Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Onkawe
◼ Onkọwe Bibeli wo ni o jẹ “ọgagun,” gẹgẹ bi a ti mẹnukan an ninu iwe naa The Bible—God’s Word or Man’s?a
Iwe ti o kun fun iranlọwọ nipa Ọ̀rọ̀ Ọlọrun yẹn sọ ni oju-iwe 10 pe: “Bibeli tun jẹ alailẹgbẹ nitori ohun ti ọpọlọpọ awọn onkọwe rẹ̀ sọ. Nnkan bii ogoji eniyan, ti o ni ninu awọn ọba, oluṣọ-agutan, apẹja, oṣiṣẹ ijọba, alufaa, ati o keretan ọgagun kan, ati oniṣegun kan, lọ́wọ́ ninu kíkọ apa ọtọọtọ Bibeli. Ṣugbọn leralera, awọn onkọwe maa nsọ ohun kan naa pe: kii ṣe ironu tiwọn funraawọn bikoṣe ti Ọlọrun ni awọn nkọ.”
Awọn kan ti beere awọn onkọwe Bibeli ti a damọ pẹlu awọn oriṣiriṣi iṣẹ ati igbokegbodo wọnni. Ni ọna yii, jọwọ yẹ eyi ti o tẹle e wò:
Awọn ọba: Iye awọn onkọwe Bibeli melookan jẹ ọba. Dafidi ati Solomoni le fi pẹlu irọrun wá sí ọkàn. (Saamu 3, akọle; Owe 1:1; Oniwaasu 1:1) Bi o ti wu ki o ri, orin ti o wà ni Aisaya 38:10-20 ni a kọ lati ọwọ́ Hesekaya. (Ẹsẹ 9) Ọpọlọpọ awọn ọmọwe gbagbọ pe oun ni ó tun ṣakopọ Saamu 119, boya ṣaaju ki o to di ọba. Hesekaya sì kopa ninu ṣiṣakopọ Owe ori 25-29. (Owe 25:1) Akori ti o kẹhin Owe ni a kọ lati ọwọ “Lemuẹli ọba.” Awọn kan dá a mọ̀ gẹgẹ bi Ọba Hesekaya, bi o tilẹ jẹ pe awọn miiran ronu pe Lemuẹli jẹ́ Ọba Solomoni.—Owe 31:1.
Awọn oluṣọ-agutan: Dafidi ati wolii Amosi ṣiṣẹ gẹgẹ bi oluṣọ-agutan. (1 Samuẹli 16:11-13; 17:15, 28, 34; Amosi 1:1) Amosi kọ iwe Bibeli ti njẹ orukọ rẹ̀, Dafidi sì ṣakojọ ọgọọrọ awọn saamu. Dajudaju Saamu 23 ti o gbajumọ naa fi mimọ ti Dafidi mọ iṣẹ oluṣọ-agutan dunju han.
Awọn apẹja: Ninu awọn apọsteli Jesu ti wọn jẹ apẹja, Johanu ati Peteru ni a misi lẹhin naa lati kọ awọn iwe Bibeli. (Matiu 4:18-22) Labẹ imisi atọrunwa Johanu kọ akọsilẹ Irohinrere kan ati pẹlu lẹta mẹta ati iwe Iṣipaya. Peteru kọ awọn lẹta onimiisi meji.
Awọn oṣiṣẹ ijọba: Daniẹli ati Nehemaya jẹ awọn oṣiṣẹ ijọba ti ijọba àjòjì tí nlo aṣẹ lori awọn eniyan Ọlọrun. (Nehemaya 1:1, 11; 2:1, 2; Daniẹli 1:19; 2:49; 6:1-3) Awọn iwe Bibeli meji jẹ orukọ awọn ọkunrin wọnyi.
Awọn alufaa: Awọn wolii Ọlọrun meji ti a lò lati kọ awọn iwe Bibeli jẹ alufaa. Awọn ni Jeremaya ati Esekiẹli. (Jeremaya 1:1; Esekiẹli 1:1-3) Ni afikun, Ẹsira jẹ alufaa idile Aaroni ẹni ti “o . . . jẹ ayáwọ́ akọwe ninu ofin Mose.” Oun “muratan ni ọkan rẹ̀ lati maa wa ofin Oluwa [“Jehofa,” NW] ati lati ṣe e, ati lati maa kọni ni òfin ati itọni ni Israẹli.”—Ẹsira 7:1-6, 10, 11.
Ọgagun: Ipa ti Joṣua ko ninu ṣiṣiwaju ogun gẹgẹ bi awọn ọmọ Israẹli ti nṣi wọnu Ilẹ Ileri ti wọn sì jà lodisi awọn ọta eniyan mú un tootun gẹgẹ bi ọgagun kan. (Joṣua 1:1-3; 11:5, 6) Oun ni anfaani lati kọ iwe Joṣua. Lẹhin naa, pẹlu, awọn onkọwe Bibeli lè wo Dafidi gẹgẹ bi ọkunrin kan ti o ṣiṣẹ gẹgẹ bi ọgagun ṣaaju ki o to di ọba.—1 Samuẹli 19:8; 23:1-5.
Oniṣegun: Nikẹhin, Kolose 4:14 mẹnukan “Luuku oniṣegun olufẹ.” Luuku kọ Irohinrere ti o jẹ orukọ rẹ̀, ati lọna ti o han gbangba oun kọ Iṣe Awọn Apọsteli pẹlu.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tẹ ẹ jade ni 1989 lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.