Fi Ọlọrun Ṣe Akọkọ Ninu Igbesi-aye Idile Rẹ!
BOB ATI JEAN—awọn tọkọtaya ti a mẹnukan ninu ọrọ ẹkọ iṣaaju—ni ko kọ ara wọn silẹ. Dipo eyi, wọn jiroro awọn iṣoro wọn pẹlu Kristian ojiṣẹ kan. Ko pẹ ti oun fi loye pe awọn iṣoro wọn niti ipilẹ jẹyọ lati inu awọn ipilẹ igbesi-aye wọn ti o yatọ sira.
Fun apẹẹrẹ, niwọn bi Bob ti wa lati inu idile ti iṣẹ wọn jẹ iṣẹ ọwọ ati iṣẹ ti o gba agbara ti oun funraarẹ si nṣiṣẹ agbara, oun fẹ lati maa jẹ ounjẹ okele laraarọ. Jean, ti o wa lati inu idile alakọwe, maa ngbe kọfi ati burẹdi fun un jẹ. Nitori naa èdèkòyedè lori ounjẹ owurọ gbèru di ìjà ńlá!
Bob ati Jean nilati mu ijumọsọrọpọ wọn sunwọn sii. Bi o ti wu ki o ri, okunfa tootọ gidi fun idaamu wọn jinlẹ ju bẹẹ lọ. Ojiṣẹ naa beere pe, “Njẹ ẹ nwo ara yin ẹnikinni keji ninu imọlẹ 1 Kọrinti 13:4?” Ọrọ ẹsẹ Bibeli naa ka pe: “Ifẹ a maa mu suuru, a si maa ṣeun, ifẹ kii ṣe ilara, ifẹ kii sọrọ igberaga, kii fẹ̀.” Ẹsẹ ti o tẹle e sọ pe ifẹ “kii huwa àìtọ́, kii wa ohun ti araarẹ, a kii mu binu, bẹẹni kii gbiro ohun buburu.” Jean ati Bob muratan lati fi awọn ọrọ wọnyi silo ninu ìbáṣepọ̀ wọn.
Awọn iṣoro tọkọtaya yii lakọọḳọ nbeere fun ojutuu kan nipa tẹmi. Niwọn bi Bob ati Jean ti fẹ́lati maa baa niṣo ni didi ibatan rere mu pẹlu Ọlọrun, ju gbogbo rẹ lọ wọn nilo lati fi awọn ilana Bibeli si ilo ki wọn si mọ pe “bikoṣe pe Oluwa [“Jehofa,” New World Translation] ba kọ ile naa, awọn ti nkọ ọ nṣiṣẹ lasan.” (Saamu 127:1) Ẹsẹ 3 si 5 niiṣe pẹlu gbigbe idile kan ró. Aṣeyọri ti o tobi julọ ní gbígbé ayọ idile ga ńwá lati inu fifi Ọlọrun ṣe akọkọ ninu igbesi-aye idile.—Efesu 3:14, 15.
Ohun ti Fifi Ọlọrun Ṣe Akọkọ Ní Nínú
Fifi Ọlọrun ṣe akọkọ ninu igbesi-aye idile rẹ lọ rekọja ọrọ naa, “Idile ti ngbadura papọ wà papọ.” Gẹgẹbi iwe agberohin jade naa Family Relations ti wi, ọpolọpọ gbagbọ “pe isin nmu ibaṣepọ onilera laaarin idile rọrun sii ti o si nmu itẹlọrun igbesi-aye awọn mẹmba rẹ ga sii.” Ṣugbọn wiwulẹ ṣe isin kan kii ṣe ohun kan naa pẹlu fifi Ọlọrun ṣe akọkọ. Ọpọlọpọ dìrọ̀ mọ́ isin kan nipa ilana nitori iwa-aṣa, ofin atọwọdọwọ idile tabi anfaani ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. Ọlọrun ko ni ipa ti o pọ lori igbesi-aye wọn ojoojumọ. Eyi ti o ṣe pataki ju, kii ṣe gbogbo isin ni o jẹ “isin mimọ ati alaileeri niwaju Ọlọrun.”—Jakọbu 1:27.
Lati fi Ọlọrun ṣe akọkọ ninu igbesi-aye idile wa, awa ati awọn ololufẹ wa gbọdọ jọsin Jehofa, “Ọga Ogo lori aye gbogbo,” ni ibamu pẹlu awọn ohun ti o beere fun. (Saamu 83:18) Ọmọkunrin Ọlọrun, Jesu Kristi, wipe: “Wakati nbọ, o si de tan nisinsinyi, nigba ti awọn olusin tootọ yoo maa sin Baba ni ẹmi ati ni otitọ, Nitori iru wọn ni Baba nwa ki o maa sin oun. Ẹmi ni Ọlọrun, awọn ẹni ti nsin in ko le ṣe alaisin in ni ẹmi ati ni otitọ.” (Johanu 4:23, 24) Lati jọsin Jehofa Ọlọrun “ni ẹmi,” ijọsin mimọ ọlọwọ wa ni a gbọdọ sún ṣiṣẹ lati inu ọkan-aya ti o kun fun ifẹ ati igbagbọ. (Maaku 12:28-31; Galatia 2:16) Jijọsin Jehofa ni “otitọ” nbeere pe ki a kọ̀ awọn irọ́ ijọsin eke silẹ ki a si faramọ ifẹ inu rẹ ni kikun gẹgẹ bi a ṣe ṣipaya ninu Bibeli. A ko le fi Jehofa Ọlọrun ṣe akọkọ ayafi bi isin wa ba doju ọpa idiwọn rẹ.a Ki ni diẹ ninu awọn wọnyii? Bawo ni fifi wọn silo ṣe le ṣanfaani fun idile rẹ?
Fifi Ọlọrun Ṣe Akọkọ Gẹgẹ bi Ọkọ
Ni 1 Kọrinti 11:3, Bibeli wipe: “Kristi ni ori olukuluku ọkunrin, ori obinrin si ni ọkọ rẹ, ati ori Kristi si ni Ọlọrun.” Bi iwọ ba jẹ ọkọ kan, iwọ ni ẹru-iṣẹ tí Ọlọrun fi fun ọ lati jẹ olori oluṣepinnu ninu idile rẹ. Ṣugbọn eyi ko fun ọkọ eyikeyi ni aṣẹ lati jẹ aninilara tabi apàṣẹ wàá.
Bibeli gba awọn ọkọ niyanju lati ronú nipa imọlara awọn aya wọn nigba ti wọn ba nṣe awọn ipinnu ti o nipa lori wọn. (Fiwe Jẹnẹsisi 21:9-14) Nitootọ, Iwe Mimọ rọ gbogbo wa lati ‘maṣe wo ohun tiwa, ṣugbọn olukuluku ohun ti ẹlomiran.’ (Filipi 2:2-4) Nibi ti kò ba ti we mọ ilana Bibeli kankan, ọkọ Kristian kan niye igba yoo juwọ silẹ fun ohun ti aya rẹ yànláàyò. Nini ifẹ ọkan ninu rẹ bi ẹnikan, oun yoo tun ri i daju pe oun ni a ko fi awọn ẹru-iṣẹ pá lórí. Fun apẹẹrẹ, ọkọ naa le ràn án lọwọ pẹlu awọn iṣẹ ile, paapaa julọ bi ó ba ni iṣẹ ounjẹ oojọ kan.
Apọsteli Pọọlu kọwe pe: “O tọ́ ki awọn ọkunrin ki o maa fẹran awọn aya wọn gẹgẹbi ara wọn tikaara wọn. Ẹni ti o ba fẹ aya rẹ o fẹran oun tikaara rẹ. Nitori ko si ẹnikan ti o tii korira ara rẹ; bikoṣe ki o maa bọọ ki o si maa ṣikẹ rẹ gẹgẹbi Kristi si ti nṣe si ijọ.” (Efesu 5:28, 29) Jesu Kristi ba awọn mẹmba ijọ lo ni ọna onifẹẹ.
Eyi ti o tun yẹ fun afiyesi ni imọran apọsteli Peteru pe: “Ẹyin ọkọ, ẹ maa fi oye ba awọn aya yin gbé, ẹ maa fi ọla fun aya, bi ohun èelò ti ko lagbara, ati pẹlu bi ajumọ jogun oore ọfẹ iye; ki adura yin ki o maa baa ni idena.” (1 Peteru 3:7) Ko ha muni ronu jinlẹ lati mọ pe biba iyawo ẹni lo lọna ainifẹ le dena awọn adura ọkọ kan? Bẹẹni, ọkunrin kan gbọdọ ba aya rẹ lo ni ọna onifẹẹ bi Ọlọrun ba nilati gbọ́ ki o si dahun awọn adura rẹ.
Fifi Ọlọrun ṣe akọkọ tun kan ipo ibatan baba pẹlu awọn ọmọ rẹ. Oun nilati ṣaniyan lọna jijinlẹ nipa ire alaafia tẹmi wọn. Sibẹ, ninu iwadii pataki kan ni U.S., kiki ìlàjì ninu awọn ọkunrin ni wọn sọ pe “kikopa ninu ikẹkọ Iwe Mimọ tabi ijiroro awujọ” ‘ṣe pataki julọ ninu idagba tẹmi idile wọn.’ Awọn yooku tọka si iru awọn nǹkan gẹgẹbi “wiwo tabi fifeti silẹ si awọn eto onisin ti a ngbe jade lori tẹlifiṣọn tabi redio” tabi ‘rironu lori itumọ igbesi-aye.’
Bi o ti wu ki o ri, Bibeli sọ fun awọn baba pe: “Ẹ maṣe mu awọn ọmọ yin binu: ṣugbọn ẹ maa tọ́ wọn ninu ẹkọ ati ikilọ Oluwa [“Jehofa,” NW].” (Efesu 6:4) Laaarin awọn Ẹlẹrii Jehofa, baba ni a reti pe ki o mu ipo iwaju ninu ijọsin idile. Nipa ṣiṣe awọn ikẹkọọ idile deedee, lilọ si awọn ipade Kristian, ati titẹle awọn ohun miiran ti Iwe mimọ beere fun, iru awọn ọkunrin bẹẹ fi Ọlọrun ṣe akọkọ ninu igbesi-aye idile.
Fifi Ọlọrun Ṣe Akọkọ Gẹgẹ bi Aya Kan
Bi iwọ ba jẹ aya kan, iwọ le fi Ọlọrun ṣe akọkọ nipa ṣiṣetilẹhin fun ọkọ rẹ ninu ipa-iṣẹ rẹ gẹgẹbi olori idile. Bibeli wipe: “Ẹyin aya, ẹ maa tẹriba fun awọn ọkọ yin, gẹgẹbi o ti yẹ ninu Oluwa.” (Kolose 3:18) Eyi le ṣoro lọpọlọpọ bi ọkunrin kan ba jẹ ẹni ti o dinú tabi alainipinnu nipa mimu ipo iwaju ninu ijọsin idile. Ninu iṣẹlẹ eyikeyi, mimu awọn abuku rẹ wa sojutaye nigba gbogbo tabi, pabambarì julọ, ki o pè é nija yoo wulẹ mu pakanleke idile pọ̀ sii.
Owe 14:1 wipe: “Olukuluku ọlọgbọn obinrin ni ikọ ile rẹ: ṣugbọn aṣiwere a fi ọwọ rẹ fà á lulẹ.” Ọna kan ti obinrin ọlọgbọn nitootọ kan ti o ti gbeyawo le gba fi Ọlọrun ṣe akọkọ ki o si ‘kọ ile rẹ’ ni nipa wiwa ni itẹriba si ọkọ rẹ. (1 Kọrinti 11:3) Pẹlu ‘ofin iṣeun ti wa ni ahọn rẹ,’ ó yẹra fun jijẹ ẹni ti o nṣariwisi ọkọ rẹ lọna ti ko pọndandan. (Owe 31:26) Oun tun ṣiṣẹ kara lati mu ki awọn ipinnu ọkọ rẹ ṣaṣeyọrisi rere.
Ọna miiran ti obinrin kan ti o ti ṣegbeyawo le gba fi Ọlọrun ṣe akọkọ ni lati jẹ aya alakitiyan. Dajudaju, bi oun ba nilati ṣiṣẹ ounjẹ oojọ, o lè má ni yala akoko tabi okun ti o nilo lati tọju ile rẹ gẹgẹbi o ti fẹ. Sibẹ o ṣi le sakun lati dabi “obinrin oniwa rere” nipa ẹni ti Bibeli wipe: “O fi oju silẹ wo iwa awọn ara ile rẹ. Ko si jẹ ounjẹ ìmẹ́lẹ́.”—Owe 31:10, 27.
Ju gbogbo re lọ, aya kan nilati fi ijọsin Ọlọrun ṣe akọkọ ninu igbesi-aye rẹ. Ọpọlọpọ ti wọn nbẹ Gbọngan Ijọba awọn Ẹlẹrii Jehofa wo fun igba akọkọ sọrọ lori irisi mímọ́ tonitoni awọn ọmọ. Iṣẹ aya kan ni ọna yii jẹ aláìseédíyelé. Ṣugbọn oun gbọdọ tun ṣiṣẹ lati tọju ipo tẹmi rẹ nipasẹ adura, ikẹkọọ, ati iṣẹ-isin si Ọlọrun.
Fifi Ọlọrun Ṣe Akọkọ Gẹgẹ bi Ọdọ
Ọrọ-ẹkọ kan ninu Adolescent Counselor wipe: “Awọn ọmọde ti ni itẹsi lati mu awọn ẹmi ironu ati ọgbọn imọ-ọran dagba ti o ti mu ki wọn gba iṣakoso lọwọ awọn obi wọn. . . . Lẹhin ti a ti ṣi wọn paya si awujọ kan ti o tẹnumọ ti o si fiyin fun itẹlọrun oju ẹsẹ ati ọrọ̀ ohun ti ara, awọn ọdọlangba mu ẹmi ironu ‘mo fẹ́ ẹ nisinsinyi dagba.’” Bi iwọ ba jẹ ọdọ kan, iyẹn ha jẹ ẹmi ironu rẹ bi?
Kolose 3:20 wipe: “Ẹyin ọmọ, ẹ maa gbọ ti awọn obi yin ni ohun gbogbo: nitori eyi dara gidigidi ninu Oluwa.” Ọdọ kan ti o wo iru igbọran bẹẹ gẹgẹ bii ohun abeere fun atọrunwa yoo fọwọsowọpọ pẹlu awọn obi rẹ. Fun apẹẹrẹ, oun ki yoo fi àìlọ́wọ̀ han si wọn ni ikọkọ nipa kikẹgbẹpọ pẹlu awọn ọmọ ile ẹkọ ẹlẹgbẹ rẹ ti wọn ko fọwọ́ sí; bẹẹni oun ki yoo gbiyanju lati dọgbọn dari obi eyikeyi lọna alumọkọroyi lati ṣe ohun ti ó wù ú. (Owe 3:32) Kaka bẹẹ, ọdọ eyikeyi ti o fi Ọlọrun ṣe akọkọ ninu igbesi-aye yoo juwọ silẹ tẹriba fun itọsọna onifẹẹ ti obi.
Fi Ọlọrun Ṣe Akọkọ!
Laika ipo ti a ni ninu agbo idile si, awa nilati fi Ọlọrun ṣe akọkọ ninu igbesi-aye ki a si mu ipo ibatan timọtimọ dagba pẹlu rẹ. Njẹ iwọ ati idile rẹ nṣe iyẹn bi?
Ninu “awọn ọjọ ikẹhin” wọnyii, gbogbo wa dojukọ “awọn akoko lilekoko.” (2 Timoti 3:1-5, NW) Bi o ti wu ki o ri, o ṣeeṣe lati laasiki nipa tẹmi ki a si la opin eto igbekalẹ awọn nǹkan yii já. (Matiu 24:3-14) Nipa gbigbe igbeṣẹ ni ibamu pẹlu imọ Bibeli pipeye, iwọ ati idile rẹ le ni ireti iwalaaye titilae lori Paradise ilẹ-aye kan. (Luuku 23:43; Johanu 17:3; Iṣipaya 21:3, 4) Bẹẹni, iyẹn le ri bẹẹ bi iwọ ba fi Ọlọrun ṣe akọkọ ninu igbesi-aye idile rẹ.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo akori 22 ninu iwe naa Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, ti a tẹ̀jade lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Aya oniwa rere kan ni a mọriri lọpọlọpọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Bibeli fun awọn ọkọ niṣiiri lati mu ipo iwaju ninu ijọsin idile