ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lmd ẹ̀kọ́ 8
  • Máa Ní Sùúrù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Ní Sùúrù
  • Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Jésù Ṣe
  • Kí La Rí Kọ́ Lára Jésù?
  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù
  • Ẹ Máa Ní Sùúrù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bí O Ṣe Lè Fi Fídíò Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
  • Àǹfààní Tí Ikú Jésù Ṣe Wá
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Sọ Ohun Táwọn Èèyàn Nífẹ̀ẹ́ Sí
    Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
Àwọn Míì
Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
lmd ẹ̀kọ́ 8

PA DÀ LỌ

Jésù lọ bá Jémíìsì àbúrò ẹ̀ níbi tó ti ń ṣiṣẹ́ káfíńtà. Ó ya Jémíìsì lẹ́nu láti rí i.

Jòh. 7:3-5; 1 Kọ́r. 15:3, 4, 7

Ẹ̀KỌ́ 8

Máa Ní Sùúrù

Ìlànà: “Ìfẹ́ máa ń ní sùúrù.”—1 Kọ́r. 13:4.

Ohun Tí Jésù Ṣe

Jésù lọ bá Jémíìsì àbúrò ẹ̀ níbi tó ti ń ṣiṣẹ́ káfíńtà. Ó ya Jémíìsì lẹ́nu láti rí i.

FÍDÍÒ: Jésù Fi Sùúrù Ran Àbúrò Ẹ̀ Lọ́wọ́

1. Wo FÍDÍÒ yìí, tàbí kó o ka Jòhánù 7:3-5 àti 1 Kọ́ríńtì 15:3, 4, 7. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  1. Báwo ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù ṣe kọ́kọ́ rí lára àwọn arákùnrin ẹ̀?

  2. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù ò jẹ́ kó sú òun láti máa ran Jémíìsì àbúrò ẹ̀ lọ́wọ́?

Kí La Rí Kọ́ Lára Jésù?

2. Ó yẹ ká máa ní sùúrù bá a ṣe ń wàásù fáwọn èèyàn, torí pé àwọn kan lè má tètè fara mọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì tá à ń kọ́ wọn.

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù

3. Máa lo oríṣiríṣi ọ̀nà. Tẹ́nì kan ò bá tètè gbà pé kó o máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, má ṣe fipá mú un. Láwọn ìgbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, o lè lo fídíò àtàwọn àpilẹ̀kọ kan láti jẹ́ kó mọ bá a ṣe máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn àǹfààní tó máa rí.

4. Má fẹnì kan wé ẹlòmíì. Máa fi sọ́kàn pé ẹnì kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra. Tó bá dà bíi pé ẹnì kan nínú ìdílé ẹ tàbí ẹnì kan tó o wàásù fún ò fẹ́ kó o máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí tí kò fara mọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì kan, ńṣe ni kó o ronú nípa ohun tó ṣeé ṣe kó fà á. Ṣé ohun kan wà tí wọ́n máa ń ṣe nínú ẹ̀sìn ẹ̀ tó fẹ́ràn gan-an? Ṣé àwọn ẹbí ẹ̀ tàbí àwọn ará àdúgbò ẹ̀ ń halẹ̀ mọ́ ọn? Tó o bá ní sùúrù, ẹni náà lè wá ronú jinlẹ̀ lórí àwọn nǹkan tó o sọ fún un, kó sì wá rí i pé òun máa jàǹfààní tóun bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

5. Máa gbàdúrà. Bẹ Jèhófà pé kó má jẹ́ kọ́rọ̀ náà sú ẹ, kó sì fún ẹ lọ́gbọ́n tí wàá fi mọ ohun tó yẹ kó o ṣe. Tẹ́nì kan ò bá ṣe ohun tó fi hàn pé òun fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kó o mọ ìgbà tí kò yẹ kó o lọ sọ́dọ̀ ẹ̀ mọ́.—1 Kọ́r. 9:26.

TÚN WO

Máàkù 4:26-28; 1 Kọ́r. 3:5-9; 2 Pét. 3:9

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́