ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lmd ẹ̀kọ́ 10
  • Fọwọ́ Pàtàkì Mú Ìkẹ́kọ̀ọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fọwọ́ Pàtàkì Mú Ìkẹ́kọ̀ọ́
  • Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Jésù Ṣe
  • Kí La Rí Kọ́ Lára Jésù?
  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù
  • Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Nikodémù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Jésù Kọ́ Nikodémù Lẹ́kọ̀ọ́ ní Òru
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Ran Ẹni Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Lọ́wọ́ Kó Lè Sin Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Kíkọ́ Nikodemu Lẹkọọ
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
Àwọn Míì
Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
lmd ẹ̀kọ́ 10

SỌ WỌ́N DỌMỌ Ẹ̀YÌN

Jésù àti Nikodémù jọ ń sọ̀rọ̀ lálẹ́ nínú àgbàlá.

Jòh. 3:1, 2

Ẹ̀KỌ́ 10

Fọwọ́ Pàtàkì Mú Ìkẹ́kọ̀ọ́

Ìlànà: “A ti pinnu pé kì í ṣe ìhìn rere Ọlọ́run nìkan la máa fún yín, a tún máa fún yín ní ara wa, torí ẹ ti di ẹni ọ̀wọ́n sí wa.”—1 Tẹs. 2:8.

Ohun Tí Jésù Ṣe

Jésù àti Nikodémù jọ ń sọ̀rọ̀ lálẹ́ nínú àgbàlá.

FÍDÍÒ: Jésù Kọ́ Nikodémù

1. Wo FÍDÍÒ yìí, tàbí kó o ka Jòhánù 3:1, 2. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  1. Kí lo rò pé ó mú kí Nikodémù lọ bá Jésù lálẹ́?—Wo Jòhánù 12:42, 43.

  2. Jésù gbà láti bá Nikodémù sọ̀rọ̀ lálẹ́. Báwo nìyẹn ṣe fi hàn pé ọwọ́ pàtàkì ló fi mú iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn?

Kí La Rí Kọ́ Lára Jésù?

2. Tá a bá fẹ́ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ó yẹ ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe, ká lè sọ wọ́n dọmọ ẹ̀yìn.

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù

3. Múra tán láti kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ ẹ ní àkókò àti ibi tó rọrùn fún un. Ó lè jẹ́ pé ọjọ́ tàbí àkókò pàtó kan ló máa ń rọrùn fún un. Ronú nípa ibi tó ti máa ń rọ̀ ọ́ lọ́rùn jù láti kẹ́kọ̀ọ́. Ṣé ibiṣẹ́ ni, ilé àbí ibòmíì? Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti máa kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ní àkókò àti ibi tó rọrùn fún un.

4. Máa kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ déédéé. Tó ò bá ní ráyè kọ́ ẹni náà lẹ́kọ̀ọ́ lọ́sẹ̀ kan, má torí ìyẹn wọ́gi lé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, o lè ṣe ọ̀kan nínú àwọn ohun mẹ́ta yìí:

  1. a. Kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ní ọjọ́ míì láàárín ọ̀sẹ̀ yẹn.

  2. b. Kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ lórí fóònù tàbí kẹ́ ẹ fi fídíò pe ara yín.

  3. d. Ní kí ẹlòmíì bá ẹ kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́.

5. Bẹ Jèhófà pé kó má jẹ́ kó sú ẹ. Gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kó o máa fọwọ́ pàtàkì mú ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹni náà, tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé kì í fi bẹ́ẹ̀ ráyè tàbí kì í yá a lára láti fàwọn ìlànà Bíbélì sílò. (Fílí. 2:13) Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o ráwọn ìwà tó dáa tẹ́ni náà ní, ìyẹn ò ní jẹ́ kọ́rọ̀ ẹ̀ sú ẹ.

TÚN WO

Òwe 3:27; Ìṣe 20:35; 2 Kọ́r. 12:15

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́