Ojú Ìwòye Bíbélì
Ìtẹríba Aya—Kí Ni Ó Túmọ̀ Sí?
Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN, Bíbélì, sọ nínú Éfésù 5:22 pé: “Kí àwọn aya wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ wọn gẹ́gẹ́ bíi fún Olúwa.” Kí ni èyí túmọ̀ sí gan-an? Ṣé aya kan gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún ohun gbogbo tí ọkọ kan bá fẹ́, láìtàrò ohunkóhun ni bí? Ṣé aya náà kò lè lo ìdánúṣe tirẹ̀ rárá tàbí kí ó ní èrò tí ó yàtọ̀ sí ti ọkọ rẹ̀ ni?
Gbé àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa Ábígẹ́lì yẹ̀ wò. Ó gbégbèésẹ̀ ọlọgbọ́n, ṣùgbọ́n lọ́nà tí kò bá ìfẹ́ ọkọ rẹ̀ ọlọ́lá, Nábálì, mu. Láìka inú rere tí àwọn ọmọlẹ́yìn Dáfídì, tí Ọlọ́run yàn láti jẹ́ ọba Ísírẹ́lì, fi hàn sí Nábálì sí, Nábálì ti “kanra mọ́ wọn.” Ìwà àìmoore Nábálì ru Dáfídì nínú, ó múra láti pa á. Ábígẹ́lì mọ̀ pé gbogbo agbo ilé òún wà nínú ewu. Ó mú kí Dáfídì fojú àánú hàn. Báwo?—Sámúẹ́lì Kìíní 25:2-35.
Ábígẹ́lì sọ fún Dáfídì pé Nábálì jẹ́ ‘ẹni tí kò wúlò fún nǹkan kan,’ ó sì kó àwọn ohun tí Nábálì kò fẹ́ láti fún Dáfídì fún un. Lọ́nà ẹ̀tọ́, kò tọ́ kí ọkọ tàbí aya polongo àṣìṣe alábàágbéyàwó rẹ̀. Ẹlẹ́mìí ọ̀tẹ̀ ha ni Ábígẹ́lì nítorí pé ó sọ̀rọ̀, ó sì hùwà lọ́nà yìí bí? Rárá o. Ó ń gbìyànjú láti dáàbò bo ẹ̀mí Nábálì àti agbo ilé rẹ̀ ni. Kò sí ìtanilólobó kan pé ó sọ ìwà àìlọ́wọ̀ tàbí ẹ̀mí òmìnira dàṣà. Bẹ́ẹ̀ sì ni Nábálì, tí ó ṣòro láti tẹ́ lọ́rùn, kò sọ rárá pé ọ̀nà tí ó ń gbà ṣèrànwọ́ láti bójú tó dúkìá ìní rẹ̀ títóbi kò tẹ́ òun lọ́rùn. Ṣùgbọ́n nínú ipò yánpọnyánrin yìí, ọgbọ́n mú kí ó lo ìdánúṣe ara rẹ̀. Síwájú sí i, Bíbélì fọwọ́ sí ohun tí Ábígẹ́lì ṣe.—Sámúẹ́lì Kìíní 25:3, 25, 32, 33.
Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú àkókò Ábígẹ́lì, àwọn àkókò wà tí àwọn aya àwọn baba ìgbàgbọ́ fi ojú ìwòye wọn hàn, tí wọ́n sì gbégbèésẹ̀ tí ó yàtọ̀ sí ohun tí àwọn ọkọ wọ́n fẹ́. Síbẹ̀, a fi “àwọn obìnrin mímọ́ tí wọ́n ní ìrètí nínú Ọlọ́run” wọ̀nyí hàn gẹ́gẹ́ bí àwòkọ́ṣe ìtẹríba fún àwọn Kristẹni aya. (Pétérù Kìíní 3:1-6) Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí Sárà ṣàkíyèsí pé ọmọkùnrin Ábúráhámù, Íṣímáẹ́lì, ń ṣèkùfì sí ọmọkùnrin wọn, Aísíìkì, ó pinnu pé kí wọ́n lé Íṣímáẹ́lì jáde. Èyí “burú gidigidi ní ojú Ábúráhámù.” Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fún Ábúráhámù pé: “Má ṣe jẹ́ kí ó burú ní ojú rẹ nítorí ọmọdékùnrin náà, . . . ní gbogbo èyí tí Sárà ń sọ fún ọ, fetí sí ohùn rẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 21:11, 12.
A Nílò Ìfòyemọ̀
Nígbà náà, kò ní dára kí aya kan nímọ̀lára pé a mú òun lọ́ràn-anyàn láti ṣe ohun tí ó mọ̀ pé kò bọ́gbọ́n mu rárá tàbí tí ó tàpá sí àwọn ìlànà Ọlọ́run, látàrí ìtẹríba. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò yẹ kí ó nímọ̀lára ẹ̀bi fún gbígbégbèésẹ̀ nínú àwọn ọ̀ràn pàtàkì kan, gẹ́gẹ́ bí Ábígẹ́lì àti Sárà ti ṣe.
Ìtẹríba aya kò túmọ̀ sí pé aya kan gbọ́dọ̀ máa fara mọ́ gbogbo ohun tí ọkọ kan bá ń fẹ́. Kí ni ìyàtọ̀ ibẹ̀? Nígbà tí ọ̀ràn bá kan àwọn ìlànà títọ́, ó lè jẹ́ pé kò ní láti fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ọkọ rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ó ṣì fi ẹ̀mí ìtẹríba oníwà-bí-Ọlọ́run hàn.
Dájúdájú, ó yẹ kí aya kan ṣọ́ra kí ó má baà ré kọjá ìfẹ́ ọkọ rẹ̀ nítorí ìfẹ́ inú ẹni, àránkàn, tàbí àwọn ìtẹ̀sí mìíràn tí kò tọ́. Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ afòyemọ̀, “olóye,” gẹ́gẹ́ bí Ábígẹ́lì ṣe jẹ́.—Sámúẹ́lì Kìíní 25:3.
Nígbà Tí Ọkọ Bá Ń Yẹ Ẹrù Iṣẹ́ Sílẹ̀
Góńgó àti ẹ̀mí ìsúnniṣe pàtàkì tí ó wà nídìí ìtẹríba oníwà-bí-Ọlọ́run aya kan jẹ́ láti tẹ́ Jèhófà lọ́rùn nípa fífọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, kí ó sì máa kọ́wọ́ ti àwọn ìpinnu rẹ̀. Èyí rọrùn díẹ̀ nígbà tí ọkọ kan bá dàgbà dénú nípa tẹ̀mí. Ó lè jẹ́ ìpèníjà bí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀.
Nínú ọ̀ràn yìí, báwo ni ó ṣe lè ṣe é? Ó lè fi taratara bẹ̀ ẹ́ tàbí kí ó dábàá àwọn ìpinnu tí yóò ṣàǹfààní fún ìdílé jù lọ. Bí aya náà bá jẹ́ kí ọkọ rẹ̀ ‘mú ipò iwájú,’ ọkọ náà lè túbọ̀ já fáfá sí i. Fífi ẹjọ́ wẹ́wẹ́ pá ọkọ náà lórí nígbà gbogbo ń tàpá sí ẹ̀mí ìtẹríba tí ó tọ́. (Òwe 21:19) Síbẹ̀, bí ìlànà ìṣe ọkọ bá fi ire ìdílé sínú ewu ní kedere, aya lè yàn láti dábàá ipa ọ̀nà tí ó tọ́, gẹ́gẹ́ bí Sárà ti ṣe.
Bí ọkọ náà bá jẹ́ aláìgbàgbọ́, ìpèníjà tí aya náà ní tilẹ̀ tún pọ̀ jù. Síbẹ̀, aya náà gbọ́dọ̀ wà ní ìtẹríba níwọ̀n bí ọkọ rẹ̀ kò ti béèrè pé kí ó ṣẹ̀ sí àwọn òfin Bíbélì. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ìhùwàpadà Kristẹni aya kan jẹ́ bíi ti àwọn ọmọ ẹ̀yìn nígbà tí ilé ẹjọ́ kan wí fún wọn láti ṣẹ̀ sí àṣẹ Ọlọ́run pé: “Àwá gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29.
Bí ó ti wù kí ó rí, nítorí àìní ìrírí tó àti ọgbọ́n tí kò tó nǹkan, kódà àwọn ọkọ àti aya tí wọ́n ní èrò rere pàápàá lè ré kọjá ìlà àwọn ipa iṣẹ́ wọn. Ọkọ lè ṣàìní ìgbatẹnirò; aya lè máa lepá mọ́ àwọn ohun àyànláàyò rẹ̀ jù. Kí ni yóò ṣèrànwọ́? Ojú ìwòye wíwà déédéé nípa ara ẹni ṣe pàtàkì fún àwọn méjèèjì, níwọ̀n bí “gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà.”—Jákọ́bù 3:2.
Ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin yóò wá mọrírì ìdánúṣe àìlábòsí aya kan bí ó bá lò ó lọ́nà bíbọ́gbọ́n mu. Ó sì tún ń mú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pọ̀ sí i bí àwọn méjèèjì bá ń tọrọ àforíjì nígbà tí wọ́n bá ṣàṣìṣe. Bí Jèhófà ṣe ń dárí àìdójú ìlà wa ojoojúmọ́ jì wá, bákan náà, ni ó ṣe yẹ kí a máa dárí ji àwọn ẹlòmíràn. “Olúwa, ì bá ṣe pé kí ìwọ kí ó máa sàmì ẹ̀ṣẹ̀, Olúwa ta ni ì bá dúró? Nítorí ìdáríjì wà lọ́dọ̀ rẹ.”—Orin Dáfídì 130:3, 4.
“Ìtẹríba fún Ara Yín Lẹ́nìkíní Kejì”
Nígbà náà, fún ire tọ̀túntòsì wa, Ìwé Mímọ́ gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ wà ní ìtẹríba fún ara yín lẹ́nìkíní kejì nínú ìbẹ̀rù Kristi.” Ẹ máa fún tọ̀túntòsì ní ọ̀wọ̀ onífẹ̀ẹ́; ẹ má ṣe ṣèdíwọ́ tàbí kí ẹ figa gbága. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà ń bá a lọ pé: “Kí àwọn aya wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ wọn gẹ́gẹ́ bíi fún Olúwa, nítorí pé ọkọ ni orí aya rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti jẹ́ orí ìjọ.”—Éfésù 5:21-23.
Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù lò ní Éfésù 5:21, 22 túmọ̀ sí títẹrí ara ẹni ba, kì í ṣe kí a fipá múni tẹrí ba. Ìtẹríba náà sì jẹ́ nítorí ti Olúwa, kì í wulẹ̀ ṣe fún ìṣọ̀kan ìgbéyàwó nìkan. Ìjọ Kristi tí a fòróró yàn ń fínnúfíndọ̀ tẹrí ara rẹ̀ ba fún Kristi, tìdùnnútìdùnnú. Bí aya kan bá ṣe ohun kan náà fún ọkọ rẹ̀, nígbà náà, yóò ṣeé ṣe kí ìgbéyàwó náà jẹ́ aláyọ̀, tí ó sì kẹ́sẹ járí.
Ìwé Mímọ́ tún sọ pé: “Kí olúkúlùkù [ọkọ] máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀,” láìkù síbì kan. (Éfésù 5:33; Pétérù Kìíní 3:7) Ọkọ gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé òun pẹ̀lú gbọ́dọ̀ wà ní ìtẹríba fún orí rẹ̀, nítorí Bíbélì sọ pé: “Orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi.” Bẹ́ẹ̀ ni, ọkùnrin gbọ́dọ̀ wà ní ìtẹríba sí àwọn ẹ̀kọ́ Kristi. Kristi, pẹ̀lú, wà ní ìtẹríba fún orí rẹ̀: “Orí Kristi ni Ọlọ́run.” Nídìí èyí, olúkúlùkù ni ó ní orí, àyàfi Jèhófà. Kódà, òún tilẹ̀ mú ara rẹ̀ bá àwọn òfin rẹ̀ mu.—Kọ́ríńtì Kìíní 11:3; Títù 1:2; Hébérù 6:18.
Ìtẹríba Kristẹni wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, ó sì ṣàǹfààní fún takọtabo. Ó ń mú ìṣọ̀kan àti ìtẹ́lọ́rùn tí Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ nìkan ṣoṣo lè mú fúnni wá nínú ìgbéyàwó.—Fílípì 4:7.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 14]
Leslie’s