“Ọjọ Oluwa”
“NIPA imisi mo wá wà ni ọjọ Oluwa.” (Iṣipaya 1:10) Bayii ni apọsteli Johanu arúgbó naa, ti a fihan ninu aworan oke yii wi, ni ori akọkọ ninu iwe Bibeli naa Iṣipaya. Awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ran wa lọwọ lati mọ akoko imuṣẹ awọn iran titobilọla ti oun tẹsiwaju lati ṣapejuwe.
Bi o ti wu ki o ri, kii ṣe gbogbo eniyan, ni o fohunṣọkan pẹlu itumọ Iṣipaya 1:10 yii. Fun apẹẹrẹ, atumọ Bibeli ara Germany naa Jörg Zink tumọ rẹ̀ pe: “Mo kun fun ẹmi mimọ—o jẹ ni ọjọ Sunday.” Bi o ti wu ki o ri, ọpọ julọ awọn ẹda itumọ Bibeli, tumọ àpólà ọ̀rọ̀ Giriiki naa teiʹ ky·ri·a·keiʹ he·meʹrai gẹgẹ bi “ọjọ Oluwa.” Ṣugbọn ninu ọ̀rọ̀ eti ìwé ọpọlopọ sọ pe o ntọkasi Sunday. Eyi ha tọna bi?
Herders Bibelkommentar naa lede Germany, iṣẹ itọka kan ti o jẹ ti awọn Katoliki, ṣalaye ero ti o wà lẹhin ironu yii nigba ti o wi pe: “Itọka ni a ṣe nihin-in [ni Iṣipaya 1:10] kii ṣe si Ọjọ Idajọ Ikẹhin, eyi ti a mọ̀ bakan naa gẹgẹ bi ‘Ọjọ Oluwa’, ṣugbọn si ọjọ pato kan laaarin ọsẹ. Awọn Kristian akọkọbẹrẹ bẹrẹ sii ṣayẹyẹ ọjọ kìn-ínní ọsẹ gẹgẹ bi ọjọ isin pataki wọn ninu ṣọọṣi tipẹtipẹ sẹhin to aarin ọrundun kìn-ínní. (Iṣe 20:7; 1 Kọr. 16:2)” Bi o ti wu ki o ri, ẹsẹ iwe mimọ meji ti iṣẹ itọka yẹn tọka si kò fi ẹ̀rí hàn ni ọnakọna pe awọn Kristian ọrundun kìn-ínní wo ọjọ akọkọ ninu ọsẹ gẹgẹ bi “ọjọ isin pataki wọn ninu ṣọọṣi.”
Ẹsẹ iwe akọkọ, Iṣe 20:7, wulẹ ṣe akọsilẹ pe Pọọlu, awọn arinrin ajo alabaakẹgbẹ rẹ̀, ati awọn Kristian lati Troas pade papọ ni ọjọ kìn-ínní ọsẹ fun ounjẹ. Niwọnbi Pọọlu yoo ti lọ ni ọjọ ti o tẹle e ti ki yoo sì rí wọn mọ́ fun akoko gigun kan, oun lò anfaani naa lati ba wọn sọ̀rọ̀ fun akoko gigun.
Ẹsẹ iwe keji, 1 Kọrinti 16:2, fun awọn Kristian ti o wà ni Kọrinti ni iṣiri lati ya owó sọtọ “ni gbogbo ọjọ akọkọ ọsẹ” ki wọn baa lè ni ohun kan lati fi tọrẹ fun awọn ti o ṣe alaini ni Judea. Ọmọwe akẹkọọjinlẹ Adolf Deissmann damọran pe ọjọ yii ti nilati jẹ ọjọ owó sisan. Bi o ti wu ki o ri, idamọran Poọlu jẹ eyi ti o gbeṣẹ, niwọnbi owó ti lè tán lọwọ laaarin ọsẹ.
Kò si ibikan ninu Bibeli ti a ti sọ pe awọn Kristian ni akoko awọn apọsteli wò ọjọ akọkọ ọsẹ, ti a npe ni Sunday nisinsinyi, gẹgẹ bi iru ọjọ Isinmi Kristian kan, ọjọ kan ti a ya sọtọ fun awọn ipade ijọsin wọn ti wọn nṣe deedee. Kiki lẹhin iku awọn apọsteli ni Sunday wa di eyi ti a ńwò lọna yii ti a sì wa ńpè é ni “ọjọ Oluwa.” Eyi jẹ apakan ipẹhinda ti Jesu ati awọn apọsteli funraawọn sọtẹlẹ.—Matiu 13:36-43; Iṣe 20:29, 30; 1 Johanu 2:18.
Nigba naa, ki ni “ọjọ Oluwa”? Ayika ọ̀rọ̀ Iṣipaya 1:10 tọkasi Jesu gẹgẹ bi Oluwa ẹni ti ọjọ naa jẹ tirẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun so awọn ọrọ bii “ọjọ Oluwa wa Jesu Kristi” mọ akoko idajọ fun araye ati imupadabọsipo Paradise.—1 Kọrinti 1:8; 15:24-26; Filipi 1:6, 10; 2:16.
Nipa bayii, Hans Bruns, ninu itumọ rẹ̀ pẹlu alaye, Das Neue Testament (Majẹmu Titun), tọna nigba ti o wi pe: “Awọn diẹ di i mu sibẹ pe oun [Johanu] nsọrọ nihin-in nipa Sunday, ṣugbọn o ṣeeṣe julọ pe oun ntọkasi Ọjọ nla Oluwa, eyi ti gbogbo apejuwe rẹ̀ ti o tẹle e niiṣe pẹlu rẹ̀.” W. E. Vine wi pe: “‘Ọjọ Oluwa naa’ . . . jẹ ọjọ idajọ rẹ̀ ti a fihan lori aye.” Lexikon zur Bibel (Iwe Gbédègbẹ́yọ̀ Bibeli) lati ọwọ Fritz Rienecker sọ pe “ọjọ Oluwa” lọna ti o han kedere tọkasi “ọjọ idajọ.”
Oye ti o tọna nipa ọrọ naa “ọjọ Oluwa” ran wa lọwọ lati loye gbogbo iwe Iṣipaya. Ju bẹẹ lọ, ẹri naa ni pe ọjọ yẹn ti bẹrẹ ṣaaju isinsinyi. Bawo ni o ti ṣe pataki to, nigba naa, wi pe ki awa ‘gbọ́ awọn ọ̀rọ̀ asọtẹlẹ inú Iṣipaya ki a sì pa awọn ohun ti a kọ sinu rẹ̀ mọ́’!—Iṣipaya 1:3, 19.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Awọn alaye ṣiṣekedere ti o sì ba igba mu ti ẹsẹ kọọkan ninu iwe Iṣipaya ni a gbekalẹ ninu iwe naa “Revelation—Its Grand Climax At Hand!” Aranṣe ikẹkọọ Bibeli ti o fanilọkan mọra yii wà larọọwọto ni èdè 33 nisinsinyi