OHUN TÓ O KỌ́ NÍ APÁ 3
Kí ìwọ àti ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ jíròrò àwọn ìbéèrè yìí:
Ka Òwe 27:11.
Kí nìdí tó o fi fẹ́ máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà nígbà gbogbo?
(Wo Ẹ̀kọ́ 34.)
Báwo lo ṣe lè ṣe ìpinnu tó dáa tí Bíbélì ò bá tiẹ̀ sọ ohun tó yẹ kó o ṣe ní pàtó?
(Wo Ẹ̀kọ́ 35.)
Báwo lo ṣe lè jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo?
(Wo Ẹ̀kọ́ 36.)
Ka Mátíù 6:33.
Báwo lo ṣe lè “máa wá Ìjọba náà . . . lákọ̀ọ́kọ́” tó bá kan ọ̀rọ̀ iṣẹ́ àti owó?
(Wo Ẹ̀kọ́ 37.)
Àwọn nǹkan wo la lè ṣe láti fi hàn pé ẹ̀mí ṣeyebíye sí wa bó ṣe ṣeyebíye sí Jèhófà?
(Wo Ẹ̀kọ́ 38.)
Ka Ìṣe 15:29.
Báwo lo ṣe lè ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run nípa ẹ̀jẹ̀?
Ṣé o rò pé òfin tí Jèhófà fún wa nípa ẹ̀jẹ̀ bọ́gbọ́n mu?
(Wo Ẹ̀kọ́ 39.)
Ka 2 Kọ́ríńtì 7:1.
Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn jẹ́ mímọ́ nípa tara, nínú èrò, ọ̀rọ̀ àti ìṣe?
(Wo Ẹ̀kọ́ 40.)
-
Kí ni Bíbélì sọ nípa ìbálòpọ̀? Ṣé o fara mọ́ ọn?
Ìtọ́ni wo ni Bíbélì fún wa nípa ọtí mímu?
Ka Mátíù 19:4-6, 9.
Kí ni Ọlọ́run sọ nípa ìgbéyàwó?
Kí nìdí tó fi yẹ kéèyàn ṣègbéyàwó lọ́nà tó bá òfin ìjọba mu, kí sì nìdí tó fi yẹ kí àwọn tó bá fẹ́ kọ ara wọn sílẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó bá òfin ìjọba mu?
(Wo Ẹ̀kọ́ 42.)
Sọ díẹ̀ lára àwọn ayẹyẹ tínú Ọlọ́run ò dùn sí. Kí nìdí tínú Ọlọ́run ò fi dùn sí wọn?
(Wo Ẹ̀kọ́ 44.)
Ka Jòhánù 17:16 àti Ìṣe 5:29.
Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o ò dá sí ogun àti ọ̀rọ̀ òṣèlú?
Kí ni wàá ṣe táwọn aláṣẹ bá ní kó o ṣe ohun tó ta ko òfin Ọlọ́run?
(Wo Ẹ̀kọ́ 45.)
Ka Máàkù 12:30.
Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?