Eeṣe Ti A Fi Nilati Gbé Irẹlẹ Wọ̀?
ONKỌWE ara America naa Edgar Allan Poe ṣẹṣẹ pari kika ìtàn rẹ titun fun awọn ọrẹ diẹ ni. Wọn wi lọna awada pe o ti lo orukọ akọni naa leralera ju. Bawo ni Poe ṣe huwa pada? Ọrẹ kan ranti pe: “Ẹmi igberaga rẹ ki yoo fayegba iru ibawi ita gbangba bẹẹ, nitori naa ninu ibinu fùfù, ṣaaju ki awọn ọrẹ rẹ to da a lọwọ kọ́, o ti fọn gbogbo abala iwe naa sinu ina ti njo.” Bẹẹ ni itan kan ti npanilẹrin in gidigidi, ti o yatọ patapata si . . . ìdágùdẹ̀ oju rẹ igba gbogbo sọnu.” Ẹmi irẹlẹ iba ti gbà á là.
Bi o tilẹ jẹ pe igberaga maa nmu ki awọn eniyan ṣe awọn ohun ti ko bọgbọnmu, o wọpọ ninu aye. Ṣugbọn o ye ki awọn iranṣẹ Jehofa yatọ. Wọn gbọdọ wọ ẹwu irẹlẹ oniṣẹ ọnà daradara.
Ki Ni Irẹlẹ?
Apọsiteli Pọọlu sọ nipa ẹwu Kristẹni meremere ti irẹlẹ nigba ti o kọwe si awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ ni ilu Kolose igbaani. O rọ̀ wọn pe: “Gẹgẹ bi ayanfẹ Ọlọrun, mimọ ati ololufẹẹ, ẹ fi awọn ifẹni onikẹẹ ti iyọnu, inurere, irẹlẹ ero inu, iwa pẹlẹ, ati ipamọra wọ ara yin ni aṣọ.”—Kolose 3:12, NW.
Bẹẹni, irẹlẹ jẹ “irẹlẹ ero inu.” O jẹ “rirẹ ero inu silẹ; aini igberaga; inututu.” Onirẹlẹ eniyan kan jẹ “ẹlẹmii irẹlẹ; kii ṣe agberaga.” Oun jẹ “abọwọfunni lọna jijinlẹ tabi lọna àyẹ́sí.” (The World Book Dictionary, Idipọ Kín-ínní, oju-iwe 1030) Irẹlẹ kii ṣe iwa ojo tabi ailera. Niti tootọ, igberaga fi ailera han, nigba ti fifi irẹlẹ han saba maa nbeere fun igboya ati okun.
Ninu Iwe mimọ lede Heberu ọrọ ti a tumọ si “rẹ ara rẹ silẹ” tumọ ni ṣakala si “tẹ ara rẹ mọlẹ.” Nipa bayii ọlọgbọn onkọwe Owe gbani nimọran pe: “Ọmọ mi . . . bi a ba fi ọrọ ẹnu rẹ mu ọ, . . . gba ara rẹ silẹ nigba ti iwọ ba bọ si ọwọ ọrẹ rẹ; lọ, rẹ ara rẹ silẹ [tẹ ara rẹ mọlẹ], ki iwọ ki o si tu ọrẹ rẹ.” (Owe 6:1-3) Iyẹn ni pe, pa igberaga tì sẹgbẹẹkan, gba aṣiṣe rẹ, mu awọn ọran tọ́.
O Gbọdọ Jẹ Ojulowo
Kii ṣe gbogbo awọn eniyan ti o dabi pé wọn nirẹlẹ ni wọn ni ojulowo irẹlẹ. Awọn kan o dabi pe wọn ni irẹlẹ le jẹ agberaga niti gidi ti wọn ki yoo si jẹ ki ohunkohun da wọn duro lati ṣe ohun ti wọn nfẹ. Lẹhin naa ni awọn wọnni ti wọn nlo ìbòjú irẹlẹ èké lati wú awọn ẹlomiran lori. Fun apẹẹrẹ, apọsiteli Pọọlu ṣalabaapade awọn kan ti wọn fi “irẹlẹ ẹlẹya” han, o si fihan pe ẹnikẹni ti nṣe eyi “nwu fùkẹ̀ pẹlu igberaga nipasẹ ọna igbekalẹ ero inu ti ẹran ara” niti gidi. Iru ẹni bẹẹ ronu lọna odi pe nini oju rere Ọlọrun sinmi lori yala oun jẹ, mu, tabi fọwọ kan awọn ohun kan tabi ṣakiyesi awọn ọjọ isin kan tabi bẹẹ kọ. Loootọ, oun le ti dabi ẹlẹmii isin ati onirẹlẹ, ṣugbọn irẹlẹ eke rẹ ko jamọ nǹkankan. (Kolose 2:18, 23, NW) Niti tootọ, o mu ki o ronu pe ẹbun ere ije iye ni a pin fun awọn wọnni ti wọn kọ awọn ohun ìní ti ara silẹ. O tun nmu iru ifẹ ọrọ̀ alumọni alarekereke kan gberu nitori awọn ohun ti a kaleewọ ti a si fi du ara ẹni ńkó afiyesi jọ sori awọn ohun ìní ti ara ti oun fẹnu lasan sọ pe oun ti pati.
Ni ọwọ keji ẹwẹ, ojulowo irẹlẹ maa ńká ẹnikan lọwọ kò kuro ninu fifi ijẹpataki ara-ẹni han ninu aṣọ wiwọ, itunraṣe, ati ọna aṣa igbesi-aye. (1 Johanu 2:15-17) Ẹnikan ti o wọ̀ ẹwu irẹlẹ kii fa afiyesi alaiyẹ si ara rẹ tabi awọn agbara rẹ. Kaka bẹẹ, irẹlẹ ran an lọwọ lati huwa si awọn ẹlomiran ni ọna igbatẹniro ati lati ri ara rẹ gẹgẹ bi Ọlọrun ti rí i. Bawo si ni iyẹn?
Oju Iwoye Jehofa
Nigba ti wolii Samuẹli fẹ́ lati fororo yan ọba titun fun orilẹ-ede Isirẹli, oun ronu pe Eliabu ọmọkunrin Jese ni Jehofa yan. Ṣugbọn Ọlọrun sọ fun Samuẹli pe: “Maṣe wo oju rẹ, tabi giga rẹ; nitori pe emi kọ̀ ọ́: nitori ti Oluwa kii wò bi eniyan ti nwo; eniyan a maa wo oju, Ṣugbọn Oluwa a maa wo ọkan.” Awọn ọmọkunrin Jese meje ni a kọ̀. Dafidi ni Ọlọrun yan, ẹni ti o jasi ọkunrin oluṣotitọ ati onirẹlẹ.—1 Samuẹli 13:14; 16:4-13.
Ẹwu irẹlẹ daabobo wa kuro lọwọ didi onigberaga, akùgbùù—ati ẹni ti Ọlọrun ko fọwọsi. O “kọ oju ija si awọn agberaga, ṣugbọn o fi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ ọkan.” (Jakọbu 4:6) Oju-iwoye rẹ ni a fihan ninu awọn ọrọ onisaamu naa pe: “Bi Oluwa [“Jehofa,” NW] tilẹ ga, sibẹ o juba awọn onirẹlẹ; ṣugbọn agberaga ni o mọ ni okeere réré.” (Saamu 138:6; 1 Peteru 5:5, 6) Ohun ti Ọlọrun reti lọdọ awọn iranṣẹ rẹ han gbangba lati inu ibeere yii, ti a beere ni Mika 6:8 (NW): “Ki ni Jehofa nbeere pada lọdọ rẹ bikoṣe lati mu idajọ ododo lo ati lati nifẹẹ inurere ati lati jẹ amẹtọmọwa ninu biba Ọlọrun rẹ rin?”
A Fihan Nipasẹ Ọlọrun ati Kristi
Abajọ ti Jehofa fi reti pe ki a fi irẹlẹ han! O jẹ ọkan lara awọn animọ tirẹ funraarẹ. Lẹhin ti Ọlọrun dá a nide kuro lọwọ awọn ọ̀tá, Dafidi kọrin pe: “Iwọ [Jehofa] yoo fun mi ni asà igbala rẹ, . . . irẹlẹ tirẹ funraarẹ yoo si mu mi di ẹni nla.” (Saamu 18:35, NW; 2 Samuẹli 22:1, 36) Bi o tilẹ jẹ pe Jehofa wa ninu awọn ọrun giga julọ, “ó rẹ araarẹ silẹ lati wo ohun ti o wà ni ọrun ati ni aye. O gbe takala soke lati inu erupẹ wa, o si gbe olupọnju soke lati ori ààtàn wa ki o le mu un jokoo pẹlu awọn ọmọ alade.” (Saamu 113:5-8) Ọlọrun fi irẹlẹ han nipa fifi aanu han si araye ẹlẹṣẹ. Ibalo rẹ pẹlu awọn ẹlẹṣẹ ati fifi Ọmọkunrin rẹ funni gẹgẹ bi ẹbọ fun ẹṣẹ jẹ ifihan irẹlẹ, ifẹ, ati awọn animọ miiran.—Roomu 5:8; 8:20, 21.
Jesu Kristi, ẹni ti o jẹ “oninututu ati onirẹlẹ ọkan,” fi apẹẹrẹ irẹlẹ titobi julọ lelẹ niha ọdọ eniyan. (Matiu 11:29) O sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ pe: “Ẹnikẹni ti o ba si gbe ara rẹ ga, ni a o rẹ silẹ; ẹnikẹni ti o ba rẹ ara rẹ silẹ ni a o gbe ga.” (Matiu 23:12) Iyẹn kii wulẹ ṣe ọrọ didun lasan. Ni alẹ ṣaaju ki o to ku, Jesu wẹ ẹsẹ awọn apọsiteli rẹ̀, ni ṣiṣe iṣẹ ti awọn ẹru maa nṣe lọna aṣa. (Johanu 13:2-5, 12-17) Jesu fi irẹlẹ sin Ọlọrun ṣaaju ki o to wa si ori ilẹ-aye o si ti fi irẹlẹ han lati akoko ajinde rẹ si ipo ti a gbega ninu ọrun. Nitori naa Pọọlu ṣi awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ leti lati ‘ka awọn ẹlomiran sí gẹgẹ bi ẹni ti o lọla ju wọn lọ,’ ki wọn si ni ẹmi onirẹlẹ ti Jesu Kristi.—Filipi 2:3, 5-11.
Niwọn bi Ọlọrun ati Kristi ti fi irẹlẹ han, awọn wọnni ti wọn fẹ ifọwọsi atọrunwa gbọdọ maa fi animọ yii han. Bi awa ba gberaga nigbamiran, yoo lọgbọn ninu lati rẹ ara wa silẹ ki a si gbadura fun idariji Ọlọrun. (Fiwe 2 Kironika 32:24-26.) Ati dipo nini ero gigalọla nipa araawa, a nilati fi imọran Pọọlu silo: “Ẹ maṣe ronu ohun giga, ṣugbọn ẹ maa tẹle awọn onirẹlẹ.” (Roomu 12:16) Bi o ti wu ki o ri, bawo ni irẹlẹ ṣe le ṣanfaani fun wa ati awọn ẹlomiran?
Awọn Anfaani Irẹlẹ
Anfaani irẹlẹ kan ni pe o ká wa lọwọ ko kuro ninu fífọ́nnu nipa ara wa. A tipa bayii dá awọn ẹlomiran sí lọwọ ibinu a o si yẹra fun kiko ojuti ba ara wa bi awọn aṣeyọri wa ko ba fà wọn mọra. A nilati yangàn ninu Jehofa, kii ṣe ninu araawa.—1 Kọrinti 1:31.
Irẹlẹ nran wa lọwọ lati gba idari atọrunwa. Jehofa ran angẹli kan si Daniẹli pẹlu iran kan nitori pe wolii yẹn rẹ araarẹ silẹ niwaju Ọlọrun nigba ti o nwa itọsọna ati oye kiri. (Daniẹli 10:12) Nigba ti o fẹrẹẹ tó akoko fun Ẹsira lati ṣamọna awọn eniyan Jehofa jade kuro ni Babiloni pẹlu ọpọlọpọ wura ati fadaka fun mimu tẹmpili ni Jerusalẹmu lẹwa, oun kede aawẹ ki wọn baa le rẹ araawọn silẹ niwaju Ọlọrun. Ki ni iyọrisi rẹ? Jehofa daabobo wọn kuro lọwọ ikọluni ọta lakooko irin ajo elewu naa. (Ẹsira 8:1-14, 21-32) Bii Daniẹli ati Ẹsira, ẹ jẹ ki a fi irẹlẹ han ki a si wa itọsọna Jehofa dipo gbigbiyanju lati mu awọn iṣẹ ti Ọlọrun yan fun wa ṣẹ nipa ọgbọn ati agbara tiwa funraawa.
Bi a ba gbe ẹwu irẹlẹ wọ̀, awa yoo bọwọ fun awọn ẹlomiran. Fun apẹẹrẹ, awọn ọmọ ti wọn ni irẹlẹ maa nbọwọ fun wọn si maa nṣegbọran si awọn obi wọn. Awọn Kristẹni onirẹlẹ tun nbọwọ fun awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn ti wọn jẹ ti orilẹ-ede, ẹya, ati ipilẹ igbesi-aye miiran, nitori irẹlẹ mu wa jẹ alaiṣojuṣaaju.—Iṣe 10:34, 35; 17:26.
Irẹlẹ maa ngbe ifẹ ati alaafia ga. Onirẹlẹ kan kii ba awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ jà ninu isapa lati fidi awọn ẹtọ ti o lero pe oun ni mulẹ. Pọọlu ṣe kiki awọn ohun ti ngbeniro ki yoo si daamu ẹri-ọkan arakunrin kankan. (Roomu 14:19-21; 1 Kọrinti 8:9-13; 10:23-33) Irẹlẹ tun nran wa lọwọ lati gbe ifẹ ati alaafia ga nipa didari ji awọn ẹlomiran fun awọn ẹṣẹ wọn lodisi wa. (Matiu 6:12-15; 18:21, 22) O nsun wa lati lọ sọdọ ẹni a ṣẹ̀, ki a gba aṣiṣe wa, beere fun idariji rẹ, ki a si ṣe ohun ti a le ṣe lati ṣatunṣe aṣiṣe eyikeyii ti a ti le ṣe. (Matiu 5:23, 24; Luuku 19:8) Bi ẹni kan ti a ṣẹ̀ ba wa sọdọ wa, irẹlẹ nsun wa lati yanju awọn ọran pẹlu alaafia ninu ẹmi ifẹ.—Matiu 18:15; Luuku 17:3.
Igbala sinmi lori fifi ẹmi irẹlẹ han. Fun apẹẹrẹ, nipa Ọlọrun, a sọ pe: “Awọn eniyan onirẹlẹ ni iwọ yoo gbala; ṣugbọn oju rẹ lodisi awọn agberaga, ki iwọ le rẹ̀ wọn walẹ.” (2 Samuẹli 22:28, NW) Nigba ti Ọba Jesu Kristi ba ‘gẹṣin ninu ipa otitọ, irẹlẹ, ati ododo,’ oun yoo gba awọn wọnni ti wọn rẹ araawọn silẹ niwaju rẹ ati Baba rẹ là. (Saamu 45:4) Awọn wọnni ti wọn fi irẹlẹ han le ri itunu ninu awọn ọrọ naa pe: “Ẹ wa Oluwa [“Jehofa,” NW], gbogbo ẹyin ọlọkan tutu aye, ti nṣe idajọ rẹ; ẹ wa ododo, ẹ wa iwa pẹlẹ: boya a o pa yin mọ ni ọjọ ibinu Oluwa [“Jehofa,” NW].”—Sefanaya 2:3.
Irẹlẹ ati Eto-ajọ Ọlọrun
Irẹlẹ maa nṣamọna awọn eniyan Ọlọrun lati mọriri eto-ajọ rẹ ki wọn si duro tì í gẹgẹ bi awọn olupa iwa titọ mọ́. (Fiwe Johanu 6:66-69.) Bi a ko ba ri anfaani iṣẹ-isin ti a nreti gbà, irẹlẹ yoo ran wa lọwọ lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn wọnni ti wọn ni ẹru-iṣẹ ninu ijọ. Ifọwọsowọpọ onirẹlẹ wa si fi apẹẹrẹ rere lelẹ.
Ni ọwọ keji ẹwẹ, ẹmi irẹlẹ pa wa mọ kuro ninu fifi ọkan giga han jade ni isopọ pẹlu awọn anfaani iṣẹ-isin wa laaarin awọn eniyan Jehofa. O ká wa lọwọ kò kuro ninu wiwa iyin fun iṣẹ ti a ni anfaani lati ṣe ninu eto-ajọ Ọlọrun. Ju bẹẹ lọ, bi a ba ni anfaani lati ṣiṣẹsin gẹgẹ bi alagba, irẹlẹ ran wa lọwọ lati huwa si agbo Ọlọrun lọna jẹlẹnkẹ.—Iṣe 20:28, 29; 1 Peteru 3:8.
Irẹlẹ ati Ibawi
Ẹwu irẹlẹ nran wa lọwọ lati tẹwọgba ibawi. Awọn eniyan onirẹlẹ ko dabii Usaya Ọba Juda, ẹni ti ọkan-aya rẹ gberaga gan an tobẹẹ debi pe o fipa gba iṣẹ alufaa ṣe. O ‘huwa lọna aiṣododo lodi si Jehofa o si wá sinu tẹmpili lati fi turari jona lori pẹpẹ turari.’ Nigba ti Usaya binu si awọn alufaa fun titọ ọ sọna, a fi ẹtẹ kọlu u. Ẹ wo iye ti o san fun aini irẹlẹ! (2 Kironika 26:16-21; Owe 16:18) Maṣe dabi Usaya lae ki o si jẹki igberaga ṣèdènà rẹ lati gba ibawi lati ọdọ Ọlọrun nipasẹ Ọrọ ati eto-ajọ Rẹ.
Nipa eyi Pọọlu sọ fun awọn Kristẹni Heberu ẹni ami ororo pe: “Ẹyin si ti gbagbe ọrọ iyanju ti nba yin sọ bi ọmọ pe, ọmọ mi, maṣe alaini ibawi Oluwa [“Jehofa,” NW], ki o ma si ṣe rẹwẹsi nigba ti a ba nti ọwọ rẹ̀ ba ọ wi: nitori pe ẹni ti Oluwa fẹ, oun ni iba wi, a si maa na olukuluku ọmọ ti o gba . . . Gbogbo ibawi ko dabi ohun ayọ nisinsinyi, bikoṣe ibanujẹ; ṣugbọn nikẹhin a so eso alaafia fun awọn ti a ti tọ́ nipa rẹ, ani eso ododo.” (Heberu 12:5-11) Ranti pẹlu, pe “ibawi ẹkọ ni ọna iye.”—Owe 6:23.
Ẹ Wà Ni Ẹni Ti O Gbe Irẹlẹ Wọ̀
Bawo ni o ti ṣe pataki tó pe ki awọn Kristẹni maa wọ ẹwu irẹlẹ nigba gbogbo! O sun wa lati foriti gẹgẹ bi awọn olupokiki Ijọba, ni jijẹrii pẹlu irẹlẹ lati ile de ile ni wiwa awọn wọnni “ti wọn ni itẹsi ọkan lọna titọ fun iye ainipẹkun kiri.” (Iṣe 13:48, NW; 20:20) Nitootọ, irẹlẹ nran wa lọwọ lati maa baa lọ ni ṣiṣegbọran si Ọlọrun ni gbogbo ọna, bi o tilẹ jẹ pe awọn aṣodi onigberaga koriira ipa ọna ododo wa.—Saamu 34:21.
Nitori pe irẹlẹ sun wa lati ‘nigbẹẹkẹle ninu Jehofa pẹlu gbogbo ọkan-aya wa,’ oun mu ki ipa ọna wa tọ́. (Owe 3:5, 6) Niti tootọ, ayafi bi a ba gbé animọ rere yii wọ̀ ni a to le rin pẹlu Ọlọrun ki a si gbadun ifọwọsi ati ibukun rẹ nitootọ. Gẹgẹ bi ọmọ-ẹhin naa Jakọbu ti kọwe: “Ẹ rẹ ara yin silẹ niwaju Oluwa [“Jehofa,” NW], oun o si gbe yin ga.” (Jakọbu 4:10) Nitori naa ẹ jẹ ki a gbe irẹlẹ wọ̀, ẹwu meremere yẹn ti Jehofa Ọlọrun ṣẹda rẹ.