ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lmd ẹ̀kọ́ 5
  • Máa Fọgbọ́n Bá Àwọn Èèyàn Sọ̀rọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Fọgbọ́n Bá Àwọn Èèyàn Sọ̀rọ̀
  • Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Pọ́ọ̀lù Ṣe
  • Kí La Rí Kọ́ Lára Pọ́ọ̀lù?
  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù
  • Ẹ Wá Ọlọ́run, Kẹ́ Ẹ sì Rí I Ní Ti Gidi
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
  • Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀
    Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
  • Ojú Wo Lo Fi Ń Wo Àwọn Tó Wà ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Rẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • “Máa Bá A Lọ ní Fífi Ara Rẹ . . . fún Kíkọ́ni”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
lmd ẹ̀kọ́ 5

BÁ A ṢE LÈ BẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ WA

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń fọgbọ́n bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nílùú Áténì.

Ìṣe 17:22, 23

Ẹ̀KỌ́ 5

Máa Fọgbọ́n Bá Àwọn Èèyàn Sọ̀rọ̀

Ìlànà: “Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín máa jẹ́ ọ̀rọ̀ onínúure.”—Kól. 4:6.

Ohun Tí Pọ́ọ̀lù Ṣe

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń fọgbọ́n bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nílùú Áténì.

FÍDÍÒ: Pọ́ọ̀lù Wàásù fún Àwọn Ará Áténì

1. Wo FÍDÍÒ yìí, tàbí kó o ka Ìṣe 17:22, 23. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  1. Báwo ló ṣe rí lára Pọ́ọ̀lù nígbà tó rí i pé òrìṣà làwọn ará Áténì ń jọ́sìn?—Wo Ìṣe 17:16.

  2. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fọgbọ́n lo ohun táwọn ará Áténì gbà gbọ́ láti fi wàásù fún wọn dípò kó dá wọn lẹ́jọ́?

Kí La Rí Kọ́ Lára Pọ́ọ̀lù?

2. Àwọn èèyàn máa fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa tá a bá fara balẹ̀ ronú lórí ohun tá a fẹ́ sọ, bá a ṣe máa sọ ọ́ lọ́nà tó dáa àti ìgbà tá a fẹ́ sọ ọ́.

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù

3. Fọgbọ́n gbé ọ̀rọ̀ ẹ kalẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń bá ẹni tí kì í ṣe Kristẹni sọ̀rọ̀, ó lè gba pé ká fọgbọ́n gbé ọ̀rọ̀ wa kalẹ̀ nígbà tá a bá fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì tàbí nípa Jésù.

4. Máa ní sùúrù tẹ́nì kan bá sọ ohun tí kò tọ̀nà. Mú kára tu ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ kó lè sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀. Tẹ́ni náà bá tiẹ̀ sọ ohun tí kò bá Bíbélì mu, má bá a jiyàn. (Jém. 1:19) Tó o bá fara balẹ̀ tẹ́tí sí i, wàá lè mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀ àtohun tó gbà gbọ́.—Òwe 20:5.

5. Gbóríyìn fún ẹni náà, kó o sì fara mọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀ tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Ó lè jẹ́ pé tọkàntọkàn ló fi gba ohun tí wọ́n kọ́ ọ nínú ẹ̀sìn ẹ̀. Torí náà, bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ níbi tọ́rọ̀ yín ti jọra. Bẹ́ ẹ sì ṣe ń bá ìjíròrò yín lọ, máa ràn án lọ́wọ́ kó lè mọ ohun tí Bíbélì kọ́ni.

TÚN WO

Òwe 25:15; 2 Tím. 2:23-26; 1 Pét. 3:15

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́