OHUN TÓ O KỌ́ NÍ APÁ 4
Kí ìwọ àti ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ jíròrò àwọn ìbéèrè yìí:
Ka Òwe 13:20.
Kí nìdí tó fi yẹ kó o ronú jinlẹ̀ kó o tó yan ọ̀rẹ́?
(Wo Ẹ̀kọ́ 48.)
Ìmọ̀ràn Bíbélì wo ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá jẹ́ . . .
ọkọ tàbí aya?
òbí tàbí ọmọ?
Irú àwọn ọ̀rọ̀ wo ló máa ń múnú Jèhófà dùn? Irú àwọn ọ̀rọ̀ wo ni Jèhófà kórìíra?
(Wo Ẹ̀kọ́ 51.)
Àwọn ìlànà wo ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá fẹ́ pinnu irú aṣọ tá a máa wọ̀ àti bá a ṣe máa múra?
(Wo Ẹ̀kọ́ 52.)
Báwo lo ṣe lè yan eré ìnàjú táá múnú Jèhófà dùn?
(Wo Ẹ̀kọ́ 53.)
Ka Mátíù 24:45-47.
Ta ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye”?
(Wo Ẹ̀kọ́ 54.)
Báwo la ṣe lè lo okun, àkókò, àti ohun ìní wa láti ṣètìlẹyìn fún ìjọ?
(Wo Ẹ̀kọ́ 55.)
Ka Sáàmù 133:1.
Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan lè túbọ̀ wà nínú ìjọ?
(Wo Ẹ̀kọ́ 56.)
Àwọn nǹkan wo la lè ṣe kí Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an?
(Wo Ẹ̀kọ́ 57.)
Ka 1 Kíróníkà 28:9.
Báwo la ṣe lè fi hàn pé “gbogbo ọkàn” la fi ń sin Jèhófà táwọn kan bá ń ta ko ìjọsìn tòótọ́ tàbí fi Jèhófà sílẹ̀?
Ṣé àwọn àyípadà kan wà tó yẹ kó o ṣe kó o lè máa jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, kó o sì lè dúró lórí ìpinnu rẹ̀ pé o ò fẹ́ ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ẹ̀sìn èké?
(Wo Ẹ̀kọ́ 58.)
Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe láti múra sílẹ̀ de inúnibíni?
(Wo Ẹ̀kọ́ 59.)
Àwọn nǹkan wo lo ti pinnu láti ṣe kó o lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?
(Wo Ẹ̀kọ́ 60.)