ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 12/1 ojú ìwé 14-19
  • Àwọn Àpẹẹrẹ Ìrẹ̀lẹ̀-Ọkàn Láti Ṣàfarawé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Àpẹẹrẹ Ìrẹ̀lẹ̀-Ọkàn Láti Ṣàfarawé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jehofa Ọlọrun Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀-Ọkàn
  • Àpẹẹrẹ Ìrẹ̀lẹ̀-Ọkàn Kristi
  • Aposteli Paulu, Àpẹẹrẹ Ìrẹ̀lẹ̀-Ọkàn Rere
  • Àwọn Àpẹẹrẹ Òde-Òní
  • Ní Ojúlówó Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Eeṣe Ti A Fi Nilati Gbé Irẹlẹ Wọ̀?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Jèhófà Mọyì Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Tó Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Jésù Kọ́ Wa Láti Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 12/1 ojú ìwé 14-19

Àwọn Àpẹẹrẹ Ìrẹ̀lẹ̀-Ọkàn Láti Ṣàfarawé

“Ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn rẹ yóò . . . sọ mi di ńlá.”—ORIN DAFIDI 18:35, NW.

1. Ẹ̀rí ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn wo ni a lè rí lára ààrẹ̀ Watch Tower Society tẹ́lẹ̀rí kan?

JOSEPH F. RUTHERFORD ní ìrísí apàfiyèsí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ ẹni tí ó ga ju ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà tí ó sì wọ̀n ju 90 kílógráàmù fíìfíì. Ó tún ní ohùn tí ó rinlẹ̀ gbingbin, èyí tí òun kò lò láti sọ orúkọ Jehofa di mímọ̀ lọ́nà tí a kò tíì gbà sọ ọ́ di mímọ̀ rí nìkan ṣùgbọ́n láti tún túdìí-àṣírí ìṣekuṣẹyẹ àwọn aṣáájú ìsìn Kristẹndọm, ní pípe ìsìn wọn ní “ìkẹkùn àti wàyó.” Ṣùgbọ́n bí àwọn ọ̀rọ̀-ẹnu rẹ̀ ti lágbára tóo nì, nígbà tí ó bá ń gbàdúrà pẹ̀lú ìdílé Beteli ní orílé-iṣẹ́, ohùn rẹ̀ máa ń dún gẹ́lẹ́ bíi ti ọmọdékùnrin kékeré kan tí ń bá dádì rẹ̀ sọ̀rọ̀, ní títipa báyìí fi ẹ̀rí ipò-ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Olùṣẹ̀dá rẹ̀ àti ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn rẹ̀ hàn. Bẹ́ẹ̀ni, ó ní ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn bíi ti ọmọ kékeré kan.—Matteu 18:3, 4.

2. Ní ọ̀nà pàtàkì wo ni àwọn ìránṣẹ́ Jehofa gbà dúró ní ìyàtọ̀ gedegbe sí àwọn ènìyàn nínú ayé?

2 Láìṣíyèméjì, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ tòótọ́ fún Jehofa Ọlọrun jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn. Ní ọ̀nà yìí wọ́n yàtọ̀ gedegbe sí àwọn ènìyàn ayé. Lónìí, ju ti ìgbàkígbà rí lọ, ó kún fún àwọn agbéraga ènìyàn. Àwọn ènìyàn jàǹkànjàǹkàn àti alágbára, àwọn ọlọ́rọ̀ àti ọ̀mọ̀wé, ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n jẹ́ òtòṣì pàápàá àti àwọn wọnnì tí wọn kò rí bátiṣe ní ọ̀nà mìíràn jẹ́ agbéraga.

3. Kí ni a lè sọ nípa àwọn èso ìgbéraga?

3 Ìgbéraga máa ń fa gbólóhùn-asọ̀ àti ìrora-ọkàn púpọ̀. Nítòótọ́, gbogbo ègbé tí ń bẹ lágbàáyé ní ìbẹ̀rẹ̀ wọn nítorí pé angeli kan báyìí di agbéraga, ní fífẹ́ kí a jọ́sìn òun ní ọ̀nà tí ó jẹ́ ti Ẹlẹ́dàá nìkanṣoṣo, Jehofa Ọlọrun. (Matteu 4:9, 10) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹni yẹn, tí ó sọ araarẹ̀ di Eṣu àti Satani, kẹ́sẹjárí nínú yíyí èrò obìnrin àkọ́kọ́ náà, Efa, padà láti dẹ́ṣẹ̀ nípa fífọ̀rànlọ ìgbéraga rẹ̀. Ó ṣèlérí fún un pé bí ó bá jẹ nínú èso tí a kàléèwọ̀ náà, òun lè dàbí Ọlọrun gan-an, ní mímọ rere àti búburú. Bí òun bá ti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn ni, òun ìbá ti sọ pé, ‘Èéṣe tí èmi ó fi fẹ́ láti dàbí Ọlọrun?’ (Genesisi 3:4, 5) Nígbà tí a bá gbé ipò òṣì nípa ti ara, èrò-orí, àti ìwàhíhù, tí aráyé wà nínú rẹ̀ yẹ̀wò, báwo ni ìgbéraga ti jẹ́ ohun tí àwọn ènìyàn kò lè wá àwáwí fún tó! Abájọ tí a fi kà pé Jehofa kórìíra “ìrera àti ìgbéraga”! (Owe 8:13) Ìyàtọ̀ gedegbe sí gbogbo àwọn agbéraga ni àwọn àpẹẹrẹ ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn tí a rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli jẹ́.

Jehofa Ọlọrun Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀-Ọkàn

4. Àwọn ẹsẹ ìwé-mímọ́ wo ni ó fihàn pé Jehofa jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn?

4 Jehofa Ọlọrun—Ẹni Gíga Jùlọ, Ọba-Aláṣẹ Àgbáyé, Ọba ayérayé—jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn. (Genesisi 14:22) Ó ha ṣeéṣe pé kí ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ bí? Bẹ́ẹ̀ni, nítòótọ́! Ọba Dafidi sọ, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ ní Orin Dafidi 18:35 (NW) pé: “Ìwọ yóò fún mi ní apata ìgbàlà rẹ, ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì mú mi dúró, ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn rẹ yóò sì sọ mi di ńlá.” Lọ́nà tí ó ṣe kedere, Ọba Dafidi kà á sí pé ìrẹ̀lẹ̀-ọ̀kan Jehofa ni ó sọ òun, Dafidi, di ńlá. Lẹ́yìn náà, a tún kà nínú Orin Dafidi 113:6 pé Jehofa “rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ láti wo ohun tí ó wà ní ọ̀run àti ní ayé.” Àwọn ìtumọ̀ mìíràn kà pé, “bẹ̀rẹ̀mọ́lẹ̀ láti wò,” (New International Version) “tẹ araarẹ̀ wálẹ̀ láti wo ìsàlẹ̀ rẹlẹ̀-rẹlẹ̀ gan-an.”—The New English Bible.

5. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni ó jẹ́rìí sí ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn Jehofa?

5 Dájúdájú Jehofa Ọlọrun rẹ araarẹ̀ wálẹ̀ ní ọ̀nà tí ó gbà bá Abrahamu lò, ní fífàyègba Abrahamu láti gbé ìbéèrè dìde sí ìwà-òdodo Rẹ̀ níti pípète láti pa àwọn ìlú-ńlá Sodomu àti Gomora bíburúbàlùmọ̀ run.a (Genesisi 18:23-32) Nígbà tí Jehofa sì sọ ìtẹ̀sí rẹ̀ jáde láti pa orílẹ̀-èdè Israeli run—ní ìgbà kan nítorí ìbọ̀rìṣà, nígbà mìíràn nítorí ọ̀tẹ̀—Mose bá Jehofa ronú pọ̀ ní àkókò-ìṣẹ̀lẹ̀ kọ̀ọ̀kan bí ẹni pé ó ń bá ènìyàn mìíràn kan sọ̀rọ̀. Ní ìgbà kọ̀ọ̀kan Jehofa fi ojúrere dáhùnpadà. Fún Un láti gba ẹ̀bẹ̀ Mose nípa àwọn ènìyàn Rẹ̀ Israeli fi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn hàn. (Eksodu 32:9-14; Numeri 14:11-20) Àwọn àpẹẹrẹ mìíràn nípa fífi tí Jehofa fi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn bá àwọn ènìyàn lò lórí ìpìlẹ̀ ti ẹnìkan sí ẹnìkan, bí a ṣe lè sọ pé ó jẹ́, ní a lè rí nínú àjọsepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Gideoni àti Jona, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ ní Awọn Onidajọ 6:36-40 àti Jona 4:9-11.

6. Àmì-ànímọ́ Jehofa wo ni ó ṣípayá ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn rẹ̀ síwájú síi?

6 Níti tòótọ́, ó kérétán ní ìgbà mẹ́sàn-án, Jehofa ni a sọ pé ó “lọ́ra láti bínú.” (NW)b Jíjẹ́ tí Jehofa jẹ́ onípamọ́ra, tí ó lọ́ra láti bínú, ní bíbá àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé lò jálẹ̀ ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rúndún jẹ́ ẹ̀rí síwájú síi nípa jíjẹ́ tí ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn. Àwọn agbéraga ènìyàn jẹ́ aláìnísùúrù, wọn tètè máa ń fi ìhónú hàn, èyí tí ó yàtọ̀ pátápátá sí ìpamọ́ra. Ẹ wo bí ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn Jehofa ti mú kí ìgbéraga àwọn ènìyàn aláìpé jẹ́ èyí tí ó lòdì sọ́gbọ́n tó! Níwọ̀n bí a ti sọ fún wa láti “máa ṣe àfarawé Ọlọrun bí àwọn ọmọ ọ̀wọ́n,” a gbọ́dọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn àní bí òun ti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn.—Efesu 5:1.

Àpẹẹrẹ Ìrẹ̀lẹ̀-Ọkàn Kristi

7, 8. Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ nípa ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn Jesu Kristi?

7 Àpẹẹrẹ ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn yíyàtọ̀ gedegbe jùlọ kejì fún wa láti ṣàfarawé ni a mẹ́nukàn ní 1 Peteru 2:21 (NW) pé: “Níti tòótọ́, ipaọ̀nà yìí ni a pè yín sí, nítorí Kristi pàápàá jìyà fún yín, ní fífi àwòṣe sílẹ̀ fún yín láti tẹ̀lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ tímọ́tímọ́.” Tipẹ́ ṣáájú kí ó tó wá sórí ilẹ̀-ayé gẹ́gẹ́ bí ènìyàn, a sọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ ní Sekariah 9:9 pé: “Hó, Ìwọ ọmọbìnrin Jerusalemu: kíyèsí i, Ọba rẹ ń bọ̀wá sọ́dọ̀ rẹ: òdodo ni òun, ó sì ní ìgbàlà; ó ní [ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn, NW], ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.” Bí Jesu Kristi bá jẹ́ agbéraga ni, ó ti ṣeéṣe pẹ̀lú pé kí ó tẹ́wọ́gba gbogbo ìjọba ayé ti Eṣu fi lọ̀ ọ́ ní pàṣípààrọ̀ fún ìṣe ìjọsìn kan. (Matteu 4:9, 10) Ó tún fi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn rẹ̀ hàn nípa kíka gbogbo ìyìn-ọlá fún ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sí ti Jehofa, ní wíwí pé: “Nígbà tí ẹ bá gbé Ọmọ-Ènìyàn sókè, nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ pé, èmi ni, àti pé èmi kò dá ohunkóhun ṣe fún ara mi; ṣùgbọ́n bí Baba ti kọ́ mi, èmi ń sọ nǹkan wọ̀nyí.”—Johannu 8:28.

8 Òun lè fi pẹ̀lú ẹ̀tọ́ sọ fún àwọn tí ń tẹ́tísílẹ̀ sí i pé: “Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì máa kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi; nítorí onínú tútù àti onírẹ̀lẹ̀-ọkàn ni èmi; ẹ̀yin ó sì rí ìsinmi fún ọkàn yín.” (Matteu 11:29) Irú àpẹẹrẹ ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn wo ni òun sì fi lélẹ̀ nípa wíwẹ ẹsẹ̀ àwọn aposteli rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ tí ó fi wà pẹ̀lú wọn gbẹ̀yìn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn! (Johannu 13:3-15) Lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú jùlọ, ní Fillipi 2:3-8 (NW), aposteli Paulu gba àwọn Kristian nímọ̀ràn láti ní “ìrẹ̀lẹ̀ èrò-inú,” ní títọ́ka sí Jesu Kristi gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ kan: “Ẹ pa ẹ̀mí-ìrònú èrò-orí yìí mọ́ nínú yín èyí tí ó wà nínú Kristi Jesu pẹ̀lú, ẹni tí, bí ó tilẹ̀ wà ní àwòrán-ìrísí Ọlọrun, kò fi ìṣàrò kankan fún ìjá-nǹkan-gbà, èyíinì ni, pé òun níláti bá Ọlọrun dọ́gba. Bẹ́ẹ̀kọ́, ṣùgbọ́n ó sọ ara rẹ̀ dòfo ó sì mú àwòrán-ìrísí ẹrú ó sì wá wà ní jíjọ àwọn ènìyàn. Ju èyíinì lọ, nígbà tí ó rí ara rẹ̀ ní àwọ̀-ẹ̀dá bí ènìyàn, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ó sì di onígbọràn títí dé ojú ikú, bẹ́ẹ̀ni, ikú lórí òpó-igi ìdálóró.” Nígbà tí ó dojúkọ ọ̀gẹ́g̣ẹ́rẹ́ pàtàkì títóbi jùlọ nínú ìgbésí-ayé rẹ̀, ó fi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn gbàdúrà sí Baba rẹ̀ pé: ‘Kí ó má ṣe bí èmi ti ń fẹ́, bíkòṣe bí ìwọ ti fẹ́.’ (Matteu 26:39) Dájúdájú láìsí iyèméjì, fún wa láti jẹ́ aláfarawé Jesu Kristi, ní títẹ̀lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ tímọ́tímọ́, a gbọ́dọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn.

Aposteli Paulu, Àpẹẹrẹ Ìrẹ̀lẹ̀-Ọkàn Rere

9-12. Ní àwọn ọ̀nà wo ni aposteli Paulu gbà fi àpẹẹrẹ ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn rere lélẹ̀?

9 Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Ẹ máa ṣe àfarawé mi, àní gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń ṣe àfarawé Kristi.” (1 Korinti 11:1) Aposteli Paulu ha ṣàfarawé Jesu Kristi nípa jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀ èrò-inú, ní títipa bẹ́ẹ̀ fún wa ní àpẹẹrẹ ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn mìíràn láti ṣàfarawé bí? Lọ́nà tí ó dájú jùlọ ó ṣe bẹ́ẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó fi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn gbà pé òun jẹ́ ẹrú Jesu Kristi. (Fillipi 1:1) Ó sọ fún àwọn alàgbà ní Efesu nípa ‘ṣíṣe tí ó ṣe ẹrú fún Oluwa pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò-inú gíga jùlọ àti ẹkún àti ìdánwò tí ó dé bá a nípa rìkíṣí àwọn Ju.’ (Iṣe 20:17-19, NW) Kí a sọ pé òun kìí ṣe onírẹ̀lẹ̀-ọkàn ni, òun kì bá tí kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí a rí ní Romu 7:18, 19 pé: “Èmi mọ̀ pé kò sí ohun rere kan tí ń gbé inú mi, èyíinì nínú ara mi . . . Nítorí ire tí èmi fẹ́ èmi kò ṣe: ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò fẹ́, èyíinì ni èmi ń ṣe.”

10 Ohun tí ó tún fi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn Paulu hàn ni oun tí ó kọ̀wé rẹ̀ sí àwọn Kristian ní Korinti, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní 1 Korinti 2:3 pé: “Èmi sì wà pẹ̀lú yín ní àìlera, àti ní ẹ̀rù, àti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwárìrì.” Ní fífi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn tọ́kasí ipa-ọ̀nà rẹ̀ àtijọ́ ṣáájú kí ó tó di Kristian, ó kọ̀wé pé: “Bí mo tilẹ̀ jẹ́ asọ̀rọ̀-òdì tẹ́lẹ̀rí àti onínúnibíni àti aláfojúdi ènìyàn. . . . Kristi Jesu wá sí ayé láti gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ là. Láàárín àwọn wọ̀nyí èmi ni ẹni àkọ́kọ́.”—1 Timoteu 1:13, 15, NW.

11 Èyí tí ó tún ń fi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn rẹ̀ hàn síwájú síi ni kíkà tí ó ka ọlá gbogbo àṣeyọrísírere nínú àwọn ìsapá rẹ̀ sí ti Jehofa Ọlọrun. Ó kọ̀wé nípa iṣẹ́-òjísẹ́ rẹ̀ pé: “Èmi gbìn, Apollo bomirin; ṣùgbọ́n Ọlọrun ni ń mú ìbísí wá. Ǹjẹ́ kìí ṣe ẹni tí ó ń gbìn nǹkankan, bẹ́ẹ̀ ni kìí ṣe ẹni tí ń bomirin; bíkòṣe Ọlọrun tí ó ń mú ìbísí wá.” (1 Korinti 3:6, 7) Ó tún ní kí àwọn arákùnrin òun gbàdúrà fún òun kí òun baà lè fúnni ní ẹ̀rí rere, gẹ́gẹ́ bí a ti kà ní Efesu 6:18-20 pé: “Ẹ máa gbàdúrà . . . fún mi, kí a lè fi ohùn fún mi . . . kí èmi kí ó lè máa fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nínú [àṣírí mímọ́-ọlọ́wọ̀ ti ìhìnrere, NW] gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi láti máa sọ.”

12 Paulu tún fi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn rẹ̀ hàn ní ọ̀nà tí ó gbà fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn aposteli yòókù: “Jakọbu, àti Kefa, àti Johannu . . . fi ọwọ́ ọ̀tún ìdàpọ̀ fún èmi àti Barnaba, pé kí àwa kí ó máa lọ sọ́dọ̀ àwọn Keferi, àti àwọn sọ́dọ̀ àwọn onílà.” (Galatia 2:9) Ó fi ìmúratán rẹ̀ láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà ìjọ Jerusalemu hàn síwájú síi nípa bíbá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mẹ́rin wọnú tẹ́ḿpìlì àti sísan ohun tí ó ná wọn bí wọ́n ti ń mú ẹ̀jẹ́ kan ṣẹ.—Iṣe 21:23-26.

13. Kí ni ó mú kí ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn Paulu pẹtẹrí tóbẹ́ẹ̀?

13 Ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn Paulu tún pẹtẹrí lọ́pọ̀lọpọ̀ síi nígbà tí a bá kíyèsí bí Jehofa Ọlọrun ṣe lò ó lọ́nà ribiribi tó. Fún àpẹẹrẹ, a kà pé “Ọlọrun sì ti ọwọ́ Paulu ṣe iṣẹ́ àṣẹ àkànṣe.” (Iṣe 19:11, 12) Ju ìyẹn lọ, a fún un ní àwọn ìran àti ìṣípayá tí ó ju ti ẹ̀dá lọ. (2 Korinti 12:1-7) A kò tún níláti gbójúfo mímí tí a mísí i láti kọ 14 nínú àwọn ìwé 27 (àwọn lẹ́tà níti gidi) nínú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki dá. Gbogbo ìyẹn kò mú kí ó wúga, kí a sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀. Ó ń ní ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn nìṣó.

Àwọn Àpẹẹrẹ Òde-Òní

14-16. (a) Báwo ni ààrẹ Watch Tower Society àkọ́kọ́ ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn rere? (b) Àpẹẹrẹ rẹ̀ dúró ní ìyàtọ̀ gedegbe sí ti ta ni?

14 Ní Heberu 13:7 (NW), a ka ìmọ̀ràn aposteli Paulu pé: “Ẹ rántí àwọn wọnnì tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, àwọn tí wọ́n ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun fún yín, bí ẹ̀yin sì ti ń da bí ìwà wọn ti jásí rò ẹ máa ṣàfarawé ìgbàgbọ́ wọn.” Ní ìbáramu pẹ̀lú ìlànà-ìpìlẹ̀ yìí, a lè mú ààrẹ àkọ́kọ́ ti Watch Tower Bible and Tract Society, Charles Taze Russell, ẹni ti a lè ṣàfarawé ìgbàgbọ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ òde-òní kan. Òun ha jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn bí? Nítòótọ́ ó jẹ́ bẹ́ẹ̀! Gẹ́gẹ́ bí a ti kíyèsí i dáradára, nínú kókó-ọ̀rọ̀-ìwé Studies in the Scriptures tí ó kọ, ìdìpọ̀ ìwé mẹ́fà tí ó ní ojú-ewé bíi 3,000, kò tilẹ̀ tọ́ka sí araarẹ̀ lẹ́ẹ̀kanṣoṣo péré. Àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower Bible and Tract Society lónìí tẹ̀lé ìlànà-ìpìlẹ̀ yìí níti ṣíṣàì darí àfiyèsí sí àwọn ènìyàn nípa fífi àwọn òǹkọ̀wé àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ wọn hàn.

15 Nínú Ile-iṣọ Na, Russell kọ̀wé nígbà kan rí pé òun kò mọ irú ohun kan bíi “ìsìnRussell” àti “ọmọlẹ́yìn Russell,” àwọn èdè-ìsọ̀rọ̀ tí àwọn alátakò rẹ̀ lò ṣùgbọ́n tí òun kọ̀ ní pàtó. Ó kọ̀wé pé: “Iṣẹ́ wa . . . ti jẹ́ láti kó àwọn èérún òtítọ́ tí a ti fọ́nkáàkiri tipẹ́tipẹ́ jọpọ̀ kí a sì gbé wọn kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn Oluwa—kìí ṣe gẹ́gẹ́ bíi titun, kìí ṣe gẹ́gẹ́ bíi tiwa, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bíi ti Oluwa. . . . Iṣẹ́ náà nínú èyí tí ó dùn mọ́ Oluwa nínú láti lo ẹ̀bùn rírẹlẹ̀ wa kò fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ ti bíbẹ̀rẹ̀ ohun titun bíkòṣe ti ìtúnkọ́, ìtúnṣebọ̀sípò, ìmúbáraṣọ̀kan.” Lóòótọ́, òun sọ èrò-ìmọ̀lára aposteli Paulu jáde, gẹ́gẹ́ bí a ti rí i nínú 1 Korinti 3:5-7.

16 Ìṣarasíhùwà rẹ̀ jẹ́ òdìkejì pátápátá gbáà sí ti Charles Darwin. Nínú ẹ̀dà ìtẹ̀jáde ìwé The Origin of Species rẹ̀ àkọ́kọ́ ní 1859, léraléra ni Darwin tọ́kasí àbá-èrò-orí “mi”, ní ṣíṣàì ka ohun tí àwọn mìíràn tí wọ́n ti wà ṣáájú rẹ̀ ti sọ nípa ẹfolúṣọ̀n sí. Òǹkọ̀wé kan tí a mọ̀-bí-ẹni-mowó ní ọ̀rúndún yẹn, Samuel Butler, na Darwin lẹ́gba ọ̀rọ̀, ní ṣíṣàlàyé pé ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn mìíràn ti ṣe ìgbékalẹ̀ àbá ẹfolúṣọ̀n tẹ́lẹ̀; kò ní ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Darwin lọ́nàkọnà.

17. Kí ni àwọn àpẹẹrẹ síwájú síi nípa ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn Arákùnrin Rutherford?

17 Ìránṣẹ́ olùṣòtítọ́ mìíràn tí Jehofa Ọlọrun lo lọ́nà ribiribi ní àkókò òde-òní ni Joseph F. Rutherford, tí a mẹ́nukàn ní ìbẹ̀rẹ̀. Òun jẹ́ olùfìgboyà gbẹnusọ fún òtítọ́ Bibeli àti ní pàtàkì fún orúkọ Jehofa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a mọ̀ ọ́n sí Judge Rutherford níbi púpọ̀, òun jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn ní ọkàn-àyà. Fún àpẹẹrẹ, ó fìgbà kan rí sọ àwọn gbólóhùn nípa èrò tí kò fẹsẹ̀múlẹ̀ níti ohun tí àwọn Kristian lè fojúsọ́nà fún ní 1925. Nígbà tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kùnà láti ti àwọn ìfojúsọ́nà rẹ̀ lẹ́yìn, ó fi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn sọ fún ìdílé Beteli ní Brooklyn pé òun ti hùwà-ẹ̀gọ̀. Kristian ẹni-àmì-òróró kan tí ó ní àjọṣepọ̀ tímọ́tímọ́ gan-an pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́rìí síi pé lọ́pọ̀ ìgbà ni òun ti gbọ́ tí Arákùnrin Rutherford ń tọrọ àforíjì ní ìbámu pẹ̀lú èrò tí ó wà nínú Matteu 5:23, 24, ní gbangba àti ní ìkọ̀kọ̀, fún bíbà tí òun ti ba ọkàn Kristian ẹlẹgbẹ́ òun kan jẹ́ nípa àwọn gbólóhùn-ọ̀rọ̀ aláìlọ́gbọ́n kan. Ó gba ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn fún ẹnìkan tí ó wà ní ipò àṣẹ láti tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn wọnnì tí wọ́n wà lábẹ́ rẹ̀. Arákùnrin Rutherford fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún gbogbo àwọn alábòójútó, yálà nínú ìjọ, lẹ́nu iṣẹ́ ìrìnrìn-àjò, tàbí ní ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka Society.

18. Gbólóhùn-ọ̀rọ̀ tí ń fi ipò ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn hàn wo ni ààrẹ Society kẹta sọ?

18 Ààrẹ kẹta ti Watch Tower Bible and Tract Society, Nathan H. Knorr, pẹ̀lú fihàn pé, bí òun ti yọrí-ọlá tó láàárín àwọn ènìyàn Jehofa, òun kò nígbèéraga nítorí ipò òun. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní òye títayọ nípa ìṣètò àti nínú sísọ ọ̀rọ̀-àsọyé ìtagbangba, ó ní ọ̀wọ̀ ńlá fún ohun tí àwọn mìíràn bá ṣe. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣèbẹ̀wò lẹ́ẹ̀kan rí sọ́dọ̀ mẹ́ḿbà Ẹ̀ka-Iṣẹ́ Ìwé-Kíkọ kan ní ọ́fíìsì rẹ̀ ó sì sọ pé: “Níhìn-ín ní iṣẹ́ ṣíṣepàtàkì jùlọ àti èyí tí ó ṣòro jùlọ ti ń wáyé. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí mo fi ń ṣe ìwọ̀n tí ó kéré gan-an níbẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ni, ó ń fi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn fi ìmọ̀ràn tí ó wà ní Fillipi 2:3 sílò, pé ‘pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò-inú ẹnìkan níláti kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá ju òun lọ.’ Ó mọ̀ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Society ṣe pàtàkì, àwọn iṣẹ́ mìíràn pẹ̀lú ṣe pàtàkì. Ó gba ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn ní apá ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti nímọ̀lára lọ́nà yẹn àti láti sọ ọ́ lọ́nà ṣíṣe kedere bẹ́ẹ̀. Àpẹẹrẹ rere mìíràn ni òun jẹ́ fún gbogbo ènìyàn láti ṣàfarawé, pàápàá jùlọ àwọn wọnnì tí wọ́n lè ní ipò àbójútó tí ó yọrí-ọlá.

19, 20. (a) Àpẹẹrẹ ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn wo ni ààrẹ Society kẹrin fi lélẹ̀? (b) Ìrànlọ́wọ́ wo ni ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lée yóò fifúnni níti bi a ṣe lè lo ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn?

19 Ààrẹ Society kẹrin, Fred W. Franz, pẹ̀lú tún jẹ́ àpẹẹrẹ ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn rere. Gẹ́gẹ́ bí igbákejì ààrẹ Society fún nǹkan bíi ọdún 32, ó kọ èyí tí ó pọ̀ jùlọ nínú ìwé kíkọ fún àwọn ìwé-ìròyìn àti àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀; síbẹ̀ níti èyí ó sábà máa ń fi ara rẹ̀ sí ipò ẹ̀yìn, láìjẹ́ wá ọ̀nà láti fa àfiyèsí àwọn ẹlòmíràn mọ́ra. Àpẹẹrẹ ìgbàanì kan tí a lè fi wé èyí ní a lè tọ́kasí. Nígbà tí Joabu ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ammoni ní Rabba, ó rí i dájú pé Ọba Dafidi gba iyìn-ọlá fún ìṣẹ́gun náà.—2 Samueli 12:26-28.

20 Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ àwọn àpẹẹrẹ rere ni ó wà, látijọ́ àti nísinsìnyí, tí ń fún wa ní ìdí lílágbára láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn. Bí ó ti wù kí ó rí, ìdí púpọ̀ síi wà fún wa láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn, ìwọ̀nyí pẹ̀lú àwọn ohun tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn ni a óò gbéyẹ̀wò nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lée.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a  “Rẹrawálẹ̀” ní a sábà máa ń lò pẹ̀lú ìtumọ̀ náà “láti fira sípò ìlọ́lájù.” Ṣùgbọ́n ìtumọ̀ rẹ̀ gan-an—àti ìtumọ̀ rẹ̀ nínú New World Translation—ni “mú dẹjú,” “yẹ àwọn àǹfààní ipò jù sílẹ̀.”—Wo Webster’s Ninth New Collegiate Dictionary.

b Eksodu 34:6; Numeri 14:18; Nehemiah 9:17; Orin Dafidi 86:15; 103:8; 145:8; Joeli 2:13; Jona 4:2; Nahumu 1:3.

Ìwọ Ha Rántí Bí?

◻ Kí ni ó ti jẹ́ àwọn èso ìgbéraga?

◻ Ta ni ó ti fi àpẹẹrẹ ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn rere jùlọ lélẹ̀?

◻ Kí ni ó fi ẹni tí ó jẹ́ àpẹẹrẹ ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn gíga jùlọ kejì hàn?

◻ Àpẹẹrẹ ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn rere wo ni aposteli Paulu fi lélẹ̀?

◻ Àwọn àpẹẹrẹ ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn títayọlọ́lá wo ni a ní lóde-òni?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Jesu ṣe àṣefihàn rere nípa ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Paulu fi àpẹẹrẹ ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn rere lélẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Arákùnrin Russell kò buyìn-ọlá fún araarẹ̀ fún àwọn nǹkan tí ó kọ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́