Ki Ni Itẹriba Ninu Igbeyawo Tumọsi?
NIGBA ti obinrin Kristẹni kan ba ṣegbeyawo, ohun nilati ṣe ọpọlọpọ atunṣe. Boya eyi ti ó ga julọ ninu iwọnyi lè kan ominira rẹ̀. Gẹgẹ bi agbalagba àpọ́n kan, oun ti lè wà lominira lati ṣe pupọ ninu awọn ipinnu rẹ̀ láìkàn si ẹnikankan. Ṣugbọn nisinsinyi ti oun ti ni ọkọ kan, oun ni ẹrù-iṣẹ́ naa lati kàn sii ki ó sì beere lọwọ rẹ̀ fun àyè lati ṣe ọpọlọpọ ninu awọn nǹkan ti oun ti maa npinnu fun araarẹ. Eeṣe ti eyi fi ri bẹẹ?
Nitori pe nigba ti Ẹlẹdaa eniyan fi obinrin akọkọ fun ọkunrin akọkọ ninu igbeyawo, Oun yan ọkunrin naa lati jẹ́ olori aya rẹ̀ ati awọn ọmọ wọn ọjọ iwaju. Eyi wulẹ bọgbọnmu. Ninu awujọ eniyan eyikeyii ti a ṣeto, ẹnikan nilati mu ipo iwaju ki o sì ṣe awọn ipinnu ti o kẹhin. Ninu ọran ti igbeyawo, Ẹlẹdaa paṣẹ pe “ọkọ nii ṣe ori aya.”—Efesu 5:23.
Ni itilẹhin fun eyi, itọni atọrunwa naa wi pe: “Ẹyin aya, ẹ maa tẹriba fun awọn ọkọ yin.” (Efesu 5:22) Bi iṣeto yii ṣe kan aya kan sinmi lori awọn ohun meji: Ekinni, bawo ni oun ti nfẹ tó lati tẹriba fun iṣeto naa? ati ekeji, bawo ni ọkọ rẹ̀ yoo ṣe lo aṣẹ rẹ̀? Ni otitọ, nigba ti awọn alajọṣegbeyawo mejeeji ba bojuwo iṣeto naa lọna titọ, wọn ri i pe ó jẹ́ ibukun kan fun aya, ọkọ, ati awọn ọmọ wọn.
Kii Ṣe Òǹrorò Kan
Bawo ni ọkọ kan ṣe lè lo aṣẹ rẹ̀? Nipa titẹle apẹẹrẹ rere ti Ọmọkunrin Ọlọrun. Bibeli wi pe: “Nitori pe ọkọ nii ṣe ori aya, gẹgẹ bi Kristi tii ṣe ori ijọ eniyan rẹ̀: oun sì ni Olugbala ara. Ẹyin ọkọ, ẹ fẹran awọn aya yin, gẹgẹ bi Kristi sì ti fẹran ijọ, ti ó sì fi araarẹ fun un.” (Efesu 5:23, 25) Ilo ipo ori niha ọdọ Kristi jẹ́ ibukun fun ijọ. Oun kii ṣe òǹrorò kan. Oun kò jẹ ki awọn ọmọlẹhin rẹ nimọlara ikalọwọko tabi itẹloriba. Kaka bẹẹ, oun jere ọwọ gbogbo wọn nipa ibaṣepọ rẹ̀ onifẹẹ ati oníyọ̀ọ́nú si wọn. Iru apẹẹrẹ rere wo ni eyi jẹ́ fun awọn ọkọ lati tẹle ninu ibaṣepọ wọn pẹlu awọn aya wọn!
Sibẹsibẹ, awọn ọkọ kan wà ti wọn kò tẹle apẹẹrẹ rere yii. Wọn nlo ipo ori ti Ọlọrun fifun wọn ni ọna imọtara-ẹni-nikan, dipo fun ire awọn aya wọn. Wọn njẹgaba lori awọn aya wọn ni ọna òǹrorò kan, wọn nbeere fun itẹriba delẹdelẹ ti wọn kò si nfi bẹẹ gbà wọn laaye lati ṣe awọn ipinnu kankan fun araawọn. Lọna ti ó yeni, aya iru awọn ọkọ bẹẹ saba maa ngbe igbesi-aye alailayọ. Iru ọkọ bẹẹ sì maa njiya niti pe oun kuna lati jere ọ̀wọ̀ onifẹẹ ti aya rẹ̀.
Loootọ, Ọlọrun beere lọwọ aya kan lati bọwọ fun ipo tí ọkọ rẹ̀ dimu gẹgẹ bi olori idile naa. Ṣugbọn bi ọkọ naa bá fẹ lati gbadun ọ̀wọ̀ atọkanwa rẹ̀ fun oun gẹgẹ bi ẹnikan, oun nilati ri i gbà, ọna ti ó sì dara julọ lati ṣe iyẹn ni lati huwa lọna oloye ki ó si mu awọn animọ rere oniwa-bi-Ọlọrun dagba, gẹgẹ bi olori agbo ile naa.
Itẹriba Jẹ́ Aláàlà
Aṣẹ ọkọ kan lori aya rẹ̀ kii ṣe jalẹjalẹ. Ni awọn ọna kan itẹriba aya ni a lè fiwe itẹriba Kristẹni si alakooso ayé kan. Ọlọrun paṣẹ pe Kristẹni kan gbọdọ “wà ni itẹriba fun awọn alaṣẹ gigaju.” (Roomu 13:1, NW.) Sibẹ itẹriba yii ni gbogbo igba ni a gbọdọ mu wà ni ori iwọn ọgbọọgba pẹlu gbese ohun ti a jẹ Ọlọrun. Jesu wi pe: “Njẹ ẹ fi ohun ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti Ọlọrun fun Ọlọrun.” (Maaku 12:17) Bi Kesari (ijọba aye) ba beere pe ki a fun oun ni ohun ti ó jẹ́ ti Ọlọrun, a o ranti ohun ti apọsiteli Peteru sọ: “Awa kò gbọdọ má gbọ ti Ọlọrun ju ti eniyan lọ.”—Iṣe 5:29.
Ni ọna kan ti ó fẹ jọ iru eyi, bi obinrin Kristẹni kan ba ṣegbeyawo pẹlu ọkunrin kan ti kò loye tabi kuna lati bọwọ fun awọn ilana Kristẹni, oun, bi o tilẹ ri bẹẹ, ni ó di dandan fun lati tẹriba fun un. Dipo ṣiṣọtẹ si iṣeto ti Ọlọrun faṣẹ si yii, oun yoo ṣe daradara lati huwa sii pẹlu ifẹ ati igbatẹniro ki o sì tipa bayii gbiyanju lati jere igbẹkẹle rẹ̀. Boya iru awọn iwa rere bayii yoo mu ki ọkọ rẹ̀ yipada; ó tilẹ lè jere rẹ̀ sinu otitọ paapaa. (1 Peteru 3:1, 2) Bi ọkọ rẹ̀ bá paṣẹ fun un lati ṣe ohun kan ti Ọlọrun kà leewọ, oun nilati ranti pe Ọlọrun ni olori Oluṣakoso oun. Fun apẹẹrẹ, bi oun ba beere pe ki ó kowọnu awọn ibalopọ takọtabo oniwa palapala, iru bii ṣiṣe paṣipaarọ aya, ó di dandan fun oun lati maṣe juwọsilẹ. (1 Kọrinti 6:9, 10) Itẹriba fun ọkọ rẹ̀ ni a ṣakoso nipasẹ ẹ̀rí ọkan rẹ̀ ati itẹriba rẹ̀ ṣiṣe pataki julọ fun Ọlọrun.
Ni akoko Ọba Dafidi, Abigẹli ṣegbeyawo pẹlu Nabali, ọkunrin kan ti kò bọwọ fun awọn ilana atọrunwa ti ó sì huwa lọna onikanra ati alainifẹẹ si Dafidi ati awọn ọkunrin Dafidi. Awọn wọnyi ti daabobo ẹgbẹẹgbẹrun awọn agutan ati ewurẹ ti ó jẹ́ ti Nabali, ṣugbọn nigba ti Dafidi beere fun iranlọwọ ounjẹ kan, Nabali kọ̀ lati fi ohunkohun silẹ.
Ni liloye pe iṣesi oniwa ihawọ ọkọ rẹ̀ yoo mu jamba wá sori agbo ile naa, Abigẹli pinnu fun araarẹ lati mu ounjẹ lọ fun Dafidi. “Abigẹli si yara, ó sì mu igba iṣu akara ati igo ọti waini meji, ati agutan marun-un, ti a ti sè, ati oṣuwọn agbado yíyan marun-un, ati ọgọrun-un ìdì àjàrà gbigbẹ, ati igba akara eso ọpọtọ, ó sì dì wọn ru kẹtẹkẹtẹ. Oun sì wi fun awọn ọmọkunrin rẹ̀ pe, maa lọ niwaju mi; wo o, emi nbọ lẹhin yin. Ṣugbọn oun kò wi fun Nabali baale rẹ̀.”—1 Samuẹli 25:18, 19.
Abigẹli ha ṣe aṣiṣe ni hihuwa lodisi ifẹ ọkọ rẹ̀ bi? Kii ṣe ninu ọran yii. Itẹriba Abigẹli kò beere pe ki oun jẹ́ alainifẹẹ bi ọkọ rẹ̀, paapaa niwọn bi ipa ọna alailọgbọn Nabali ti fa gbogbo agbo ile naa sinu ewu. Fun idi yii, Dafidi wi fun un pe: “Alabukunfun ni Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun Isirẹli, ti ó ran ọ lonii yii lati pade mi! Ibukun sì ni fun ọgbọn rẹ.” (1 Samuẹli 25:32, 33) Ni ọna kan naa, awọn aya Kristẹni lonii kò gbọdọ fa rugudu ki wọn si sọtẹ lodisi ipo ori awọn ọkọ wọn, ṣugbọn bi awọn wọnyi ba ntẹle ipa ọna ti kii ṣe ti Kristẹni, awọn aya wọn kò nilati tẹle wọn ninu eyi.
Loootọ, Pọọlu ninu lẹta rẹ̀ si awọn ara Efesu sọ pe: “Nitori naa gẹgẹ bi ijọ ti tẹriba fun Kristi, bẹẹ sì ni ki awọn aya ki ó maa ṣe si ọkọ wọn ni ohun gbogbo.” (Efesu 5:24) Lilo ti apọsiteli naa lo ọrọ naa “ohun gbogbo” nihin-in kò tumọsi pe kò si awọn ààlà fun itẹriba iyawo naa. Ọrọ Pọọlu naa, “nitori gẹgẹ bi ijọ ti tẹriba fun Kristi,” tọka si ohun ti oun ní lọkan. Ohun gbogbo ti Kristi ba beere fun lọwọ ijọ rẹ̀ jẹ ododo, ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun. Nitori naa, ijọ lè fi tirọruntirọrun ati tayọtayọ tẹriba fun un ninu ohun gbogbo. Ni ọna kan naa, aya Kristẹni ọkọ kan ẹni ti ó fi titaratitara gbiyanju lati tẹle apẹẹrẹ ti Jesu yoo ni inudidun lati tẹriba fun un ninu ohun gbogbo. Oun mọ pe ó daniyan gan-an fun ire oun didara julọ, oun ki yoo sì mọ̀-ọ́nmọ̀ wi fun un lati ṣe ohun kan ti kò si ni iṣọkan pẹlu ifẹ Ọlọrun.
Ọkọ kan yoo pa ifẹ ati ọ̀wọ̀ aya rẹ mọ́ nigba ti oun ba fi animọ oniwa-bi-Ọlọrun ti ori rẹ̀, Jesu Kristi, ẹni ti o paṣẹ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lati nifẹẹ araawọn han. (Johanu 13:34) Ani bi o tilẹ jẹ pe ọkọ kan lè ṣaṣiṣe ti ó sì jẹ́ alaipe, bi oun ba ṣabojuto ipo aṣẹ rẹ̀ ni iṣọkan pẹlu ipo olori gigajulọ ti Kristi, oun mu ki ó rọrun fun aya rẹ lati ni inu didun lati ni in gẹgẹ bi olori rẹ̀. (1 Kọrinti 11:3) Bi aya kan ba mu awọn animọ Kristẹni naa ti iwọntunwọnsi ati iṣeun-ifẹ dagba, ko nira fun un lati tẹri araarẹ ba fun ọkọ rẹ̀.
Onirẹlẹ Ati Olugbatẹniro
Awọn ọkọ ati awọn aya ninu ijọ jẹ́ arakunrin ati arabinrin nipa tẹmi pẹlu iduro ti ó rí bakan naa niwaju Jehofa. (Fiwe Galatia 3:28.) Bi o ti wu ki o ri, awọn ọkunrin ni Ọlọrun ti yan lati ṣe abojuto ijọ. Eyi ni awọn obinrin ọlọkan titọ fi tayọtayọ kà sí pẹlu gbogbo itẹriba. Iṣẹ aigbọdọmaṣe wiwuwo ti ó sì gbe ka ori awọn ọkunrin lati maṣe jẹ gàba lori agbo naa ni awọn ọkunrin ti ó dagbadenu ninu ijọ fi tirẹlẹtirẹlẹ mọdaju.—1 Peteru 5:2, 3.
Bi eyi ba jẹ iru ibatan ti ó wa laaarin awọn ọkunrin ati awọn obinrin ninu ijọ, bawo ni Kristẹni ọkọ kan ṣe le dare fun ihuwa rẹ̀ bi òǹrorò kan lori aya rẹ̀, arabinrin rẹ̀ nipa tẹmi? Bawo si ni aya ṣe le dare fun jíjàdù pẹlu ọkọ rẹ̀ fun ipo olori? Kaka bẹẹ, wọn gbọdọ ba araawọn lò gẹgẹ bi Peteru ti ṣi gbogbo mẹmba ijọ leti pe: “Ki gbogbo yin ṣe oninu kan, ẹ maa ba araayin kẹ́dùn, ẹ ni ifẹ ará, ẹ maa ṣe ìyọ́nú, ẹ ni ẹ̀mí irẹlẹ.” (1 Peteru 3:8) Pọọlu pẹlu gbani nimọran pe: “Ẹ fi awọn ifẹni onikẹẹ ti ìyọ́nú, inurere, irẹlẹ ero-inu, iwapẹlẹ, ati ipamọra wọ araayin laṣọ. Ẹ maa baa lọ ni fifarada a fun araayin ẹnikinni keji ati didariji araayin ẹnikinni keji lọfẹẹ bi ẹnikẹni ba ni idi fun ìráhùn si ẹnikeji. Ani gẹgẹ bi Jehofa ti dariji yin lọfẹẹ, bẹẹ ni ki ẹyin pẹlu maa ṣe.”—Kolose 3:12, 13, NW.
Iru iṣarasihuwa bẹẹ ni a gbọdọ mu dagba ninu ijọ. A si gbọdọ mu wọn dagba ni pataki laaarin ọkọ ati aya ninu ile Kristẹni. Ọkọ kan lè fi ifẹni onikẹẹ ati irẹlẹ han nipa titẹtisi awọn imọran lati ọdọ aya rẹ̀. Oun gbọdọ ronu nipa awọn koko oju iwoye aya rẹ̀ ki ó to ṣe awọn ipinnu ti ó kan idile. Awọn aya Kristẹni kii ṣe olori òfo. Wọn lè fun awọn ọkọ wọn ni awọn amọran ti ó gbeṣẹ lati igba de igba, gẹgẹ bi Sera ti ṣe fun ọkọ rẹ, Aburahamu. (Jẹnẹsisi 21:12) Ni ọwọ keji ẹ̀wẹ̀, Kristẹni aya kan kò ni jẹ afidandangbọn beere lọna aigbatẹniro lọwọ ọkọ rẹ̀. Oun yoo fi inurere ati irẹlẹ ero-inu rẹ̀ han nipa titẹle idari rẹ ati kikọwọti awọn ipinnu rẹ̀, ani bi o tilẹ jẹ pe wọn lè yatọ si awọn ohun ti oun fẹ ju ni ìgbà miiran.
Ọkọ olugbatẹniro kan, bii alagba olugbatẹniro kan, jẹ ẹni ti ó ṣee sunmọ ati oninurere. Aya onifẹẹ kan ndahunpada nipa jijẹ oniyọọnu ati onipamọra, ni mimọyi awọn isapa ti oun nse lati mu ẹrù iṣẹ rẹ̀ ṣẹ loju aipe ati awọn ikimọlẹ igbesi-aye. Nigba ti ọkọ ati aya ba mu iru awọn iṣarasihuwa wọnyi dagba, itẹriba ninu igbeyawo ki yoo jẹ́ iṣoro. Kaka bẹẹ, ó jẹ orisun ayọ, aabo, ati itẹlọrun pipẹtiti.