ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lmd ẹ̀kọ́ 4
  • Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀
  • Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Pọ́ọ̀lù Ṣe
  • Kí La Rí Kọ́ Lára Pọ́ọ̀lù?
  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù
  • Eeṣe Ti A Fi Nilati Gbé Irẹlẹ Wọ̀?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Jèhófà Mọyì Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Tó Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Àwọn Àpẹẹrẹ Ìrẹ̀lẹ̀-Ọkàn Láti Ṣàfarawé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ní Ojúlówó Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
lmd ẹ̀kọ́ 4

BÁ A ṢE LÈ BẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ WA

Wọ́n so ọwọ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ́ ẹ̀ṣọ́ kan, ó sì ń fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ̀rọ̀ níwájú Ọba Ágírípà, Gómìnà Fẹ́sítọ́ọ̀sì àti Bẹ̀níìsì.

Ìṣe 26:2, 3

Ẹ̀KỌ́ 4

Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀

Ìlànà: “Ẹ jẹ́ kí ìrẹ̀lẹ̀ máa mú kí ẹ gbà pé àwọn míì sàn jù yín lọ.”—Fílí. 2:3.

Ohun Tí Pọ́ọ̀lù Ṣe

Wọ́n so ọwọ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ́ ẹ̀ṣọ́ kan, ó sì ń fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ̀rọ̀ níwájú Ọba Ágírípà, Gómìnà Fẹ́sítọ́ọ̀sì àti Bẹ̀níìsì.

FÍDÍÒ: Pọ́ọ̀lù Wàásù fún Ọba Ágírípà

1. Wo FÍDÍÒ yìí, tàbí kó o ka Ìṣe 26:2, 3. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  1. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ nígbà tó ń bá Ọba Ágírípà sọ̀rọ̀?

  2. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Jèhófà àti Ìwé Mímọ́ lòun gbára lé?—Wo Ìṣe 26:22.

Kí La Rí Kọ́ Lára Pọ́ọ̀lù?

2. Tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tá a sì ń bọ̀wọ̀ fáwọn tá à ń bá sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ wa máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn.

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù

3. Má ṣe máa fojú pa àwọn èèyàn rẹ́. Má wo ara ẹ bíi pé o ti mọ gbogbo nǹkan tán, má sì wo àwọn míì bíi pé wọn ò mọ nǹkan kan. Máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.

4. Jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé inú Bíbélì ni ọ̀rọ̀ rẹ ti wá. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń wọni lọ́kàn gan-an. Torí náà, tó bá jẹ́ pé ohun tó wà nínú Bíbélì lò ń kọ́ àwọn èèyàn, ìgbàgbọ́ wọn á túbọ̀ lágbára.

5. Máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́. Má ṣe fi dandan mú àwọn èèyàn láti fara mọ́ ohun tó o sọ, má sì máa bá àwọn èèyàn jiyàn. Tó o bá ń ní sùúrù lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, tó o sì ń tètè kúrò níbì kan kọ́rọ̀ tó di wàhálà, wàá fi hàn pé onírẹ̀lẹ̀ ni ẹ́. (Òwe 17:14; Títù 3:2) Tó o bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́, èyí lè mú kó wù wọ́n láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ nígbà míì.

TÚN WO

Róòmù 12:16-18; 1 Kọ́r. 8:1; 2 Kọ́r. 3:5

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́