ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 10/1 ojú ìwé 8-13
  • Ọlọrun Ha Gbapò Kìíní Nínú Ìdílé Rẹ Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọrun Ha Gbapò Kìíní Nínú Ìdílé Rẹ Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdẹkùn Àtakò Ìdílé
  • Kíkojú Ìpèníjà Náà
  • Èrè Jìngbìnnì Tí Ó Ṣeé Ṣe
  • Kíkẹ́kọ̀ọ́ Láti Ọ̀dọ̀ Jesu
  • Ẹ̀yin Ọkọ, Ẹ̀yin Aya—Ẹ Fara Wé Kristi!
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Kí Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ẹ̀yin Ọkọ, Ẹ Mọ Kristi Ní Orí Yín
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n Fún Àwọn Tọkọtaya
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ẹ̀yin Aya, Ẹ Ní Ọ̀wọ̀ Jíjinlẹ̀ Fún Ọkọ Yín
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 10/1 ojú ìwé 8-13

Ọlọrun Ha Gbapò Kìíní Nínú Ìdílé Rẹ Bí?

“Iwọ . . . gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jehofa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn-àyà rẹ.”—MARKU 12:29‚ 30.

1. Báwo ni ó ti ṣe pàtàkì tó pé kí a nífẹ̀ẹ́ Jehofa?

AKỌ̀WÉ kan bi Jesu léèrè pé: “Àṣẹ wo ni èkínní ninu gbogbo wọn?” Kàkà kí ó fún un ní èrò ara rẹ̀, Jesu dáhùn ìbéèrè rẹ̀ nípa fífa ọ̀rọ̀ yọ láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun nínú Deuteronomi 6:4, 5. Ó fèsì pé: “Èkínní ni, ‘Gbọ́, Óò Israeli, Jehofa Ọlọrun wa jẹ́ Jehofa kanṣoṣo, iwọ sì gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jehofa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn-àyà rẹ ati pẹlu gbogbo ọkàn rẹ ati pẹlu gbogbo èrò inú rẹ ati pẹlu gbogbo okun rẹ.’”—Marku 12:28-30.

2. (a) Àtakò wo ni Jesu ní láti dojú kọ? (b) Kí ni ó lè mú kí ó ṣòro nígbà mìíràn láti wu Jehofa?

2 Láti ṣègbọràn sí ohun tí Jesu pè ní àṣẹ èkíní—èyí tí ó ṣe pàtàkì jù lọ—ń béèrè pé kí a máa ṣe ohun tí ó wu Jehofa nígbà gbogbo. Jesu ṣe bẹ́ẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ní àkókò kan, aposteli Peteru tako ipa ọ̀nà Jesu, àwọn ìbátan rẹ̀ tímọ́tímọ́ náà sì ṣe bẹ́ẹ̀ ní àkókò mìíràn. (Matteu 16:21-23; Marku 3:21; Johannu 8:29) Kí ni ìwọ yóò ṣe bí o bá bá ara rẹ nínú ipò tí ó fara jọ èyí? Jẹ́ kí a sọ pé àwọn mẹ́ḿbà ìdílé fẹ́ kí o pa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli àti kíkẹ́gbẹ́ pọ̀ rẹ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tì. Ìwọ yóò ha fi Ọlọrun sí ipò kìíní nípa ṣíṣe ohun tí ó wù ú bí? Ọlọrun ha gba ipò kìíní, àní pàápàá nígbà tí àwọn mẹ́ḿbà ìdílé bá tilẹ̀ tako ìsapá rẹ láti ṣiṣẹ́ sìn ín bí?

Ìdẹkùn Àtakò Ìdílé

3. (a) Kí ni ó lè jẹ́ àbájáde ẹ̀kọ́ Jesu fún ìdílé? (b) Báwo ni àwọn mẹ́ḿbà ìdílé ṣe lè fi ẹni tí wọ́n ní ìfẹ́ni tí ó ga jù lọ sí hàn?

3 Jesu kò fẹnu kéré ìnira tí ó lè wáyé nígbà tí àwọn yòókù nínú ìdílé bá tako mẹ́ḿbà ìdílé tí ó tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ rẹ̀. Jesu sọ pé: “Awọn ọ̀tá ènìyàn yoo jẹ́ awọn ènìyàn agbo ilé oun fúnra rẹ̀.” Síbẹ̀, láìka àbájáde bíbaninínújẹ́ náà sí, Jesu fi ẹni tí ó ní láti gba ipò kìíní hàn nípa sísọ pé: “Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ni tí ó pọ̀ fún baba tabi ìyá ju èyí tí ó ní fún mi kò yẹ fún mi; ẹni tí ó bá sì ní ìfẹ́ni tí ó pọ̀ fún ọmọkùnrin ati ọmọbìnrin ju èyí tí ó ní fún mi kò yẹ fún mi.” (Matteu 10:34-37) A ń fi Jehofa Ọlọrun sí ipò kìíní nípa títẹ̀lé àwọn ẹ̀kọ́ Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi, ẹni tí ó jẹ́ “àwòrán naa gẹ́lẹ́ ti wíwà [Ọlọrun] gan-an.”—Heberu 1:3; Johannu 14:9.

4. (a) Kí ni Jesu sọ pé jíjẹ́ ọmọlẹ́yìn òun ní nínú? (b) Ní èrò ìtumọ̀ wo ni àwọn Kristian fi ní láti kórìíra àwọn mẹ́ḿbà ìdílé wọn?

4 Ní àkókò mìíràn, nígbà tí Jesu ń jíròrò ohun tí jíjẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tòótọ́ ní nínú gan-an, ó sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá wá sọ́dọ̀ mi tí kò sì kórìíra baba ati ìyá ati aya ati awọn ọmọ ati awọn arákùnrin ati awọn arábìnrin rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni, àní ati ọkàn tirẹ̀ pàápàá, oun kò lè jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi.” (Luku 14:26) Ó hàn kedere pé, Jesu kò ní in lọ́kàn pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun ní láti kórìíra àwọn mẹ́ḿbà ìdílé wọn ní ti gidi, níwọ̀n bí ó ti pàṣẹ fún àwọn ènìyàn láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn pàápàá. (Matteu 5:44) Kàkà bẹ́ẹ̀, níhìn-ín, Jesu ní in lọ́kàn pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn mẹ́ḿbà ìdílé ní ọ̀nà tí ó rẹlẹ̀ sí bí wọ́n ti nífẹ̀ẹ́ Ọlọrun. (Fi wé Matteu 6:24.) Ní títẹ̀lé ìlàlóye náà, Bibeli sọ pé, Jekọbu “kórìíra” Lea, ó sì nífẹ̀ẹ́ Rakeli, èyí tí ó túmọ̀ sí pé, kò nífẹ̀ẹ́ Lea tó bí ó ti nífẹ̀ẹ́ arábìnrin rẹ̀, Rakeli. (Genesisi 29:30-32) Jesu sọ pé, a ní láti kórìíra, tàbí nífẹ̀ẹ́ “ẹ̀mí” tiwa tàbí ìwàláàyè wa pàápàá, ní ọ̀nà tí ó rẹlẹ̀, sí bí a ti nífẹ̀ẹ́ Jehofa!

5. Báwo ni Satani ṣe ń fi àrékérekè lo ìṣètò ìdílé?

5 Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá àti Olùfúnni ní ìyè, Jehofa yẹ fún ìfọkànsìn pátápátá láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. (Ìṣípayá 4:11) Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Emi tẹ eékún mi ba fún Baba, ẹni tí olúkúlùkù ìdílé ní ọ̀run ati lórí ilẹ̀-ayé jẹ ní gbèsè fún orúkọ rẹ̀.” (Efesu 3:14‚ 15) Jehofa dá ìṣètò ìdílé ní ọ̀nà àgbàyanu, tí àwọn mẹ́ḿbà ìdílé fi ń ní ìfẹ́ni àdánidá fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì. (1 Awọn Ọba 3:25, 26; 1 Tessalonika 2:7) Bí ó ti wù kí ó rí, lọ́nà àrékérekè, Satani Èṣù ń lo ọ̀nà ìfẹ́ni àdánidá tí ìdílé ní yìí, tí ó ní ìfẹ́ ọkàn láti wu ẹni tí a nífẹ̀ẹ́ nínú. Ó ń rúná sí àtakò ìdílé, ọ̀pọ̀ sì ń rí i pé ó jẹ́ ìpèníjà láti dúró gbọn-in-gbọn-in ti òtítọ́ Bibeli lójú àtakò ìdílé.—Ìṣípayá 12:9, 12.

Kíkojú Ìpèníjà Náà

6, 7. (a) Báwo ni a ṣe lè ran àwọn mẹ́ḿbà ìdílé lọ́wọ́ láti mọrírì ìjẹ́pàtàkì ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli àti ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ Kristian? (b) Báwo ni a ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn mẹ́ḿbà ìdílé wa ní tòótọ́?

6 Kí ni ìwọ yóò ṣe bí a bá fi dandan mú ọ láti yàn láàárín wíwu Ọlọrun tàbí wíwu mẹ́ḿbà ìdílé kan? Ìwọ yóò ha wí àwíjàre pé Ọlọrun kò retí pé kí a kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ òun, kí a sì fi àwọn ìlànà òun sílò, bí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò bá dá ìyapa sílẹ̀ nínú ìdílé bí? Ṣùgbọ́n ronú nípa rẹ̀ wò ná. Bí o bá juwọ́ sílẹ̀, tí o sì dáwọ́ kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tàbí kíkẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa dúró, báwo ni àwọn olólùfẹ́ yóò ṣe lóye pé ìmọ̀ pípéye nípa Bibeli jẹ́ ọ̀ràn ìyè òun ikú?—Johannu 17:3; 2 Tessalonika 1:6-8.

7 A lè ṣàkàwé ipò náà lọ́nà yìí: Bóyá mẹ́ḿbà kan nínú ìdílé ní ọkàn-ìfẹ́ tí ó ré kọjá ààlà fún ọtí líle. Ǹjẹ́ gbígbójú fò tàbí fífàyè gba ìṣòro ọtí mímu rẹ̀ yóò ṣàǹfààní ní ti gidi fún un bí? Yóò ha sàn láti mú kí àlàáfíà máa bá a nìṣó nípa jíjuwọ́ sílẹ̀, kí o má sì ṣe ohunkóhun nípa ìṣòro rẹ̀ bí? Bẹ́ẹ̀ kọ́, ó ṣeé ṣe kí o gbà pé yóò dára jù lọ láti gbìyànjú láti ràn án lọ́wọ́ láti borí ìṣòro ọtí mímu rẹ̀, àní bí èyí yóò bá tilẹ̀ túmọ̀ sí fífi ìgboyà dojú kọ ìrunú àti ìhalẹ̀mọ́ni rẹ̀. (Owe 29:25) Ní ọ̀nà kan náà, bí o bá nífẹ̀ẹ́ àwọn mẹ́ḿbà ìdílé rẹ ní tòótọ́, ìwọ kì yóò juwọ́ sílẹ̀ fún ìsapá wọn láti mú ọ dá kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli dúró. (Ìṣe 5:29) Kìkì nípa mímú ìdúró gbọn-in-gbọn-in ni ìwọ fi lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọrírì pé, gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ Kristi túmọ̀ sí ìwàláàyè wa fúnra wa.

8. Báwo ni a ṣe lè jàǹfààní láti inú òkodoro òtítọ́ náà pé Jesu fi ìṣòtítọ́ ṣe ìfẹ́ inú Ọlọrun?

8 Nígbà mìíràn, fífi Ọlọrun ṣáájú lè ṣòro gidigidi. Ṣùgbọ́n rántí pé, Satani mú kí ó ṣòro fún Jesu pẹ̀lú láti ṣe ìfẹ́ Ọlọrun. Síbẹ̀, Jesu kò fìgbà kankan juwọ́ sílẹ̀; ó fara da ìdálóró amúnijẹ̀rora lórí igi nítorí tiwa. Bibeli sọ pé: “Jesu Kristi [ni] Olùgbàlà wa.” “Ó kú fún wa.” (Titu 3:6; 1 Tessalonika 5:10) Àwa kò ha dúpẹ́ pé Jesu kò juwọ́ sílẹ̀ fún àtakò bí? Nítorí pé ó fara da ikú ìrúbọ, a ní ìfojúsọ́nà fún ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé titun òdodo alálàáfíà, nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tí a ta sílẹ̀.—Johannu 3:16‚ 36; Ìṣípayá 21:3‚ 4.

Èrè Jìngbìnnì Tí Ó Ṣeé Ṣe

9. (a) Báwo ni àwọn Kristian ṣe lè nípìn-ín nínú gbígba àwọn mìíràn là? (b) Báwo ni ipò ìdílé Timoteu ṣe rí?

9 O ha mọ̀ pé ìwọ pẹ̀lú lè nípìn-ín nínú gbígba àwọn ẹlòmíràn là, títí kan àwọn olólùfẹ́ tí wọ́n jẹ́ ìbátan ọ̀wọ́n pẹ̀lú bí? Aposteli Paulu rọ Timoteu pé: “Dúró ninu awọn nǹkan wọnyi [tí a ti kọ́ ọ], nitori nipa ṣíṣe èyí iwọ yoo gba ara rẹ ati awọn wọnnì tí ń fetísílẹ̀ sí ọ là.” (1 Timoteu 4:16) Timoteu gbé nínú agboolé tí ó yapa, bàbá rẹ̀ ará Griki jẹ́ aláìgbàgbọ́. (Ìṣe 16:1; 2 Timoteu 1:5; 3:14) Bí a kò tilẹ̀ mọ̀ bóyá bàbá Timoteu di onígbàgbọ́ rárá, ó ṣeé ṣe kí ìhùwàsí olùṣòtítọ́ ti ìyàwó rẹ̀, Eunike, àti ti Timoteu sún un láti ṣe bẹ́ẹ̀.

10. Kí ni àwọn Kristian lè ṣe ní ṣíṣojú fún àwọn alábàágbéyàwó ẹlẹgbẹ́ wọn?

10 Ìwé Mímọ́ ṣí i payá pé àwọn ọkọ àti aya, tí wọ́n di òtítọ́ Bibeli mú láìyẹsẹ̀, lè dákún gbígba àwọn alábàáṣègbéyàwó ẹlẹgbẹ́ wọn tí kì í ṣe Kristian là, nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti di onígbàgbọ́. Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Bí arákùnrin èyíkéyìí bá ní aya tí kò gbàgbọ́, síbẹ̀ tí obìnrin naa sì faramọ́ bíbá a gbé, kí oun máṣe fi obìnrin naa sílẹ̀; ati obìnrin tí ó ní ọkọ tí kò gbàgbọ́, síbẹ̀ tí ọkùnrin naa sì faramọ́ bíbá a gbé, kí oun máṣe fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀. Nitori, aya, bawo ni o ṣe mọ̀ bóyá iwọ yoo gba ọkọ rẹ là? Tabi, ọkọ, bawo ni o ṣe mọ̀ bóyá iwọ yoo gba aya rẹ là?” (1 Korinti 7:12‚ 13‚ 16) Aposteli Peteru ṣàpèjúwe bí àwọn aya, ṣe lè tipa bẹ́ẹ̀ gba àwọn ọkọ wọn là, nípa rírọ̀ wọ́n pé: “Ẹ wà ní ìtẹríba fún awọn ọkọ tiyín, kí ó baà lè jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni kò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ naa, kí a lè jèrè wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà awọn aya wọn.”—1 Peteru 3:1.

11, 12. (a) Èrè wo ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Kristian ti rí gbà, kí ni wọ́n sì ṣe láti rí i gbà? (b) Sọ ìrírí mẹ́ḿbà ìdílé kan tí a san èrè fún nítorí ìfaradà oníṣòtítọ́ rẹ̀.

11 Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ti di Ẹlẹ́rìí Jehofa lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù àti ọdún pàápàá ti ṣíṣàtakò sí ìgbòkègbodò Kristian ti àwọn ìbátan wọn tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí. Ẹ wo irú èrè tí èyí jẹ́ fún àwọn Kristian tí wọ́n ti dúró láìyẹsẹ̀, ẹ sì wo irú ìbùkún tí ó jẹ́ fún alátakò tẹ́lẹ̀ rí náà! Pẹ̀lú ohùn ìmoore, Kristian alàgbà kan tí ó jẹ́ ẹni ọdún 74 ròyìn pé: “Mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ ìyàwó àti àwọn ọmọ mi fún dídúró ti òtítọ́ ní àwọn ọdún tí mo fi ń takò wọ́n.” Ó sọ pé, fún ọdún mẹ́ta, òun fi orí kunkun kọ̀ láti gba ìyàwó òun láyè láti bá òun sọ̀rọ̀ nípa Bibeli. Ó sọ pé: “Ṣùgbọ́n ó lo ọgbọ́n ìfiṣemọ̀rònú fún mi, ó sì máa ń jẹ́rìí fún mi bí ó ti ń fi ọwọ́ pa mí lẹ́sẹ̀. Ẹ wo bí mo ti ṣọpẹ́ tó pé kò juwọ́ sílẹ̀ fún àtakò mi!”

12 Ọkọ mìíràn tí ó tako ìdílé rẹ̀ kọ̀wé pé: ‘Èmi ni ọ̀tá tí ó burú jù lọ tí ìyàwó mi ní, nítorí lẹ́yìn tí ó gba òtítọ́, mo halẹ̀ mọ́ ọn, a sì máa ń jà lójoojúmọ́; ìyẹn ni pé, èmi ni mo máa ń dá ìjà náà sílẹ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ já sí pàbó; ìyàwó mi dìrọ̀ mọ́ Bibeli. Ọdún 12 kọjá pẹ̀lú ìjà tí ó gbóná janjan ní ìlòdìsí òtítọ́ àti sí ìyàwó àti ọmọ mi. Lọ́dọ̀ àwọn méjèèjì, mo gbé agọ̀ Èṣù wọ̀.’ Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí yẹ ìwà ara rẹ̀ wò. Ó ṣàlàyé pé: ‘Mo rí bí mo ti jẹ́ onínúfùfù tó. Mo ka Bibeli, ọpẹ́ sì ni fún ìtọ́ni rẹ̀, mo ti di Ẹlẹ́rìí tí a ti batisí nísinsìnyí.’ Ronú nípa èrè kíkọyọyọ aya náà, ti ṣíṣèrànwọ́ láti ‘gba ọkọ rẹ̀ là’ nípa fífi ìṣòtítọ́ fara da àtakò rẹ̀ fún ọdún 12!

Kíkẹ́kọ̀ọ́ Láti Ọ̀dọ̀ Jesu

13. (a) Kí ni kókó ẹ̀kọ́ tí àwọn ọkọ àti aya ní láti kọ́ láti inú ipa ọ̀nà ìgbésí ayé Jesu? (b) Báwo ni àwọn ènìyàn tí ó ṣòro fún láti juwọ́ sílẹ̀ fún ìfẹ́ inú Ọlọrun ṣe ń jàǹfààní láti inú àpẹẹrẹ Jesu?

13 Ẹ̀kọ́ pàtàkì tí àwọn ọkọ àti aya ní láti kọ́ nínú ipa ọ̀nà ìgbésí ayé Jesu ni ti ìgbọràn sí Ọlọrun. Jesu wí pé: “Nígbà gbogbo ni mo ń ṣe ohun tí ó wù ú.” “Kì í ṣe ìfẹ́-inú ara mi ni mo ń wá, bíkòṣe ìfẹ́-inú ẹni tí ó rán mi.” (Johannu 5:30; 8:29) Àní nígbà tí Jesu rí i pé apá kan ìfẹ́ inú Ọlọrun pàápàá kò bára dé, ó ṣe ìgbọràn. Ó gbàdúrà pé: “Bí iwọ bá fẹ́, mú ife yii kúrò lórí mi.” Ṣùgbọ́n ó yára fi kún un pé: “Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ìfẹ́-inú mi ni kí ó ṣẹ, bíkòṣe tìrẹ.” (Luku 22:42) Jesu kò sọ pé kí Ọlọrun yí ìfẹ́ inú Rẹ̀ padà; ó fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Ọlọrun ní tòótọ́ nípa fífi ìgbọràn juwọ́ sílẹ̀ fún ohun yòówù kí ó jẹ́ ìfẹ́ inú Ọlọrun fún un. (1 Johannu 5:3) Fífi ìfẹ́ inú Ọlọrun sí ipò kìíní nígbà gbogbo, gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ṣe, ṣe pàtàkì gidigidi fún àṣeyọrí, kì í ṣe kìkì nínú ìgbésí ayé kòlọ́kọ kòláya nìkan, ṣùgbọ́n nínú ìgbésí ayé lọ́kọláya àti ti ìdílé pẹ̀lú. Ṣàgbéyẹ̀wò bí èyí ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀.

14. Báwo ni àwọn Kristian kan ṣe ronú lọ́nà tí kò tọ́?

14 Bí a ti ṣàkíyèsí lókè, nígbà tí àwọn onígbàgbọ́ bá fi Ọlọrun sí ipò kìíní, wọ́n ń gbìyànjú láti dúró ti alábàágbéyàwó wọn aláìgbàgbọ́, ó sì máa ń fìgbà gbogbo ṣeé ṣe fún wọn láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wá sí ojú ọ̀nà ìgbàlà. Àní nígbà tí àwọn alábàágbéyàwó méjèèjì bá tilẹ̀ jẹ́ onígbàgbọ́ pàápàá, ìgbéyàwó wọn lè jẹ́ èyí tí kò dára tán pátápátá. Nítorí ìtẹ̀sí ẹ̀ṣẹ̀, àwọn ọkọ àti aya kì í fìgbà gbogbo ní ìrònú onífẹ̀ẹ́ sí ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì. (Romu 7:19‚ 20; 1 Korinti 7:28) Àwọn kan tilẹ̀ ń lọ jìnnà débi pé kí wọ́n máa lépa láti ní alábàágbéyàwó mìíràn, bí wọn kò tilẹ̀ ní ìdí tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu fún ìkọ̀sílẹ̀. (Matteu 19:9; Heberu 13:4) Wọ́n ń ronú pé èyí ni ohun tí ó dára jù lọ fún àwọn, pé ìfẹ́ inú Ọlọrun fún àwọn ọkọ àti aya láti wà papọ̀ ti le koko jù. (Malaki 2:16; Matteu 19:5‚ 6) Láìṣe àníàní, èyí jẹ́ ọ̀nà mìíràn ti níní ìrònú ènìyàn dípò kí ó jẹ́ ti Ọlọrun.

15. Èé ṣe ti fífi Ọlọrun sí ipò kìíní fi jẹ́ ààbò?

15 Ẹ wo irú ààbò tí ó jẹ́ láti fi Ọlọrun sí ipò kìíní! Àwọn tọkọtaya tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ yóò gbìyànjú láti wà papọ̀, kí wọ́n sì yanjú àwọn ìṣòro wọn nípa fífi ìmọ̀ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sílò. Wọ́n tipa báyìí yẹra fún gbogbo ìrora ọkàn tí ó máa ń jẹyọ nígbà tí a bá pa ìfẹ́ inú rẹ̀ tì. (Orin Dafidi 19:7-11) Èyí ni àwọn tọkọtaya kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó ṣàkàwé, nígbà tí wọ́n wà ní bèbè kíkọ ara wọn sílẹ̀, wọ́n pinnu láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bibeli. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tí ìyàwó náà ronú padà lórí ayọ̀ tí ó ti ní nínú ìgbéyàwó rẹ̀, ó sọ pé: “Mo máa ń jókòó, tí mo sì máa ń sunkún, nígbà tí mo bá ṣàgbéyẹ̀wò pé ó ṣeé ṣe kí n má ti lè gbé papọ̀ pẹ̀lú ọkọ mi láti ọ̀pọ̀ ọdún wọ̀nyí wá. Nígbà náà ni n óò gbàdúrà sí Jehofa Ọlọrun, tí n óò sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún ìmọ̀ràn àti ìtọ́sọ́nà rẹ̀ tí ó mú wa wà papọ̀ nínú irú ipò ìbátan aláyọ̀ bẹ́ẹ̀.”

Ẹ̀yin Ọkọ, Ẹ̀yin Aya—Ẹ Fara Wé Kristi!

16. Àpẹẹrẹ wo ni Jesu fi lélẹ̀ fún àwọn ọkọ àti aya?

16 Jesu, ẹni tí ó máa ń fi Ọlọrun sí ipò kìíní nígbà gbogbo, fi àpẹẹrẹ àgbàyanu lélẹ̀ fún àwọn ọkọ àti aya, wọn yóò sì ṣe dáradára bí wọ́n bá fara balẹ̀ kíyèsí i. Àwọn ọkọ ni a rọ̀ láti fara wé ọ̀nà tí Jesu gbà lo ipò orí rẹ̀ lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ lórí àwọn mẹ́ḿbà ìjọ Kristian. (Efesu 5:23) Àwọn Kristian aya sì lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àpẹẹrẹ aláìlálèébù ti jíjuwọ́ sílẹ̀ fún Ọlọrun tí Jesu ní.—1 Korinti 11:3.

17, 18. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Jesu gbà fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ fún àwọn ọkọ?

17 Bibeli pàṣẹ pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ awọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹlu ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un.” (Efesu 5:25) Ọ̀nà pàtàkì kan tí Jesu gbà fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí ìjọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni nípa jíjẹ́ ọ̀rẹ́ wọn tímọ́tímọ́. Jesu wí pé: “Emi ti pè yín ní ọ̀rẹ́, nitori pé gbogbo nǹkan tí mo ti gbọ́ lati ọ̀dọ̀ Baba mi ni mo ti sọ di mímọ̀ fún yín.” (Johannu 15:15) Ronú nípa gbogbo àsìkò tí Jesu lò, tí ó fi ń bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀—ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ìjíròrò tí ó ní pẹ̀lú wọn—àti ìgbọ́kànlé tí ó ní nínú wọn! Ìyẹn kò ha jẹ́ àpẹẹrẹ tí ó gbámúṣé fún àwọn ọkọ bí?

18 Jesu ní ọkàn-ìfẹ́ gidi nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì ní ojúlówó ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún wọn. (Johannu 13:1) Nígbà tí ẹ̀kọ́ rẹ̀ kò yé wọn, ó fara balẹ̀ láti la ọ̀rọ̀ náà yé wọn ní ìkọ̀kọ̀. (Matteu 13:36-43) Ẹ̀yin ọkọ, ire tẹ̀mí ti aya yín ha ṣe pàtàkì sí yín bákan náà bí? O ha máa ń lo àkókò pẹ̀lú rẹ̀, ní rírí i dájú pé òtítọ́ Bibeli ṣe kedere nínú èrò inú àti ọkàn-àyà ẹ̀yin méjèèjì bí? Jesu bá àwọn aposteli rẹ̀ lọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ó kọ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lẹ́kọ̀ọ́. O ha máa ń bá ìyàwó rẹ̀ lọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, ní níní ìpín nínú ìbẹ̀wò ilé dé ilé àti ní dídarí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli bí?

19. Báwo ni ọ̀nà tí Jesu gbà ṣèkáwọ́ àìlera tí ń wá léraléra tí àwọn aposteli rẹ̀ ní ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún àwọn ọkọ?

19 Ní pàtàkì, Jesu pèsè àpẹẹrẹ tí ó ga lọ́lá fún àwọn ọkọ nínú kíkáwọ́ àìpé àwọn aposteli rẹ̀. Nígbà oúnjẹ rẹ̀ tí ó kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn aposteli rẹ̀, ó rí ẹ̀mí ìbánidíje tí ń wá léraléra. Ó ha ṣe lámèyítọ́ rẹ̀ lọ́nà líle koko bí? Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n ó fi ìrẹ̀lẹ̀ fọ ẹsẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. (Marku 9:33-37; 10:35-45; Johannu 13:2-17) O ha ń fi irú sùúrù bẹ́ẹ̀ hàn sí ìyàwó rẹ bí? Dípò kí o máa ráhùn lórí àìlera kan tí ń wá léraléra, o ha ń fi sùúrù ràn án lọ́wọ́, tí o sì ń dé inú ọkàn-àyà rẹ̀ nípa àpẹẹrẹ tìrẹ bí? Ó ṣeé ṣe kí àwọn aya dáhùn padà sí irú ìyọ́nú onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn aposteli ti ṣe lẹ́yìn-ò-rẹyìn.

20. Kí ni àwọn Kristian aya kò ní láti gbàgbé, ta sì ni a fi lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ fún wọn?

20 Àwọn aya pẹ̀lú ní láti ṣàkíyèsí Jesu, ẹni tí kò gbàgbé láé rí pé, “orí Kristi ni Ọlọrun.” Nígbà gbogbo ni ó ń juwọ́ sílẹ̀ fún Bàbá rẹ̀ ọ̀run. Bákan náà, àwọn aya kò ní láti gbàgbé pé, “orí obìnrin ni ọkùnrin,” àní, pé ọkọ wọn ni orí wọn. (1 Korinti 11:3; Efesu 5:23) Aposteli Peteru rọ àwọn Kristian aya láti ṣàgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ “awọn obìnrin mímọ́” ti ìgbàanì, pàápàá ní pàtàkì, ti Sara, tí ó “máa ń ṣègbọràn sí Abrahamu, ní pípè é ní ‘oluwa.’”—1 Peteru 3:5‚ 6.

21. Èé ṣe tí ìgbéyàwó Abrahamu àti Sara fi ṣàṣeyọrí ṣùgbọ́n tí ti Lọti àti ìyàwó rẹ̀ sì kùnà?

21 Ẹ̀rí hàn gbangba pé Sara fi ilé tí ó tura sílẹ̀ ní ìlú ńlá aláásìkí kan láti lọ gbé nínú àgọ́ ní ilẹ̀ àjèjì. Èé ṣe? Ó ha jẹ́ nítorí pé ó fara mọ́ irú ìgbésí ayé yẹn bí? Kò dájú. Ó ha jẹ́ nítorí pé ọkọ rẹ̀ ní kí ó ká lọ bí? Láìṣe àníàní, èyí jẹ́ kókó abájọ kan, níwọ̀n bí Sara ti nífẹ̀ẹ́, tí ó sì bọ̀wọ̀ fún Abrahamu nítorí àwọn ànímọ́ rẹ̀ ti jíjẹ́ olùṣèfẹ́ Ọlọrun. (Genesisi 18:12) Ṣùgbọ́n ìdí pàtàkì tí ó fi bá ọkọ rẹ̀ lọ ni nítorí ìfẹ́ rẹ̀ fún Jehofa àti ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọrun. (Genesisi 12:1) Inú rẹ̀ dùn sí ṣíṣe ìgbọràn sí Ọlọrun. Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, ìyàwó Loti lọ́ tìkọ̀ láti ṣe ìfẹ́ inú Ọlọrun, ó sì tipa báyìí wẹ̀yìn ní fífọkàn ṣìkẹ́ àwọn ohun tí ó fi sílẹ̀ sẹ́yìn ní ìlú rẹ̀, Sodomu. (Genesisi 19:15‚ 25‚ 26; Luku 17:32) Ẹ wo òpin oníbànújẹ́ tí ó dé bá ìgbéyàwó náà—kìkì nítorí pé kò ṣègbọràn sí Ọlọrun!

22. (a) Àyẹ̀wò ara ẹni wo ni àwọn mẹ́ḿbà ìdílé yóò fi ọgbọ́n ṣe? (b) Kí ni a óò gbé yẹ̀wò nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ wa tí yóò tẹ̀ lé e?

22 Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ọkọ tàbí aya, ó ṣe pàtàkì láti bi ara rẹ léèrè pé, ‘Ọlọrun ha wà ní ipò kìíní nínú ìdílé wa bí? Mo ha ń sapá ní tòótọ́ láti ṣe ipa iṣẹ́ tí Ọlọrun fi fún mi nínú ìdílé bí? Mo ha ń ṣe ojúlówó ìsapá láti nífẹ̀ẹ́ alábàágbéyàwó mi àti láti ràn án lọ́wọ́ láti jèrè tàbí láti máa bá àjọṣepọ̀ tí ó dára pẹ̀lú Jehofa lọ bí?’ Àwọn ọmọ tún wà nínú ọ̀pọ̀ ìdílé. A óò wá ṣàgbéyẹ̀wò ipa iṣẹ́ àwọn òbí àti àìgbọdọ̀máṣe tí ó wà fún àwọn àti àwọn ọmọ wọn láti fi Ọlọrun sí ipò kìíní.

Ìwọ Ha Rántí Bí?

◻ Kí ni ó lè jẹ́ àbájáde àwọn ẹ̀kọ́ Jesu fún ọ̀pọ̀ ìdílé?

◻ Èrè wo ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Kristian adúróṣinṣin ti rí gbà?

◻ Kí ni yóò ran àwọn alábàágbéyàwó lọ́wọ́ láti yẹra fún ìwà pálapàla àti ìkọ̀sílẹ̀?

◻ Kí ni àwọn ọkọ lè kọ́ láti inú àpẹẹrẹ Jesu?

◻ Báwo ni àwọn aya ṣe lè dákún ayọ̀ ìdílé?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Báwo ni Sara ṣe dákún àṣeyọrí ìgbéyàwó rẹ̀?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́