Ẹ̀yin Aya, Ẹ Ní Ọ̀wọ̀ Jíjinlẹ̀ Fún Ọkọ Yín
“Kí [ẹ̀yin] aya wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ [yín].”—ÉFÉSÙ 5:22.
1. Kí nìdí tí kì í fi í rọrùn nígbà míì fún aya láti bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀?
NÍ Ọ̀PỌ̀ ibi, lọ́jọ́ tí ọkùnrin àtobìnrin kan bá ń ṣe ìgbéyàwó, ìyàwó á jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun á máa bọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ òun. Ṣùgbọ́n, ọ̀nà tí ọ̀pọ̀ ọkọ gbà ń bá aya wọn lò máa ń pinnu bóyá á rọrùn fún aya láti mú ẹ̀jẹ́ yìí ṣẹ tàbí kò ní rọrùn. Síbẹ̀ ohun alárinrin ni ìgbéyàwó nígbà tí Ọlọ́run dá a sílẹ̀. Ńṣe ni Ọlọ́run mú egungun ìhà kan láti ara Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́, ó sì fi mọ obìnrin. Ádámù sì sọ pé: “Èyí ni egungun nínú àwọn egungun mi àti ẹran ara nínú ẹran ara mi.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:19-23.
2. Láyé ìsinsìnyí, kí ló ń ṣẹlẹ̀ lágbo àwọn obìnrin, ìyípadà wo ló sì ti bá ọwọ́ tí wọ́n fi mú ìgbéyàwó?
2 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbéyàwó ní ìbẹ̀rẹ̀ alárinrin, síbẹ̀ láàárín ọdún 1960 sí 1964, àwọn obìnrin kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà dá ẹgbẹ́ kan sílẹ̀ nítorí pé wọ́n ò fẹ́ kí ọkùnrin máa pàṣẹ lé wọn lórí. Láyé ìgbà yẹn, tá a bá fi máa rí ọ̀ọ́dúnrún [300] ọkùnrin tó faya àtọmọ ẹ̀ sílẹ̀, a ò ní rí ju obìnrin kan ṣoṣo tó fọkọ àtọmọ ẹ̀ sílẹ̀. Àmọ́ nígbà tó ń sún mọ́ ọdún 1969, tá a bá fi máa rí ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin tó fi ìdílé rẹ̀ sílẹ̀, a ó ti rí obìnrin mẹ́ta tó ti ṣe bẹ́ẹ̀. Láyé ìsinsìnyí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé báwọn ọkùnrin ṣe ń mutí, tí wọ́n ń mu sìgá, tí wọ́n ń ṣèṣekúṣe, tí wọ́n sì ń ṣépè làwọn obìnrin náà ń ṣe é. Ṣé gbogbo nǹkan táwọn obìnrin ń ṣe yìí ti wá mú kí wọ́n láyọ̀ sí i? Rárá o. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, nǹkan bí ìdajì àwọn tó ń ṣègbéyàwó ló ń padà jáwèé fúnra wọn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Ǹjẹ́ ipá táwọn obìnrin kan ń sà láti mú kí ipò tí wọ́n wà nínú ìgbéyàwó gbé pẹ́ẹ́lí sí i ń yọrí sí rere, tàbí kàkà kéwé àgbọn dẹ̀ ńṣe ló ń le sí i?—2 Tímótì 3:1-5.
3. Kí ló ń fa ìṣòro bá ìgbéyàwó gan-an?
3 Kí ló ń fa ìṣòro yẹn gan-an? Dé àyè kan, ohun tó ń fa ìṣòro yẹn ni nǹkan tí áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ nì, ìyẹn “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì” ti ń ṣe látìgbà tó ti tan Éfà jẹ. (Ìṣípayá 12:9; 1 Tímótì 2:13, 14) Sátánì ń mú kí ọmọ aráyé máa wo àwọn ohun tí Ọlọ́run fi kọ́ni gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò wúlò. Bí àpẹẹrẹ, Èṣù mú kí ìgbéyàwó dà bí ohun tó ti le jù àtohun tó ń ká èèyàn lọ́wọ́ kò. Ńṣe làwọn ọ̀rọ̀ tí Sátánì, alákòóso ayé yìí, ń fi ìwé ìròyìn ayé, ètò orí rédíò àti ti tẹlifíṣọ̀n gbé lárugẹ ń mú kí ìtọ́ni Ọlọ́run dà bí ohun tí kò tọ́ tí kò sì bágbà mu. (2 Kọ́ríńtì 4:3, 4) Àmọ́, tá a bá fi òótọ́ ọkàn ṣàyẹ̀wò ohun tí Ọlọ́run sọ nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa ipò tó fàwọn obìnrin sí nínú ìgbéyàwó, a óò rí i pé ohun tó sọ bọ́gbọ́n mu, ó sì dára.
Ìkìlọ̀ Fáwọn Tó Ti Ṣègbéyàwó
4, 5. (a) Kí nìdí tó fi yẹ kí obìnrin kan tó ń ronú àtilọ́kọ kíyè sára? (b) Kí ló yẹ kí obìnrin kan ṣe kó tó gbà láti fẹ́ ọkùnrin kan?
4 Bíbélì ṣe ìkìlọ̀ kan fáwọn lọ́kọláya. Ó sọ pé nínú ayé tí Èṣù ń ṣàkóso yìí, àwọn tọkọtaya yóò ní “ìpọ́njú,” títí kan àwọn tí àárín wọn gún régé pàápàá. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi ṣèkìlọ̀ fáwọn tó ti ṣègbéyàwó bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ló dá ìgbéyàwó sílẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn tí Ọlọ́run mí sí láti kọ Bíbélì sọ nípa obìnrin tí ọkọ rẹ̀ kú tó sì lómìnira láti fẹ́ ẹlòmíràn pé: “Ó láyọ̀ jù bí ó bá dúró bí ó ti wà.” Jésù pàápàá sọ pé á dára kí àwọn “tí ó bá lè wá àyè fún un,” ìyẹn àwọn tó bá lè wà láìlọ́kọ tàbí láìláya, ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ o, tí ẹnikẹ́ni bá lóun fẹ́ ṣègbéyàwó, kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ kìkì “nínú Olúwa,” ìyẹn ni pé kó fẹ́ olùjọsìn Ọlọ́run tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ tó sì ti ṣèrìbọmi.—1 Kọ́ríńtì 7:28, 36-40; Mátíù 19:10-12.
5 Ìdí pàtàkì kan tóbìnrin tó fẹ́ lọ́kọ fi ní láti ronú dáadáa nípa ẹni tó fẹ́ fẹ́ ni ìkìlọ̀ Bíbélì tó sọ pé: “Òfin de obìnrin tí a gbé níyàwó mọ́ ọkọ rẹ̀.” Àyàfi bí ọkọ obìnrin náà bá kú tàbí tó ṣe panṣágà tí wọ́n sì kọra wọn nìkan ló tó lè “di òmìnira kúrò nínú òfin [ọkọ] rẹ̀.” (Róòmù 7:2, 3) Téèyàn bá rí ẹnì kan fúngbà àkọ́kọ́ tí ìfẹ́ ẹni náà sì kó sí i lọ́kàn, inú rẹ̀ lè máa dùn, àmọ́ kì í ṣe ìfẹ́ yẹn nìkan ló máa mú kí ìgbéyàwó wọn yọrí sí rere. Nítorí náà, ó yẹ kí obìnrin tó bá fẹ́ lọ́kọ bi ara rẹ̀ pé: ‘Ǹjẹ́ mo ṣe tán láti wà lábẹ́ òfin ọkùnrin yìí?’ Kó tó gbà láti fẹ́ ọkùnrin náà ló ti yẹ kó bi ara rẹ̀ ní ìbéèrè yẹn o, kì í ṣe lẹ́yìn tí wọ́n ti fẹ́ra wọn.
6. Ìpinnu wo ni ọ̀pọ̀ obìnrin lè ṣe fúnra wọn láyé ìsinsìnyí, kí sì nìdí tí ìpinnu yẹn fi ṣe pàtàkì?
6 Ní ọ̀pọ̀ ibi lónìí, tí ọkùnrin bá bá obìnrin kan sọ̀rọ̀ pé òun fẹ́ fẹ́ ẹ, obìnrin náà lómìnira láti gbà fún ọkùnrin náà, ó sì lè sọ pé òun ò gbà. Síbẹ̀, ó lè má rọrùn fáwọn obìnrin láti ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu nítorí pé ìfẹ́ láti ní olólùfẹ́ máa ń lágbára gan-an lọ́kàn wọn. Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Tó bá wà lọ́kàn èèyàn láti ṣe nǹkan kan, bóyá èèyàn fẹ́ ṣègbéyàwó ni o tàbí ó fẹ́ fi okùn pọ́nkè, ọkàn èèyàn lè má lọ sára àwọn ìṣòro téèyàn lè bá pàdé níbẹ̀, àwọn ohun téèyàn sì fẹ́ láti gbọ́ nìkan lá máa fọkàn sí.” Bí ẹnì kan tó fẹ́ pọ́nkè ò bá fara balẹ̀ rò ó dáadáa, ó lè fẹ̀mí ara ẹ̀ ṣòfò, bákan náà, tẹ́nì kan ò bá fọgbọ́n yan ẹni tó fẹ́ fẹ́, ó lè kòṣòro.
7. Ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n wo ló wà fáwọn tó ń wá ọkọ tàbí àwọn tó ń wá ìyàwó?
7 Ó yẹ kí obìnrin kan ronú dáadáa nípa ohun tó túmọ̀ sí láti wà lábẹ́ òfin ọkùnrin tó bá bá a sọ̀rọ̀ pé òun fẹ́ fẹ́ ẹ. Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ọ̀dọ́bìnrin ọmọ ilẹ̀ Íńdíà kan fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ sọ pé: “Àwọn òbí wa jù wá lọ lọ́jọ́ orí, wọ́n gbọ́n jù wá, èèyàn ò sì lè tètè tàn wọ́n jẹ bí àwa wọ̀nyí. . . . Èmi lè tètè ṣe àṣìṣe.” Èèyàn ò gbọ́dọ̀ fojú kéré ìrànlọ́wọ́ táwọn òbí àtàwọn míì lè ṣe. Agbaninímọ̀ràn kan tó jẹ́ ọlọgbọ́n máa ń gba àwọn ọ̀dọ́ nímọ̀ràn pé kí wọ́n rí i pé wọ́n mọ òbí ẹni tí wọ́n fẹ́ fẹ́, kí wọ́n sì fara balẹ̀ wo bí ẹni náà ṣe ń ṣe sí àwọn òbí ẹ̀ àtàwọn ará ilé ẹ̀ yòókù.
Bí Jésù Ṣe Fi Ẹ̀mí Ìtẹríba Hàn
8, 9. (a) Ọwọ́ wo ni Jésù fi mú ọ̀rọ̀ ìtẹríba fún Ọlọ́run? (b) Èrè wo làwọn obìnrin máa jẹ tí wọ́n bá lẹ́mìí ìtẹríba?
8 Òótọ́ ni pé ó lè má rọrùn láti tẹrí ba, síbẹ̀ ó yẹ káwọn obìnrin wo ìtẹríba gẹ́gẹ́ bí ohun tó buyì kúnni, bí Jésù ti ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtẹríba Jésù fún Ọlọ́run gba pé kó jìyà títí dójú ikú lórí òpó igi oró, síbẹ̀ bó ṣe tẹrí ba fún Ọlọ́run jẹ́ kó láyọ̀. (Lúùkù 22:41-44; Hébérù 5:7, 8; 12:3) Àwọn obìnrin lè kọ́ ẹ̀kọ́ lára Jésù, nítorí Bíbélì sọ pé: “Orí obìnrin ni ọkùnrin; ẹ̀wẹ̀, orí Kristi ni Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 11:3) Àmọ́, kì í ṣe ìgbà táwọn obìnrin bá lọ́kọ nìkan ni wọ́n wà lábẹ́ àṣẹ ọkùnrin o.
9 Bíbélì sọ pé káwọn obìnrin, àtèyí tó ti lọ́kọ àtèyí tí kò ní, máa tẹrí ba fáwọn ọkùnrin tó tóótun nípa tẹ̀mí tí wọ́n ń ṣe àbójútó nínú ìjọ Ọlọ́run. (1 Tímótì 2:12, 13; Hébérù 13:17) Táwọn obìnrin bá ń tẹ̀ lé ìtọ́ni Ọlọ́run yìí, ńṣe ni wọ́n ń fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fáwọn áńgẹ́lì tó wà nínú ètò Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 11:8-10) Kò tán síbẹ̀ o, àwọn àgbà obìnrin ń tipasẹ̀ àpẹẹrẹ rere wọn àti ìmọ̀ràn tó wúlò kọ́ àwọn ọ̀dọ́bìnrin láti ‘fi ara wọn sábẹ́ àwọn ọkọ wọn.’—Títù 2:3-5.
10. Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ tó dá dọ̀rọ̀ níní ìtẹríba?
10 Jésù mọ bí ìtẹríba tó bójú mu ṣe ṣe pàtàkì tó. Lákòókò kan, Jésù sọ fún àpọ́sítélì Pétérù pé kó san owó orí òun àti tiẹ̀ fáwọn aláṣẹ, àní ó tiẹ̀ tún pèsè owó tí Pétérù máa fi san án. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìyẹn, Pétérù kọ̀wé pé: “Nítorí Olúwa, ẹ fi ara yín sábẹ́ gbogbo ohun tí ẹ̀dá ènìyàn ṣẹ̀dá.” (1 Pétérù 2:13; Mátíù 17:24-27) Bíbélì sọ bí Jésù ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ tó tayọ tó bá dọ̀rọ̀ níní ẹ̀mí ìtẹríba, ó ní: “Ó sọ ara rẹ̀ di òfìfo, ó sì gbé ìrísí ẹrú wọ̀, ó sì wá wà ní ìrí ènìyàn. Ju èyíinì lọ, nígbà tí ó rí ara rẹ̀ ní àwọ̀ ènìyàn, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di onígbọràn títí dé ikú.”—Fílípì 2:5-8.
11. Kí nìdí tí Pétérù fi gba àwọn aya níyànjú pé kí wọ́n máa tẹrí ba fún ọkọ wọn tí kì í ṣe onígbàgbọ́ pàápàá?
11 Nígbà tí Pétérù ń gba àwọn Kristẹni nímọ̀ràn pé kí wọ́n máa tẹrí ba fáwọn aláṣẹ ayé yìí, kódà fáwọn tí wọ́n jẹ́ òǹrorò lára wọn tí wọn kì í sì í ṣe ohun tó tọ́ pàápàá, ó ní: “Ní ti tòótọ́, ipa ọ̀nà yìí ni a pè yín sí, nítorí Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (1 Pétérù 2:21) Lẹ́yìn tí Pétérù ti ṣàlàyé ìyà tí Jésù jẹ àti bó ṣe fi ẹ̀mí ìtẹríba fara da ìyà ọ̀hún, ó gba àwọn aya tí ọkọ wọn kì í ṣe onígbàgbọ́ níyànjú pé: “Lọ́nà kan náà, ẹ̀yin aya, ẹ wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ tiyín, kí ó lè jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni kò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà àwọn aya wọn, nítorí fífi tí wọ́n fi ojú rí ìwà mímọ́ yín pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.”—1 Pétérù 3:1, 2.
12. Èrè wo ló wà nínú níní tí Jésù lẹ́mìí ìtẹríba?
12 Àwọn kan lè máa fojú ọ̀dẹ̀ wo obìnrin tó bá ń tẹrí bá fún ọkọ rẹ̀ tó sì jẹ́ pé ńṣe ni ọkọ ọ̀hún ń fojú ẹ̀ gbolẹ̀, tó tún máa ń sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí i. Àmọ́ Jésù ò wo ọ̀rọ̀ náà bẹ́ẹ̀. Pétérù sọ pé: “Nígbà tí a ń kẹ́gàn rẹ̀, kò bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́gàn padà. Nígbà tí ó ń jìyà, kò bẹ̀rẹ̀ sí halẹ̀ mọ́ni.” (1 Pétérù 2:23) Ó ṣe tán, àwọn kan tó rí ìyà tí Jésù jẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù dé ìwọ̀n àyè kan. Àpẹẹrẹ kan ni ti ọlọ́ṣà kan tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù, òmíràn ni ti ọ̀gá sójà tó ń wo bí wọ́n ṣe kan Jésù mọ́gi. (Mátíù 27:38-44, 54; Máàkù 15:39; Lúùkù 23:39-43) Bákan náà, Pétérù fi hàn pé àwọn ọkọ kan tí kì í ṣe onígbàgbọ́, tí wọ́n tiẹ̀ tún jẹ́ òǹrorò pàápàá, yóò di Kristẹni lẹ́yìn tí wọ́n bá rí i pé ìyàwó àwọn lẹ́mìí ìtẹríba. Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ tó fi èyí hàn ló wà lónìí.
Bí Aya Ṣe Lè Jèrè Ọkọ Rẹ̀
13, 14. Báwo ni títẹríba táwọn aya kan tẹrí ba fún ọkọ wọn tí kì í ṣe onígbàgbọ́ ṣe ṣàǹfààní?
13 Àwọn aya kan tí wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ ti jèrè ọkọ wọn nítorí ìwà bíi ti Kristi tí wọ́n ń hù. Nígbà àpéjọ àgbègbè kan táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ọkùnrin kan sọ̀rọ̀ nípa ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ Kristẹni, ó ní: “Mo fojú ìyàwó mi rí màbo. Síbẹ̀, ó máa ń fi ọ̀wọ̀ mi wọ̀ mí. Kò wọ́mi ńlẹ̀ rí. Kò sì sọ pé àfi dandan kí n gba ẹ̀sìn òun. Ó máa ń tọ́jú mi. Nígbà kan tó fẹ́ lọ sípàdé àyíká, ó rí i dájú pé òun se oúnjẹ mi sílẹ̀, ó sì rí i pé òun parí iṣẹ́ ilé kó tó lọ. Gbogbo ìwà tó ń hù wọ̀nyí wá bẹ̀rẹ̀ sí í mú kó wù mí láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Èmi rèé lónìí, mo ti di Ẹlẹ́rìí!” Bẹ́ẹ̀ ni, ìwà arábìnrin yìí mú kó jèrè ọkọ rẹ̀ “láìsọ ọ̀rọ̀ kan.”
14 Gẹ́gẹ́ bí Pétérù ṣe sọ, ohun tí aya sọ kì í sábà mú àbájáde rere wá tó ìwà rẹ̀. Ìrírí ìyàwó ilé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó sì pinnu láti máa lọ sípàdé ìjọ fìdí òótọ́ ọ̀rọ̀ yẹn múlẹ̀. Ọkọ rẹ̀ jágbe mọ́ ọn pé: “Agnes, tó o bá jáde lẹ́nu ọ̀nà yẹn pẹ́nrẹ́n, má padà wálé yìí mọ́ o!” Lóòótọ́, obìnrin náà ò gba ẹnu ọ̀nà tí ọkọ rẹ̀ tọ́ka sí jáde, ẹnu ọ̀nà míì ló gbà jáde. Nígbà tó tún di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ míì tó fẹ́ lọ sípàdé, ọkọ rẹ̀ halẹ̀ mọ́ ọn, ó ní: “Mọ̀ pé tó o bá ti lọ, o ò ní padà wá bá mi nínú ilé yìí o.” Nígbà tó fi máa padà dé, kò bá ọkọ rẹ̀ nílé lóòótọ́. Ọjọ́ mẹ́tà gbáko ni ọkọ rẹ̀ lò níta. Nígbà tó wá padà wálé, ohùn pẹ̀lẹ́ ni ìyàwó rẹ̀ fi bí i pé: “Ṣé kí n bá yín gbé oúnjẹ yín wá?” Agnes ò yẹsẹ̀ nínú ìjọsìn rẹ̀ sí Jèhófà. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọkọ rẹ̀ gbà pé kí wọ́n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run, nígbà tó sì ṣe, ó di alàgbà tó ní ọ̀pọ̀ ẹrù iṣẹ́.
15. Irú “ọ̀ṣọ́” wo ni Pétérù sọ pé ó yẹ káwọn aya tó jẹ́ Kristẹni ní?
15 Àwọn tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ mẹ́nu kan àpẹẹrẹ wọn yìí ní ohun kan tí àpọ́sítélì Pétérù sọ pé ó yẹ káwọn aya ní, ìyẹn ni “ọ̀ṣọ́.” Àmọ́, ọ̀ṣọ́ tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí kì í ṣe ti “irun dídì” lọ́nà àrà tàbí “ti wíwọ àwọn ẹ̀wù àwọ̀lékè” o. Kàkà bẹ́ẹ̀, Pétérù sọ pé: “Kí [ọ̀ṣọ́ yín] jẹ́ ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ tí kò lè díbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù, èyí tí ó níye lórí gidigidi lójú Ọlọ́run.” Tí aya kan tó jẹ́ Kristẹni bá nírú ẹ̀mí yìí, á hàn nínú ìsọ̀rọ̀ àti ìwà rẹ̀, kò ní máa jájú mọ́ ọkọ rẹ̀, kò sì ní jẹ́ ẹni tó ṣòroó tẹ́ lọ́rùn. Èyí ló máa fi hàn pé ó bọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.—1 Pétérù 3:3, 4.
Àwọn Tí Aya Lè Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Wọn
16. Ọ̀nà wo ni Sárà gbà jẹ́ àpẹẹrẹ tó yẹ káwọn aya tó jẹ́ Kristẹni máa tẹ̀ lé?
16 Pétérù kọ̀wé pé: “Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn obìnrin mímọ́ tí wọ́n ní ìrètí nínú Ọlọ́run máa ń ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, ní fífi ara wọn sábẹ́ àwọn ọkọ tiwọn.” (1 Pétérù 3:5) Irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ rí i pé táwọn bá ń múnú Jèhófà dùn nípa títẹ̀lé àwọn ìtọ́ni rẹ̀, ìdílé àwọn yóò láyọ̀ àwọn á sì ní ìyè àìnípẹ̀kun. Pétérù mẹ́nu kan aya Ábúráhámù, ìyẹn Sárà arẹwà obìnrin, ó sọ pé ó “máa ń ṣègbọràn sí Ábúráhámù, ní pípè é ní ‘olúwa.’” Sárà dúró gbágbáágbá ti ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run, tí Ọlọ́run rán lọ sọ́nà jíjìn. Sárà tiẹ̀ gbà láti kúrò níbi tí ìgbésí ayé ti dẹrùn, ó tún fẹ̀mí ara rẹ̀ wewu pàápàá. (Jẹ́nẹ́sísì 12:1, 10-13) Pétérù sọ pé Sárà yẹ lẹ́ni táwọn aya ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, ó ní: “Ẹ sì ti di ọmọ rẹ̀, kìkì bí ẹ bá ń bá a nìṣó ní ṣíṣe rere, tí ẹ kò sì bẹ̀rù okùnfà èyíkéyìí fún ìpayà.”—1 Pétérù 3:6.
17. Kí nìdí tó fi ṣeé ṣe kí Pétérù ní Ábígẹ́lì lọ́kàn pé ó jẹ́ àpẹẹrẹ fáwọn aya tó jẹ́ Kristẹni?
17 Obìnrin mìíràn tó nígboyà tó sì ní ìrètí nínú Ọlọ́run ni Ábígẹ́lì, ó sì ṣeé ṣe kó wà lára àwọn tí Pétérù ní lọ́kàn nínú ọ̀rọ̀ tó sọ. Ábígẹ́lì jẹ́ ẹnì kan tó “ní ọgbọ́n inú dáadáa,” àmọ́ ọkọ rẹ̀ Nábálì jẹ́ ẹnì kan tó “le koko, ó sì burú ní àwọn ìṣe rẹ̀.” Nígbà kan tí Nábálì kọ̀ jálẹ̀ tó lóun ò ní ṣèrànwọ́ fún Dáfídì àtàwọn èèyàn rẹ̀, Dáfídì àtàwọn èèyàn ẹ̀ gbéra láti lọ pa Nábálì àti ìdílé rẹ̀ run. Àmọ́ Ábígẹ́lì gbé ìgbésẹ̀ lọ́gán láti gba ìdílé rẹ̀ là. Ó di onírúurú oúnjẹ sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ láti lọ gbé e fún Dáfídì. Bó ṣe ń lọ, ó pàdé Dáfídì àtàwọn èèyàn ẹ̀ tó ti dìhámọ́ra ogun lọ́nà. Bó sì ṣe rí Dáfídì báyìí, ó sọ̀kalẹ̀ látorí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó wólẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ ẹ́ pé kó má ṣe jẹ́ kí ìbínú mú un ṣìwà hù. Ohun tó ṣe yìí wú Dáfídì lórí gidigidi. Ó ní: “Ìbùkún ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó rán ọ lónìí yìí láti pàdé mi! Ìbùkún sì ni fún ìlóyenínú rẹ.”—1 Sámúẹ́lì 25:2-33.
18. Tí ọkùnrin kan bá ń fa ojú ìyàwó ilé kan mọ́ra, àpẹẹrẹ ta ni obìnrin náà lè ronú lé lórí, kí sì nìdí tó fi yẹ kó ṣe bẹ́ẹ̀?
18 Ẹlòmíì táwọn aya lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ ni ọ̀dọ́bìnrin kan tí wọ́n ń pè ní Ṣúlámáítì, tó dúró ti àfẹ́sọ́nà rẹ̀ tí kì í ṣe èèyàn ńlá, tó jẹ́ pé olùṣọ́ àgùntàn ni. Ìfẹ́ tí ọ̀dọ́bìnrin yìí ní sí àfẹ́sọ́nà rẹ̀ ò yìnrìn láìka gbogbo bí ọba ọlọ́rọ̀ kan ṣe ń gbìyànjú láti fajú ẹ̀ mọ́ra sí. Ìfẹ́ tó ní sí ọ̀dọ́ olùṣọ́ àgùntàn yìí mú kó sọ bí nǹkan ṣe rí lọ́kàn rẹ̀ fún olùṣọ́ àgùntàn náà pé: “Gbé mi lé ọkàn-àyà rẹ gẹ́gẹ́ bí èdìdì, gẹ́gẹ́ bí èdìdì lé apá rẹ; nítorí pé ìfẹ́ lágbára bí ikú . . . Omi púpọ̀ pàápàá kò lè paná ìfẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn odò alára kò lè gbé e lọ.” (Orin Sólómọ́nì 8:6, 7) A rọ gbogbo àwọn obìnrin tó ti lọ́kọ pé kí wọ́n pinnu láti má ṣe fi ọkọ wọn sílẹ̀ láé kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn.
Àmọ̀ràn Míì Tí Ọlọ́run Fún Àwọn Aya
19, 20. (a) Kí nìdí tó fi yẹ kí aya máa tẹrí bá fún ọkọ rẹ̀? (b) Àwọn wo ló jẹ́ àpẹẹrẹ rere fáwọn aya?
19 Ní paríparí rẹ̀, ẹ jẹ́ ká wo àwọn ọ̀rọ̀ tó wà níbi tá a ti mú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a gbé àpilẹ̀kọ yìí kà, ìyẹn ẹsẹ tó sọ pé: “Kí [ẹ̀yìn] aya wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ [yín].” (Éfésù 5:22) Kí nìdí tí irú ìtẹríba bẹ́ẹ̀ fi pọn dandan? Ẹsẹ tó tẹ̀ lé e sọ pé: “Nítorí pé ọkọ ni orí aya rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti jẹ́ orí ìjọ.” Nítorí náà, Bíbélì gba àwọn aya nímọ̀ràn, ó ní: “Gẹ́gẹ́ bí ìjọ ti wà ní ìtẹríba fún Kristi, bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn aya pẹ̀lú wà fún àwọn ọkọ wọn nínú ohun gbogbo.”—Éfésù 5:23, 24, 33.
20 Ohun kan tó máa ran àwọn aya lọ́wọ́ láti pa òfin yẹn mọ́ ni pé kí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa àpẹẹrẹ àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ ìjọ Kristi, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Jọ̀wọ́ ka 2 Kọ́ríńtì 11:23-28 kó o lè mọ ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ ọkàn lára àwọn tó wà nínú ìjọ náà fojú winá rẹ̀ láti lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jésù Kristi tí í ṣe Orí rẹ̀. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, àwọn aya àtàwọn yòókù nínú ìjọ gbọ́dọ̀ wà ní ìtẹríba fún Jésù. Ọ̀nà táwọn aya sì lè gbà ṣe èyí ni pé kí wọ́n máa tẹrí ba fáwọn ọkọ wọn.
21. Kí ni nǹkan tó lè túbọ̀ mú káwọn aya fẹ́ láti máa tẹrí bá fún ọkọ wọn?
21 Láyé ìsinsìnyí, ọ̀pọ̀ aya lè má fẹ́ láti máa tẹrí bá fún ọkọ wọn, àmọ́ ńṣe làwọn obìnrin tó bá gbọ́n yóò máa wo èrè tó wà nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tí obìnrin kan tí ọkọ rẹ̀ kì í ṣe onígbàgbọ́ bá ń tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀ nínú ohun gbogbo, àyàfi nínú ohun tó ta ko òfin tàbí ìlànà Ọlọ́run nìkan, irú obìnrin bẹ́ẹ̀ lè tipa bẹ́ẹ̀ ‘gba ọkọ rẹ̀ là.’ Èrè ńláǹlà sì nìyẹn. (1 Kọ́ríńtì 7:13, 16) Yàtọ̀ síyẹn, ọkàn rẹ̀ á balẹ̀ nítorí ó mọ̀ pé inú Jèhófà Ọlọ́run dùn sí nǹkan tóun ń ṣe, ó sì tún mọ̀ pé Ọlọ́run máa bù kún òun lọ́pọ̀ yanturu fún bóun ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí nìdí tó fi lè má rọrùn fún aya kan láti bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀?
• Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ pé kí obìnrin kan gbà láti fẹ́ ọkùnrin tó bá a sọ̀rọ̀ fi jẹ́ ọ̀rọ̀ tó gba ìrònújinlẹ̀?
• Báwo ni Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fáwọn aya, èrè wo ló sì lè tibẹ̀ jáde tí wọ́n bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ bóyá kí obìnrin kan gbà láti fẹ́ ẹni tó bá a sọ̀rọ̀ tàbí kó má gbà fi jẹ́ ọ̀rọ̀ tó gba ìrònújinlẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ẹ̀kọ́ wo làwọn aya lè rí kọ́ lára àwọn obìnrin tí Bíbélì mẹ́nu kàn, irú bí Ábígẹ́lì?