bíi Ti Orí Ìwé

Ẹ̀bùn iyebíye kan wà tí Jèhófà fún wa, ẹ̀bùn náà ni ìwé kéékèèké mẹ́rìndínláàádọ́rin (66) tó para pọ̀ di ìwé tá à ń pè ní Bíbélì. O lè máa ronú pé: ‘Báwo ni Bíbélì ṣe dé ọwọ́ wa? Ọ̀rọ̀ ta ló wà nínú ẹ̀?’ Ká lè rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí, jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí Bíbélì ṣe dé ọwọ́ wa.

1. Tó bá jẹ́ pé àwọn èèyàn ló kọ Bíbélì, kí nìdí tá a fi sọ pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló wà nínú ẹ̀?

Nǹkan bí ogójì (40) ọkùnrin ló kọ Bíbélì, ó sì tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (1,600) ọdún tí wọ́n fi kọ ọ́, ìyẹn 1513 Ṣ.S.K. sí nǹkan bíi 98 S.K. Àwọn tó kọ Bíbélì yàtọ̀ síra lóríṣiríṣi ọ̀nà. Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ò ta kora. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló wà nínú Bíbélì. (Ka 1 Tẹsalóníkà 2:13.) Kì í ṣe èrò àwọn tó kọ Bíbélì ló wà níbẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n “sọ̀rọ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe darí wọn.”a (2 Pétérù 1:21) Ọlọ́run lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti mú kí wọ́n kọ èrò rẹ̀ sílẹ̀.​—2 Tímótì 3:16.

2. Ṣe gbogbo èèyàn ni Bíbélì wúlò fún?

Ọlọ́run sọ pé “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti èèyàn” ló máa jàǹfààní látinú ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì. (Ka Ìfihàn 14:6.) Ó sì rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́. Torí pé nínú gbogbo ìwé tó wà láyé lóde òní, Bíbélì ló wà ní èdè tó pọ̀ jù lọ! Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló ní Bíbélì lọ́wọ́ tàbí tí wọ́n ti gbọ́ ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ rí, láìka ibi tí wọ́n ń gbé sí tàbí èdè yòówù kí wọ́n máa sọ.

3. Báwo ni Jèhófà ṣe dáàbò bo Bíbélì?

Orí awọ àti ohun kan tí wọ́n ń pè ní ìwé òrépèté ni wọ́n kọ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì si níbẹ̀rẹ̀. Àmọ́ àwọn nǹkan yìí máa ń tètè gbó. Èyí ló mú kí àwọn tó fẹ́ràn Bíbélì fara balẹ̀ ṣe àdàkọ rẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn aláṣẹ kan ti gbìyànjú láti pa Bíbélì run, síbẹ̀ àwọn kan fẹ̀mí ara wọn wewu kí Bíbélì lè dọ́wọ́ àwọn èèyàn. Jèhófà ò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun dí òun lọ́wọ́ láti bá àwa èèyàn sọ̀rọ̀. Bíbélì sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa máa wà títí láé.”​—Àìsáyà 40:8.

KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

Jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa bí Ọlọ́run ṣe fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí àwọn èèyàn láti kọ Bíbélì, bó ṣe dáàbò bò ó àti bó ṣe jẹ́ kó dé ọwọ́ àwọn èèyàn.

4. Bíbélì jẹ́ ká mọ ọ̀dọ̀ Ẹni tí òun ti wá

Wo FÍDÍÒ yìí. Lẹ́yìn náà, ka 2 Tímótì 3:16, kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

FÍDÍÒ: Ta Ni Òǹṣèwé Bíbélì?​—Àyọlò (2:48)

  • Tó bá jẹ́ pé àwọn èèyàn ló kọ Bíbélì, kí nìdí tá a fi ń pè é ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

  • Ṣó o rò pé ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Ọlọ́run lè fi ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ ránṣẹ́ sáwọn èèyàn kí wọ́n sì kọ ọ́ sílẹ̀?

Ọ̀gá ilé iṣẹ́ kan ń sọ ohun tí akọ̀wé ẹ̀ máa kọ sínú lẹ́tà, akọ̀wé náà sì ń fi kọ̀ǹpútà tẹ ohun tí ọ̀gá rẹ̀ ń sọ.

Akọ̀wé kan lè kọ lẹ́tà, àmọ́ ẹni tó ní kó kọ lẹ́tà náà ló ni ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹ̀. Lọ́nà kan náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ló kọ Bíbélì, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ti wá

5. Bíbélì bọ́ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá

Tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá lóòótọ́, ó yẹ kí Ọlọ́run lè dáàbò bò ó. Ọjọ́ pẹ́ táwọn aláṣẹ kan ti ń gbìyànjú láti pa Bíbélì run. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ò fẹ́ káwọn èèyàn ní Bíbélì lọ́wọ́ rárá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbógun ti àwọn èèyàn, tí wọ́n sì fẹ́ pa wọ́n, àwọn kan fẹ̀mí ara wọn wewu kí wọ́n lè dáàbò bo Bíbélì. Tó o bá fẹ́ mọ̀ nípa ọ̀kan lára àwọn tó fẹ̀mí ara wọn wewu, wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

FÍDÍÒ: Wọ́n Mọyì Bíbélì​—Díẹ̀ Nínú Ìtàn William Tyndale (6:17)

  • Ní báyìí tó o ti mọ ohun tójú àwọn kan rí kí wọ́n lè dáàbò bo Bíbélì, ṣé ìyẹn mú kó túbọ̀ wù ẹ́ láti máa kà á? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

Ka Sáàmù 119:97, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Kí ló mú káwọn kan fẹ̀mí ara wọn wewu kí wọ́n lè túmọ̀ Bíbélì, kí wọ́n sì rí i pé ó dé ọwọ́ àwọn èèyàn?

6. Ìwé kan tó wà fún gbogbo èèyàn

Nínú gbogbo ìwé tó wà láyé, Bíbélì ni ìwé tó dé ibi tó pọ̀ jù lọ, òun ló sì wà ní èdè tó pọ̀ jù lọ! Ka Ìṣe 10:34, 35, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Kí nìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ kí wọ́n túmọ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí èdè tó pọ̀ gan-an, tó sì tún dé ibi tó pọ̀ jù lọ láyé?

  • Kí ló mú kó o fẹ́ràn Bíbélì?

Àwọn èèyàn tí ẹ̀yà àti èdè wọn yàtọ̀ síra ń ka Bíbélì ní èdè àbínibí wọn.

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé

gbogbo èèyàn

tó wà láyé

ló ní Bíbélì lédè tó yé wọn

Bíbélì wà ní

èdè tó lé ní

3,000

lódindi tàbí lápá kan

5,000,000,000

Èyí ni iye tí wọ́n ṣírò pé wọ́n ti tẹ̀ jáde,

kò sí ìwé míì láyé tí iye ẹ̀ pọ̀ tó yẹn

ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Ìwé àtijọ́ kan lásán táwọn èèyàn kọ ni Bíbélì jàre.”

  • Kí lèrò tìẹ?

  • Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì?

KÓKÓ PÀTÀKÌ

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì, ó sì rí i dájú pé ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo èèyàn.

Kí lo rí kọ́?

  • Kí ló túmọ̀ sí nígbà tá a sọ pé Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí àwọn èèyàn láti kọ Bíbélì?

  • Kí ló wú ẹ lórí nípa bí Bíbélì ṣe wà títí dòní, iye èdè tó wà àti iye èèyàn tó ní in lọ́wọ́?

  • Báwo ló ṣe rí lára ẹ nígbà tó o mọ ohun tí Ọlọ́run ti ṣe kó lè máa bá ẹ sọ̀rọ̀?

Ohun tó yẹ kó o ṣe

ṢÈWÁDÌÍ

Kà nípa bí wọ́n ṣe túmọ̀ Bíbélì látinú àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ sáwọn èdè tá à ń sọ lóde òní.

“Bí Bíbélì Ṣe Tẹ̀ Wá Lọ́wọ́” (Jí!, November 2007)

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Bíbélì ṣe bọ́ lọ́wọ́ ohun mẹ́ta tó fẹ́ pa á run.

“Bí Ọlọ́run Ṣe Pa Bíbélì Mọ́” (Ilé Ìṣọ́ No. 4 2016)

Wo fídíò yìí kó o lè mọ báwọn kan ṣe fẹ̀mí ara wọn wewu kí wọ́n lè túmọ̀ Bíbélì.

Wọ́n Mọyì Bíbélì (14:26)

Wọ́n ti ṣàdàkọ Bíbélì, wọ́n sì ti túmọ̀ rẹ̀ sí ọ̀pọ̀ èdè. Kí ló lè mú kó dá ẹ lójú pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà nínú rẹ̀ ò tíì yí pa dà?

“Ṣé Wọ́n Ti Yí Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì Pa Dà?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

a Bá a ṣe máa rí i ní ẹ̀kọ́ 7, ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ agbára tí Ọlọ́run fi ń ṣiṣẹ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́