Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Ó Hùwà Ọgbọ́n
ÁBÍGẸ́LÌ kíyè sí pé jìnnìjìnnì bo ọ̀dọ́kùnrin náà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ tó báàyàn lẹ́rù lóòótọ́. Wàhálà ńlá ló ń bọ̀ lọ́nà. Àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [400] ọmọ ogun ti ń bọ̀ lójú ọ̀nà, wọ́n sì ti ṣe tán láti pa gbogbo ọkùnrin tó bá wà nílé Nábálì, ìyẹn ọkọ Ábígẹ́lì. Kí nìdí?
Nábálì leku ẹdá tó dá gbogbo ẹ̀ sílẹ̀. Ó ti hùwà ọ̀dájú àti ìwà àfojúdi bó ṣe máa ń ṣe. Àmọ́ ẹni tó fàbùkù kàn lọ́tẹ̀ yìí máa bu ú lọ́wọ́, ó ti fàbùkù kan olórí àwọn ọmọ ogun kan, ẹni tó láwọn ọmọ ogun tó kọ́ṣẹ́ mọṣẹ́ tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ọ̀gá wọn. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó ń ṣiṣẹ́ fún Nábálì, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ darandaran, wá sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún Ábígẹ́lì torí ó gbà pé Ábígẹ́lì máa róhun tó lè ṣe láti fi gba àwọn sílẹ̀. Àmọ́, kí ni obìnrin kan ṣoṣo máa ṣe lójú ẹgbẹ́ ọmọ ogun?
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ ká mọ nǹkan díẹ̀ nípa obìnrin tó fani lọ́kàn mọ́ra yìí. Ta ni Ábígẹ́lì? Báwo ni wàhálà yìí ṣe bẹ̀rẹ̀? Kí la sì lè rí kọ́ látinú ìgbàgbọ́ tí obìnrin náà ní?
Ó Ní “Ọgbọ́n Inú Dáadáa, Ó sì Lẹ́wà ní Ìrísí”
Ábígẹ́lì àti Nábálì ò fi ibì kankan bára mu. Bóyá ni Nábálì lè rí aya rere tó dáa lóbìnrin ju Ábígẹ́lì lọ fẹ́, àmọ́ ó ṣeni láàánú pé Ábígẹ́lì bára ẹ̀ lọ́dọ̀ ẹhànnà ọkùnrin yìí. Òótọ́ ni pé ọkùnrin náà lówó lọ́wọ́. Ìdí nìyẹn tó fi kara ẹ̀ séèyàn pàtàkì, àmọ́ irú ojú wo làwọn èèyàn fi ń wò ó? Bóyá la tún lè rí ẹnì kankan tí Bíbélì ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí èèyànkéèyàn lọ́nà tó ju ti Nábálì lọ. Orúkọ ẹ̀ gan-an túmọ̀ sí “Òpònú” tàbí “Arìndìn.” Ṣáwọn òbí ẹ̀ náà ló fún un nírú orúkọ yẹn nígbà tí wọ́n bí i, àbí orúkọ táwọn èèyàn fún un nígbà tó yá torí bó ṣe ń hùwà? Èyí ó wù kó jẹ́, orúkọ rò ó. Nábálì “le koko, ó sì burú ní àwọn ìṣe rẹ̀.” Ẹhànnà àti òkú ọ̀mùtí ni, àwọn èèyàn máa ń bẹ̀rù ẹ̀ gan-an, wọ́n sì kórìíra ẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 25:2, 3, 17, 21, 25.
Ní ti Ábígẹ́lì, ìwà ẹ̀ yàtọ̀ pátápátá. Orúkọ ẹ̀ túmọ̀ sí “Bàbá Mi Ti Múnú Ara Ẹ̀ Dùn.” Àmúyangàn ọmọ ni ọmọbìnrin tó bá rẹwà máa ń jẹ́ fún ọ̀pọ̀ bàbá, àmọ́ inú bàbá tó bá jẹ́ ọlọ́gbọ́n túbọ̀ máa ń dùn tí ọmọbìnrin wọn bá ń hùwà ọgbọ́n. Lọ́pọ̀ ìgbà, ẹni tó bá rẹwà ní ìrísí kìí rí ìdí tó fi yẹ kóun ní àwọn ànímọ́ bí ọgbọ́n inú, òye, ìgboyà tàbí ìgbàgbọ́. Àmọ́, ti Ábígẹ́lì ò rí bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé ó “ní ọgbọ́n inú dáadáa, ó sì lẹ́wà ní ìrísí.”—1 Sámúẹ́lì 25:3.
Àwọn kan lónìí lè máa ronú pé kí nìdí tírú obìnrin tó gbọ́n bẹ́ẹ̀ ṣe lọ fẹ́ ọkùnrin tí kò dára fún ohunkóhun yìí? Má gbàgbé pé láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ọ̀pọ̀ òbí ló máa ń yan ẹni tí ọmọ wọn máa fẹ́. Tí wọn ò bá sì yan ẹni tí ọmọ wọn máa fẹ́, ìpinnu àwọn òbí lórí ọ̀rọ̀ náà máa ń ṣe pàtàkì gan-an. Ṣáwọn òbí Ábígẹ́lì mọ̀ sí ẹni tí Ábígẹ́lì fẹ́ yìí, àbí àwọn tiẹ̀ ló fẹ́ ẹ fún Nábálì torí ọrọ̀ àti òkìkí tí Nábálì ní? Ṣé kì í ṣe àìlówó lọ́wọ́ ló sún wọn dédìí ohun tí wọ́n ṣe yìí? Èyí ó wù kó jẹ́, ọrọ̀ tí Nábálì ní kò sọ ọ́ di ọkọ rere.
Àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ ọlọ́gbọ́n máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn pé kí wọ́n fi ojú tó tọ́ wo ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó. Wọn kìí gba àwọn ọmọ wọn nímọ̀ràn láti fẹ́ ẹnì kan torí owó tàbí kí wọ́n fi tipátipá mú káwọn ọmọ wọn máa fẹ́ ẹnì kan sọ́nà nígbà tí wọ́n ṣì kéré láti máa ṣojúṣe àgbàlagbà. (1 Kọ́ríńtì 7:36) Ó ti pẹ́ jù fún Ábígẹ́lì láti máa ronú nípa irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ohun yòówù tó mú kí Ábígẹ́lì fẹ́ Nábálì, ó ti fẹ́ ẹ ná, Ábígẹ́lì sì pinnu láti ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe láti dojú kọ ipò tó le koko yẹn.
“Ó Fi Ìkanra Sọ̀rọ̀ Sí Wọn”
Èyí tí Nábálì ṣe lọ́tẹ̀ yìí tún wá dá kún ìṣòro Ábígẹ́lì. Dáfídì tó jẹ́ èèyàn pàtàkì ló kàn lábùkù. Olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tí Sámúẹ́lì fòróró yàn ni Dáfídì, ìyẹn sì fi hàn pé òun ni Ọlọ́run fọwọ́ sí pé kó jọba dípò Sọ́ọ̀lù. (1 Sámúẹ́lì 16:1, 2, 11-13) Inú aginjù ni Dáfídì àtàwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600] jagunjagun ẹ̀ tí wọ́n dúró tì í gbágbáágbá ń gbé, ohun tó sì fà á ni pé wọ́n ń sá fún Sọ́ọ̀lù Ọba tó jẹ́ òjòwú àti apààyàn.
Ìlú Máónì ni Nábálì ń gbé, àmọ́ ìlú Kámẹ́lì tí kò jìnnà sí Máónì ló ti ń ṣiṣẹ́, ó sì ṣeé ṣe kó nílẹ̀ síbẹ̀.a Nábálì ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] àgùntàn tó ń sìn láwọn ìlú yẹn torí pé koríko tó pọ̀ dáadáa wà níbẹ̀, èyí sì jẹ́ kí ibẹ̀ dáa fún sísin àgùntàn. Igbó kìjikìji ló yí àwọn ìlú náà ká. Aginjù Páránì tó fẹ̀ gan-an ló wà lápá gúúsù àwọn ìlú náà. Ọ̀nà tó sì lọ sí Òkun Iyọ̀ ló wà lápá ìlà oòrùn, ọ̀nà yẹn gba inú aṣálẹ̀ tó ní kòtò àti gegele kọjá. Àgbègbè yìí ni Dáfídì àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ ti ń wá jíjẹ mímu, ó dájú pé ìyẹn ò rọrùn, wọ́n sì ń fara da ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń pàdé àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n ń bá Nábálì olówó da àwọn ẹran ẹ̀.
Báwo làwọn akíkanjú ọmọ ogun Dáfídì ṣe máa ń ṣe sáwọn tó ń bá Nábálì da ẹran? Kò nira fún wọn láti máa jí àgùntàn wọn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n dà bí ògiri tó ń dàábò bo agbo ẹran àtàwọn ìránṣẹ́ Nábálì. (1 Sámúẹ́lì 25:15, 16) Ewu tó pọ̀ ló máa ń dojú kọ àgùntàn àtàwọn tó ń dà wọ́n. Àwọn ẹranko tó lè ṣèpalára fáwọn àgùntàn pọ̀ gan-an nígbà yẹn. Wọ́n sì ti ti ibodè tó wà lápá gúúsù tó wọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pa, torí náà àwọn olè máa ń ṣọṣẹ́ lọ́pọ̀ ìgbà.b
Iṣẹ́ kékeré kọ́ ló wà lọ́rùn Dáfídì kó tó lè máa bọ́ adúrú àwọn ọkùnrin yẹn nínú aginjù. Torí náà, lọ́jọ́ kan Dáfídì rán àwọn ìránṣẹ́ mẹ́wàá sí Nábálì pé kó ran àwọn lọ́wọ́. Ìgbà tó bọ́ sákòókò gan-an ni Dáfídì rán àwọn ọkùnrin yìí. Àkókò àjọyọ̀ tí wọ́n máa ń rẹ́ irun àwọn àgùntàn ni, àwọn èèyàn sábà máa ń ta àwọn ẹlòmíì lọ́rẹ lákòókò yìí, wọ́n sì máa ń gbádùn ara wọn. Ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sì ní káwọn tó rán níṣẹ́ sọ tí wọ́n bá dọ́hùn-ún jẹ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n, ó fọ̀wọ̀ fúnni, ó sì pọ́n èèyàn lé. Ó tiẹ̀ pera ẹ̀ ní “Dáfídì ọmọkùnrin rẹ,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Dáfídì fìyẹn bọ̀wọ̀ fún Nábálì. Báwo wá ni Nábálì ṣe fún wọn lésì?—1 Sámúẹ́lì 25:5-8.
Ó bínú gan-an! Ọ̀dọ́kùnrin tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé ohun to ṣẹlẹ̀ fún Ábígẹ́lì, ó ní, Nábálì “fi ìkanra sọ̀rọ̀ sí wọn.” Nábálì ahun bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo, ó sì ń ṣàròyé nípa búrẹ́dì, omi àtàwọn ẹran tí wọ́n ti pa. Ó sọ̀rọ̀ burúkú sí Dáfídì bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan, ó sì sọ pé ìsáǹsá ìránṣẹ́ tó sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá ẹ̀ ni Dáfídì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé èrò kan náà ni Nábálì àti Sọ́ọ̀lù, tó kórìíra Dáfídì ní. Kò séyìí tó ń fi irú ojú tí Jèhófà fi ń wo Dáfídì wò ó nínú àwọn ọkùnrin méjèèjì. Ọlọ́run fẹ́ràn Dáfídì, kò sì fojú ìránṣẹ́ tó ya ọlọ̀tẹ̀ wò ó, ó mọ̀ pé òun ló máa jọba orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì láìpẹ́.—1 Sámúẹ́lì 25:10, 11, 14.
Inú bí Dáfídì gan-an nígbà táwọn tó rán níṣẹ́ pa dà wá jíṣẹ́ fún un. Ó pàṣẹ fáwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ pé, “kí olúkúlùkù sán idà rẹ̀!” Dáfídì náà bá dira ogun, ó sì kó ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [400] lára àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sẹ́yìn láti lọ jà. Ó búra pé òun máa pa gbogbo ọkùnrin tó bá ń gbé nílé Nábálì run. (1 Sámúẹ́lì 25:12, 13, 21, 22) Kò sóhun tó burú bí Dáfídì ṣe bínú, àmọ́ ọ̀nà tó gbà fìbínú ẹ̀ hàn ló burú. Bíbélì sọ pé: “Ìrunú ènìyàn kì í ṣiṣẹ́ yọrí sí òdodo Ọlọ́run.” (Jákọ́bù 1:20) Báwo ni Ábígẹ́lì ṣe máa gba àwọn èèyàn ẹ̀ sílẹ̀?
“Ìbùkún . . . ni fún Ìlóyenínú Rẹ”
Lọ́nà kan, a lè sọ pé Ábígẹ́lì ti gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ tó máa jẹ́ kó lè yanjú ìṣòro ńlá tó wà nílẹ̀ yìí. Níyàtọ̀ sí Nábálì ọkọ rẹ̀, òun ṣe tán láti fetí sílẹ̀. Ìránṣẹ́ náà sọ nípa Nábálì pé: “Àwé tí kò dára fún ohunkóhun rárá láti bá sọ̀rọ̀” ni.c (1 Sámúẹ́lì 25:17) Ó bani nínú jẹ́ pé Nábálì ò ṣe tán láti fetí sílẹ̀ torí pé ó kara ẹ̀ séèyàn pàtàkì. Irú ìwà ìjọra-ẹni-lójú bẹ́ẹ̀ ṣì wọ́pọ̀ títí dòní olónìí. Àmọ́, ọ̀dọ́kùnrin yẹn mọ̀ pé Ábígẹ́lì yàtọ̀ ní tiẹ̀, ìdí sì nìyẹn tó fi lọ ṣàlàyé ìṣòro tó wà nílẹ̀ fún un.
Ábígẹ́lì tètè ronú ohun tó máa ṣe, ó sì gbégbèésẹ̀ kíámọ́sá. Bíbélì sọ pé: “Ní kíá, Ábígẹ́lì ṣe kánkán.” Ìgbà mẹ́rin nínú ìtàn yìí ni Bíbélì lo ọ̀rọ̀ ìṣe náà “láti ṣe kánkán” nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa Ábígẹ́lì. Ábígẹ́lì ṣètò oríṣiríṣi ẹ̀bùn tó máa kó fún Dáfídì àtàwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú ẹ̀. Lára ẹ̀bùn tó ṣètò ni búrẹ́dì, wáìnì, àgùntàn, àyangbẹ ọkà, èso àjàrà gbígbẹ àti ìṣù èso ọ̀pọ̀tọ́. Ó dájú pé Ábígẹ́lì mọ ojúṣe ẹ̀ dáadáa, ó sì ń sa gbogbo ipá ẹ̀ láti máa bójú tó agbo ilé ẹ̀, ńṣe ló dà bí aya tó dáńgájíá tí ìwé Òwe wá ṣàpèjúwe nígbà tó yá. (Òwe 31:10-31) Ó ní káwọn ìránṣẹ́ kan máa kó àwọn ẹ̀bùn tó ti ṣètò náà lọ níwájú, òun nìkan sì wá ń bọ̀ lẹ́yìn. Bíbélì sọ pé: “Ṣùgbọ́n kò sọ nǹkan kan fún Nábálì ọkọ rẹ̀.”—1 Sámúẹ́lì 25:18, 19.
Ṣéyìí wá túmọ̀ sí pé Ábígẹ́lì ń ṣọ̀tẹ̀ sí ipò orí ọkọ rẹ̀ ni? Rárá o. Nábálì ti hùwà ìkà sí ẹni àmì òróró Jèhófà, ohun tó sì ṣe yìí ṣeé ṣe kó yọrí sí ikú àwọn ara ilé ẹ̀ tí wọn ò mọwọ́ mẹsẹ̀. Ṣó ṣeé ṣe kí Ábígẹ́lì náà pín nínú ìyà ọkọ ẹ̀ tí kò bá tètè gbégbèésẹ̀? Bóyá ó máa pín nínú ẹ̀ tàbí kò ní pín nínú ẹ̀, ó gbọ́dọ̀ fi ìgbọràn sí Ọlọ́run ṣáájú tọkọ ẹ̀.
Kò pẹ́ púpọ̀ tí Ábígẹ́lì fi pàdé Dáfídì àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ lójú ọ̀nà. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ó ṣe kánkán, lọ́tẹ̀ yìí, láti sọ̀ kalẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Dáfídì. (1 Sámúẹ́lì 25:20, 23) Nígbà náà ló wá kó àlàyé palẹ̀, ó ń bẹ Dáfídì pé kó ṣàánú ọkọ òun àti agbo ilé òun. Kí ló jẹ́ kọ́rọ̀ ẹ̀ wọ Dáfídì lọ́kàn?
Ó sọ pé kí Dáfídì gbà pé òun lòun ṣàṣìṣe, ó sì ní kó dárí ji òun. Ó sọ gbangba pé òun mọ̀ pé aláìnírònú ni ọkọ òun, bí ìtúmọ̀ orúkọ rẹ̀, ó sì ṣeé ṣe kó máa fìyẹn dọ́gbọ́n sọ fún Dáfídì pé ó máa bu Dáfídì kù láti lọ bá irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ jà. Ábígẹ́lì sọ pé òun gbà pé Jèhófà ni Dáfídì ń ṣojú fún torí ó mọ̀ pé “àwọn ogun Jèhófà” ni Dáfídì ń jà. Ó tún sọ pé òun mọ ìlérí tí Jèhófà ṣe pé Dáfídì máa jọba, ó sọ pé: “Jèhófà . . . yóò fàṣẹ yàn ọ́ [dájúdájú] ṣe aṣáájú lórí Ísírẹ́lì.” Yàtọ̀ síyẹn, ó rọ Dáfídì pé kó má ṣohun tó máa jẹ́ kó jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tàbí tó lè “di okùnfà títa gọ̀ọ́gọ̀ọ́,” ohun tó sì ń fìyẹn sọ ni pé kí ẹ̀rí ọkàn má bàa máa da Dáfídì láàmú tó bá yá. (1 Sámúẹ́lì 25:24-31) Àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ yìí tu Dáfídì lára, ó sì wọ̀ ọ́ lọ́kàn.
Kí wá ni Dáfídì ṣe? Ó gba àwọn nǹkan tí Ábígẹ́lì kó wá, ó sì sọ pé: “Ìbùkún ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó rán ọ lónìí yìí láti pàdé mi! Ìbùkún sì ni fún ìlóyenínú rẹ, ìbùkún sì ni fún ìwọ tí o ti dá mi dúró lónìí yìí kí n má bàa wọnú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀.” Dáfídì dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ fún bó ṣe lo ìgboyà, tó sì ṣe kánkán láti wá pàdé òun, ó sì sọ fún Ábígẹ́lì pé ó ti ran òun lọ́wọ́ láti má ṣe jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. Dáfídì wá sọ fún un pé: “Gòkè lọ sí ilé rẹ ní àlàáfíà,” ó sì fi kún un tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ pé: “Mo ti fetí sí ohùn rẹ.”—1 Sámúẹ́lì 25:32-35.
“Ẹrúbìnrin Rẹ Rèé”
Lẹ́yìn tí wọ́n pa dà sílé, Ábígẹ́lì ń ronú ṣáá nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n pàdé, bẹ́ẹ̀ ni kò ṣàì rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín Dáfídì, olóòótọ́ àti onínúure èèyàn, àti Nábálì ẹhànnà ọkọ tó fẹ́. Àmọ́, kò jẹ́ kíyẹn gbà á lọ́kàn. Bíbélì sọ pé: “Lẹ́yìn náà, Ábígẹ́lì wọlé wá bá Nábálì.” Ó pa dà wálé sọ́dọ̀ ọkọ ẹ̀, ó túbọ̀ pinnu pé òun máa ṣe gbogbo ohun tóun bá lè ṣe láti máa ṣe ipa tòun gẹ́gẹ́ bí ìyàwó Nábálì. Torí náà, ó sọ fún ọkọ ẹ̀ nípa ẹ̀bùn tó fún Dáfídì àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀. Ó yẹ kí ọkọ ẹ̀ mọ̀ lóòótọ́. Ó tún ní láti sọ fún un nípa ewu tóun ti jẹ́ kó ré agbo ilé àwọn kọjá, kó tó di pé ó máa gbọ́ ọ níbòmíì, torí pé ìtìjú gbáà ló máa jẹ́ tó bá lọ gbọ́ ọ níbòmíì. Àmọ́, kò lè sọ fún un lásìkò yẹn, torí pé, Nábálì ń jayé ọlọ́ba lọ́wọ́, ó sì ti mutí yó bìnàkò.—1 Sámúẹ́lì 25:36.
Lẹ́ẹ̀kan sí i, Ábígẹ́lì lo ìgboyà, ó sì hùwà ọgbọ́n, ó dúró di àárọ̀ ọjọ́ kejì tí ọtí ti dá lójú ọkọ ẹ̀. Nábálì máa fara balẹ̀ dáádáá láti gbọ́ ohun tó fẹ́ sọ, síbẹ̀ náà ó léwu torí Nábálì tètè máa ń bínú. Àmọ́, Ábígẹ́lì lọ bá a, ó sì sọ gbogbo bọ́rọ̀ ṣe rí fún un. Ábígẹ́lì ti ń retí pé kí ọkọ ẹ̀ gbaná jẹ, bóyá kó tiẹ̀ fẹ́ lu òun pàápàá. Àmọ́, Nábálì kàn jókòó sójú kan ni, kò dìde.—1 Sámúẹ́lì 25:37.
Kí ló ṣe ọkùnrin yìí? Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà rẹ̀ sì kú ní inú rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ sì dà bí òkúta.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àìsàn rọpárọsẹ̀ ló kọ lù ú. Ọjọ́ mẹ́wàá lẹ́yìn ìgbà náà ló kú, àìsàn kọ́ ló sì pa á. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà sì kọlu Nábálì, tí ó fi kú.” (1 Sámúẹ́lì 25:38) Bí Ọlọ́run ṣe fúnra ẹ̀ ṣèdájọ́ òdodo nìyẹn, ìgbéyàwó tó ń kó wàhálà bá Ábígẹ́lì látọjọ́ yìí wá sì dópin. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kìí fikú pa ẹnikẹ́ni lọ́nà ìyanu bẹ́ẹ̀ yẹn mọ́ lónìí, ìtàn yìí ń rán wa létí pé kò sẹ́ni tó ń jẹ gàba tàbí tó ń fìyà jẹ àwọn ẹlòmíì tí Jèhófà ò rí, ì bá à jẹ́ nínú ilé. Lásìkò tó bá tọ́ ní ojú rẹ̀, ó máa ṣohun tó bá ìdájọ́ òdodo mu.
Yàtọ̀ sí pé Ábígẹ́lì bọ́ lọ́wọ́ ọkọ burúkú, ó tún máa gba ìbùkún míì. Nígbà tí Dáfídì gbọ́ pé Nábálì ti kú, ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí Ábígẹ́lì pé òun máa fẹ́ ẹ. Ábígẹ́lì dáhùn pé: “Ẹrúbìnrin rẹ rèé gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́bìnrin láti máa wẹ ẹsẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi.” Ó ṣe kedere pé kò torí pé òun máa tó dìyàwò Dáfídì kó wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga, kódà ó ní kí Dáfídì fi òun ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀! Lẹ́yìn náà, a tún kà pé, ó ṣe kánkán lọ́tẹ̀ yìí láti lọ bá Dáfídì.—1 Sámúẹ́lì 25:39-42.
Èyí ò túmọ̀ sí pé Ábígẹ́lì ò wá ní níṣòro kankan mọ́, kìí ṣe gbogbo ìgbà ni ìgbésí ayé ẹ̀ á máa dùn yùngbà nílé Dáfídì. Dáfídì ti fẹ́ Áhínóámù tẹ́lẹ̀, ilé olórogún sì máa ń jẹ́ ìṣòro ńlá fáwọn olóòótọ́ obìnrin nígbà yẹn.d Dáfídì ò sì tíì di ọba nígbà yẹn, àwọn ohun ìdílọ́wọ́ àti ìṣòro ṣì máa dojú kọ Dáfídì kó tó wá di ọba bí Jèhófà ṣe fẹ́. Síbẹ̀, Ábígẹ́lì ran Dáfídì lọ́wọ́, ó sì tì í lẹ́yìn, ó bí ọmọkùnrin kan fún un lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó sì wá mọ̀ pé òun ní ọkọ tó mọyì òun, tó sì ń dáàbò bo òun. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Dáfídì gba Ábígẹ́lì lọ́wọ́ àwọn tó ń jí èèyàn gbé! (1 Sámúẹ́lì 30:1-19) Dáfídì tipa báyìí fara wé Jèhófà Ọlọ́run tó fẹ́ràn tó sì tún mọyì irú àwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ ọlọ́gbọ́n, onígboyà àti olóòótọ́ bẹ́ẹ̀.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kámẹ́lì yìí kì í ṣe Òkè Ńlá Kámẹ́lì tí gbogbo èèyàn mọ̀ tó wà lápá àríwá, àmọ́ ìlú kan tó wà ní ìkángun aginjù tó wà lápá gúúsù ni.
b Ó ṣeé ṣe kí Dáfídì máa rò ó pé dídáàbò bo àwọn onílẹ̀ àti agbo ẹran wọn jẹ́ iṣẹ́ ìsìn kan sí Jèhófà Ọlọ́run. Nígbà yẹn, ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé káwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù máa gbé nílẹ̀ náà. Torí náà, dídáàbò bo ilẹ̀ yẹn lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá àtàwọn olè jẹ́ ìjọsìn mímọ́.
c Gbólóhùn tí ọ̀dọ́kùnrin náà lò túmọ̀ sí “ọmọ bélíálì (ìyẹn ẹni tí kò wúlò fún ohunkóhun).” Àwọn Bíbélì míì túmọ̀ ẹsẹ yìí nípa ṣíṣàpèjúwe Nábálì bí ọkùnrin “tí kìí fẹ́ gbọ́ tẹnì kankan,” ìyẹn sì túmọ̀ sí pé “kò yẹ lẹ́ni téèyàn ń bá sọ̀rọ̀.”
d Wo àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Ọlọ́run Fọwọ́ Sí Ìkóbìnrinjọ?” ojú ìwé 30.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Ábígẹ́lì máa ń fetí sílẹ̀ dáadáa, kò dà bí ọkọ ẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ábígẹ́lì fi hàn pé òun jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, onígboyà àti olóye nígbà tó ń bá Dáfídì sọ̀rọ̀