Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Onkawe
◼ Njẹ ọ̀dọ́bìnrin Júù naa Esteri ní ìbálòpọ̀-takọtabo oníwà pálapàla pẹlu ọba Paṣia lati jèrè ojúrere rẹ̀ kí ó sì tipa bayii jèrè awọn àǹfààní?
Awọn kan ti lè de ìparí-èrò yii lati inú ìròhìn ayé, ṣugbọn akọsilẹ tí ó ṣeégbáralé ninu Bibeli takò igbagbọ alaiwadii yii.
Òpìtàn Júù naa Flavius Josephus pèsè ìròhìn kan ti kii ṣe ti isin pe ayaba Paṣia naa Faṣiti kọ̀ lati farahàn niwaju ọkọ rẹ̀, Ahasuerusi. Lórí eyiini, ọba naa ti o ṣekedere pe o jẹ Saksisi Kìn-ínní ti ọ̀rúndún karùn-ún ṣaaju Sanmanni Tiwa fi ibinu kọ Faṣiti ó sì fohùnṣọ̀kan pe ki a ṣe iwakiri kan yíká ilẹ̀-ọba naa lati rí ayaba titun. Awọn wundia arẹwà ti wọn jẹ ọ̀dọ́ ni a pèjọ tí a sì fun wọn ní ìtọ́jú ẹwà fun ọjọ gigun.
“Lẹhin naa, nigba ti [ìwẹ̀fà ọba] ronú pe awọn omidan naa ti ní ìtọ́jú pupọ tó . . . tí wọn sì yẹ nisinsinyi lati wá sórí ibùsùn ọba, oun nfi ẹnikan ranṣẹ lojoojumọ lati sùn pẹlu ọba, ẹni tí, lẹhin ti o ba ti ní ibalopọ pẹlu rẹ̀, yoo rán an padà sí ìwẹ̀fà naa lọ́gán. Ṣugbọn, nigba ti Esteri wọlé tọ̀ ọ́, oun nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹlu rẹ̀, ati lẹhin naa, ní kikowọnu ìfẹ́ pẹlu rẹ̀, o fi ṣe aya rẹ̀ tí ó bófinmu wọn sì ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó wọn.”—Jewish Antiquities, Book XI, 184-202, tí a túmọ̀ lati ọwọ́ Ralph Marcus, (Ìwé 11, orí-ìwé 6, awọn ìpínrọ̀ 1, 2, gẹgẹ bi William Whiston ti túmọ̀ rẹ̀).
Akọsilẹ ti kii ṣe ti isin yii lè ṣamọ̀nà ẹnikan sí ríronú pe awọn omidan naa ṣàjọpín ninu ìbálòpọ̀-takọtabo oníwà pálapàla pẹlu ọba naa ati pe kìkì ìyàtọ̀ kan ninu ọ̀ràn ti Esteri ni pe ìwà pálapàla rẹ̀ ṣamọ̀nà rẹ̀ sí ìgbéyàwó ati dídi ayaba rẹ̀. Bibeli, bí ó ti wù kí ó rí, pèsè ìsọfúnni ti o tubọ péye tí ó sì tẹ́nilọ́rùn fun wa.
Lẹhin ṣíṣàpèjúwe awọn ìtọ́jú ẹwà naa, Bibeli wipe: “Lẹhin naa lórí awọn ipò wọnyi ọ̀dọ́bìnrin [kọọkan] fúnraarẹ̀ wọlé tọ ọba. . . . Ní alẹ́ oun fúnraarẹ̀ yoo wọlé, ati ní òwúrọ̀ oun fúnraarẹ̀ yoo padà sí ilé keji ti awọn obinrin ní ìkáwọ́ Ṣaaṣigasi ìwẹ̀fà ọba, olùṣètọ́jú awọn àlè. Oun kì yoo wọlé tọ ọba mọ́ àyàfi bí ọba bá ní inúdídùn ninu rẹ̀ tí ọba sì ti pè é pẹlu orukọ.”—Esteri 2:13, 14, NW.
Awọn Iwe Mimọ wipe Esteri “ni a múlọ” sí “ilé awọn obinrin” fun iwewee itọju ẹwà tí a lànàsílẹ̀, fun ọjọ pípẹ́: “Lẹhin naa a mú Esteri lọ sọ́dọ̀ Ọba Ahasuerusi . . . Ọba naa sì wá nífẹ̀ẹ́ Esteri ju gbogbo awọn obinrin miiran, débi pe oun jèrè ojúrere-ìṣeun ati ìṣeun-ìfẹ́ síi niwaju rẹ̀ ju gbogbo awọn wundia miiran. Oun sì tẹsiwaju lati fi ọ̀ṣọ́-ìwérí ọlọ́ba sórí rẹ̀ ó sì ṣe é ní ayaba dípò Faṣiti.”—Esteri 2:8, 9, 16, 17.
Njẹ iwọ ha ṣàkíyèsí lati inú akọsilẹ Bibeli ibi tí a mú awọn obinrin naa lọ lẹhin tí wọn ti lò òru pẹlu ọba? ‘Sí inú ilé keji ti awọn obinrin, lábẹ́ olùṣètọ́jú awọn àlè.’ Nitorinaa wọn ti di awọn àlè. Modekai, onkọwe ìwé Bibeli ti Esteri, jẹ́ Heberu, ati láàárín awọn ènìyàn rẹ̀ nigba naa lọhun-un, àlè kan ní ìdúró bi ti aya atẹle laaarin ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà. Òfin atọrunwa sọ pe ọkunrin ara Israẹli kan lè mú ọ̀dọ́mọbìnrin àjèjì kan tí a múlẹ́rú nigba ogun, oun yoo sì di àlè rẹ̀, tabi aya atẹle, pẹlu awọn ẹ̀tọ́ ati idaabobo òfin. (Deuteronomi 21:10-17; fiwera pẹlu Ẹksodu 21:7-11.) Awọn ọmọ tí a bí fun irúfẹ́ àlè tí ó bófinmu bẹẹ jẹ́ ọmọ-ọkọ wọn sì lè jèrè ogún. Awọn ọmọkunrin 12 ti Jakobu, awọn babanla awọn ẹ̀yà 12 Israẹli, jẹ́ ọmọ awọn aya rẹ̀ ati awọn àlè tí wọn bófinmu.—Jẹnẹsisi 30:3-13.
Ìlànà-ìṣe naa ni pe lẹhin tí awọn wundia naa ti kuro lọdọ ọba Paṣia, wọn lọ sínú ilé awọn àlè. Eyi fihàn pe wọn di awọn aya atẹle.
Kinni nipa Esteri? Bibeli kò wipe ó sùn pẹlu ọba naa ó sì tipa bayii jèrè ojúrere rẹ̀. Kò sọ nipa mímú un lọ sínú ilé awọn àlè, ṣugbọn ó wí ní ṣákálá pe: “Lẹhin naa Esteri ni a mú lọ sọ́dọ̀ Ọba Ahasuerusi ní ilé ọlọ́ba . . . Ọba sì wá nífẹ̀ẹ́ Esteri ju gbogbo awọn obinrin miiran.” Rántí pe ní àkọ́kọ́, láìsí fifi ipò ìwà funfun ati wundia rẹ̀ banidọrẹẹ, oun laisi ìbálòpọ̀-takọtabo jèrè “ìṣeun-ìfẹ́” ti “Hegai olùṣètọ́jú awọn obinrin.” Siwaju síi: “Esteri si ri ojurere lọdọ gbogbo ẹni ti nwo o.” (Esteri 2:8, 9, 15-17) Nitori naa Esteri ní kedere wú ọba lórí ó sì jèrè ọ̀wọ̀ rẹ̀, àní bí oun ti jèrè ọ̀wọ̀ awọn ẹlomiran pàápàá.
Bawo ni awa ti lè kún fun ọpẹ́ tó lati ní awọn otitọ-iṣẹlẹ ati ijinlẹ-oye tí Bibeli pèsè fun wa! Bí ó tilẹ jẹ́ pe awa ti fi ẹgbẹẹgbẹrun ọdun jìnnà sí ìṣẹ̀lẹ̀ naa, awa tipa bayii ní ìdí fun ìgbọ́kànlé pe Esteri hùwà pẹlu ìwà funfun tootọ ati ní ìbámu pẹlu awọn ìlànà oníwà-bí-Ọlọ́run.