ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lmd ẹ̀kọ́ 11
  • Kọ́ni Lọ́nà Tó Rọrùn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kọ́ni Lọ́nà Tó Rọrùn
  • Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Jésù Ṣe
  • Kí La Rí Kọ́ Lára Jésù?
  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù
  • Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Bá A Ṣe Lè Fi Ìwé “Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!” Kọ́ Àwọn Èèyàn Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
    Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
  • Fiyè Sí “Ọnà Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Máa Múra Sílẹ̀ Dáadáa Tó O Bá Fẹ́ Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
Àwọn Míì
Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
lmd ẹ̀kọ́ 11

SỌ WỌ́N DỌMỌ Ẹ̀YÌN

Jésù ń kọ́ àwùjọ èèyàn létí omi. Àwọn ẹyẹ ń fò lójú ọ̀run, àwọn òdòdó sì wà níbẹ̀.

Mát. 6:25-27

Ẹ̀KỌ́ 11

Kọ́ni Lọ́nà Tó Rọrùn

Ìlànà: “Sọ ọ̀rọ̀ tó rọrùn láti lóye.” —1 Kọ́r. 14:9.

Ohun Tí Jésù Ṣe

Jésù ń kọ́ àwùjọ èèyàn létí omi. Àwọn ẹyẹ ń fò lójú ọ̀run, àwọn òdòdó sì wà níbẹ̀.

FÍDÍÒ: Jésù Ṣàpèjúwe Bí Jèhófà Ṣe Nífẹ̀ẹ́ Wa Tó

1. Wo FÍDÍÒ yìí, tàbí kó o ka Mátíù 6:25-27. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  1. Àpèjúwe wo ni Jésù sọ tó jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó?

  2. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa àwọn ẹyẹ, àpèjúwe tó rọrùn wo ló sọ nípa wọn? Kí nìdí tí ìyẹn fi jẹ́ ọ̀nà tó dáa láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́?

Kí La Rí Kọ́ Lára Jésù?

2. Tá a bá kọ́ àwọn èèyàn lọ́nà tó rọrùn, wọ́n á rántí ohun tá a kọ́ wọn, á sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn.

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù

3. Má sọ̀rọ̀ jù. Dípò tí wàá fi sọ gbogbo ohun tó o mọ̀ nípa ohun tẹ́ ẹ̀ ń kọ́, ohun tó wà nínú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tẹ́ ẹ̀ ń lò ni kó o fi àlàyé ẹ mọ sí. Tó o bá béèrè ìbéèrè kan, ní sùúrù kí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ dáhùn. Tí kò bá mọ ìdáhùn tàbí tí ìdáhùn ẹ̀ ò bá ohun tó wà nínú Bíbélì mu, o lè bi í láwọn ìbéèrè míì tó máa jẹ́ kó ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà. Tí kókó pàtàkì inú ohun tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ bá ti yé e, ńṣe ni kẹ́ ẹ lọ sí kókó tó kàn.

4. So ohun tẹ́ ẹ ti kọ́ tẹ́lẹ̀ mọ́ èyí tẹ́ ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ kọ́. Bí àpẹẹrẹ, kẹ́ ẹ tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ nípa àjíǹde, o lè sọ̀rọ̀ ṣókí nípa ohun tẹ́ ẹ ti kọ́ tẹ́lẹ̀ pé àwọn òkú ò mọ nǹkan kan.

5. Ronú jinlẹ̀ kó o tó lo àpèjúwe. Kó o tó lo àpèjúwe, bi ara ẹ pé:

  1. a. ‘Ṣé àpèjúwe yìí ò lọ́jú pọ̀?’

  2. b. ‘Ṣó máa tètè yé ẹni tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́?’

  3. d. ‘Ṣó máa jẹ́ kí ẹni tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ rántí kókó pàtàkì inú ohun tá à ń kọ́ àbí àpèjúwe yẹn nìkan láá kàn máa rántí?’

TÚN WO

Mát. 11:25; Jòh. 16:12; 1 Kọ́r. 2:1

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́