Platypus Àràmàǹdà
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ AUSTRALIA
NÍGBÀ tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kọ́kọ́ rí platypus, wọn kò mọ ohun tí wọn óò pè é. Ẹnà kan nìyí nínú ìṣẹ̀dá, ó wọn nǹkan bíi kìlógíráàmù kan tàbí méjì, ó jọ pé ó ní àwọn ànímọ́ yíyàtọ̀ síra tí ó pe díẹ̀ lára àwọn èrò ìgbàgbọ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ wọn níjà. A ké sí ọ láti mọ̀ nípa ará Australia aláìlẹ́gbẹ́ kóńkó yìí—ìṣẹ̀dá onítìjú, afàfẹ́mọ́ra, tí ó jojú ní gbèsè. Bí ó ti wù kí ó rí, jẹ́ kí a kọ́kọ́ padà sí 1799, kí a sì wo yánpọnyánrin tí ó dá sílẹ̀ nígbà tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ará Britain ṣàyẹ̀wò awọ platypus àkọ́kọ́.
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan sọ nípa Dókítà Shaw, igbákejì alábòójútó ní ẹ̀ka Ìtàn Ìṣẹ̀dá ní Ibi Àkójọ Ohun Ìṣẹ̀m̀báyé Britain, pé: “Kò lè gba [ojú rẹ̀] gbọ́.” Ó fura pé “ẹnì kan ti lẹ àgógó pẹ́pẹ́yẹ kan mọ́ ara [ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin] kan. Ó gbìyànjú láti [gé] àgógó náà kúrò, àti pé lónìí, a ṣì lè rí àwọn àpá àlùmọ́gàjí rẹ̀ lára awọ àtètèkọ́ṣe náà.”
Kódà nígbà tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣàwárí pé awọ náà jẹ́ ojúlówó, ó ṣe wọ́n ní kàyéfì. Platypus—tí orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “ẹlẹ́sẹ̀ pẹlẹbẹ”—ní ètò ìgbékalẹ̀ ìmúrújáde tí ó jọra gan-an pẹ̀lú ti ẹyẹ, ṣùgbọ́n ó tún ní ẹṣẹ́ ọmú, tàbí ti wàrà. Ohun tí ó jọ ìtakora yìí gbé ìbéèrè náà dìde pé: Ǹjẹ́ ìṣẹ̀dá tí kò dá ni lójú yìí ń yé ẹyin, tàbí kì í yé ẹyin?
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí a ti fi ṣe àríyànjiyàn, a ṣàwárí pé ní tòótọ́, platypus máa ń yé ẹyin. Ṣùgbọ́n, ó jọ pé àwárí kọ̀ọ̀kan wulẹ̀ ń dá kún ìṣòro náà ni. Irú ọ̀wọ́ wo ni ìwọ yóò pín ìṣẹ̀dá (1) tí ń yé ẹyin ṣùgbọ́n tí ó ní ẹṣẹ́ ọmú; (2) tí ó ní irun lára àmọ́ tí ó ní àgógó pẹ́pẹ́yẹ; àti (3) tí ó ní ìgbékalẹ̀ egungun ara tí ó ní àwọn àbùdá ẹranko afàyàfà ẹlẹ́jẹ̀ tútù àmọ́ tí ó ṣì jẹ́ ẹlẹ́jẹ̀ lílọ́wọ́ọ́wọ́ sí?
Láìpẹ́, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ fohùn ṣọ̀kan pé platypus jẹ́ ẹranko afọ́mọlọ́mú ti ọ̀wọ́ Monotremata. Monotreme kan, bí ẹranko afàyàfà, ní ihò, tàbí ojú ara kan, tí ẹyin, àtọ̀, ìgbẹ́, àti ìtọ̀ ń gbà kọjá. Monotreme kan ṣoṣo mìíràn tí ó wà láàyè ni echidna. Orúkọ tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ fún platypus ni Ornithorhynchus anatinus, tí ó túmọ̀ sí “ẹranko bíi pẹ́pẹ́yẹ onígiimú ẹyẹ.”
Ẹ Jẹ́ Kí A Bẹ Platypus Kan Wò
A lè lọ sí ọgbà ẹranko kan, àmọ́ kò sí ohun tí ó dà bíi kí a rí platypus afarapamọ́ nínú ẹgàn—ohun tí ó jẹ́ pé ìwọ̀nba àwọn ará Australia ló tí ì ṣe é rí. Ìwákiri wa bẹ̀rẹ̀ ní ìhà ìlà oòrùn Australia, ní Òkè Ńlá Blue ní ìwọ̀ oòrùn Sydney, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè rí i ní agbègbè ọ̀pọ̀ lára àwọn odò, ìṣàn omi, àti adágún olómi tí kò ní iyọ̀ ní ìhà ìlà oòrùn Australia.
A dé ibẹ̀ kí oòrùn tó là níbi ògbólógbòó afárá onípákó kan tí ó wà lórí odò tí ń kọ mànà, tí irúgbìn eucalyptus yí ká. Pẹ̀lú sùúrù àti ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́, a ń wo omi náà láti rí kí irú ohun ìṣàpẹẹrẹ kan tí ń fì níbàǹbalẹ̀ fara hàn. Kò pẹ́ tí a rí nǹkan. Ní nǹkan bí 50 mítà lódìkejì ìṣàn omi, ohun kan fara hàn, tí ó ń bọ̀ lọ́dọ̀ wa. A gbọ́dọ̀ dúró láìmira.
Òpòòrò ìṣẹ́wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ omi tí ń wá láti ara àgógó rẹ̀ fẹ̀rí hàn pé platypus ni. Àwọn ìṣẹ́wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ omi tí ń tú u fó náà ń ṣẹ́ bí platypus náà ti ń lọ oúnjẹ tí ó gbé sẹ́nu bí ó ṣe ń wá oúnjẹ nísàlẹ̀ odò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé oúnjẹ rẹ̀ máa ń yàtọ̀ láti ìgbà dé ìgbà, ó máa ń ní nínú, ní pàtàkì ekòló, ìdin kòkòrò, àti edé inú omi tí kò ní iyọ̀.
Bí platypus ṣe rí kólíẹ́ yìí ha yà ọ́ lẹ́nu bí? Ó ya ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn lẹ́nu. Wọ́n finú wòye pé platypus yóò tóbi tó ẹranko beaver tàbí otter. Ṣùgbọ́n bí o ti lè rí i, ó kéré ju ológbò ọ̀sìn tí a lè mú gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ lọ. Ìwọ̀n gígùn àwọn akọ wà láàárín sẹ̀ǹtímítà 45 sí 60, ó sì wọn láti kìlógíráàmù kan sí méjì àtààbọ̀. Àwọn abo túbọ̀ kéré díẹ̀.
Bí ó ti ń ta abẹ̀bẹ̀ ẹsẹ̀ iwájú rẹ̀ wàìwàì, ó rọra lúwẹ̀ẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, ó sì wà lábẹ́ omi fún bí ìṣẹ́jú kan tàbí méjì bí ó ti rọra ń lúwẹ̀ẹ́ wá sábẹ́ afárá. Kì í lo ẹsẹ̀ ẹ̀yìn rẹ̀ tí abẹ̀bẹ̀ rẹ̀ kò fẹ̀ fún lílúwẹ̀ẹ́, ṣùgbọ́n ó ń lò ó gẹ́gẹ́ bí ìtukọ̀, ó sì ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ìrù rẹ̀ nígbà tí ó bá ń lúwẹ̀ẹ́. Wọ́n tún máa ń dá ara rẹ̀ ró gbọn-ingbọn-in tí ó bá fara sin.
Bí a bá yọ platypus lẹ́nu, ó máa ń lúwẹ̀ẹ́ lọ́nà tí a óò fi gbọ́ ọwọ́ ìjami rẹ̀, ìyẹn sì túmọ̀ sí, ó dìgbóṣe! Nítorí náà, ìgbà tí ó bá wà lábẹ́ omi nìkan ni a máa ń sọ̀rọ̀. Ènìyàn yóò sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé: “Báwo ni ara irú ẹ̀dá kóńkó yẹn ṣe ń móoru, pàápàá jù lọ nínú omi dídì nígbà òtútù?” Platypus ń rọ́nà gbé e gbà, ọpẹ́lọpẹ́ àwọn ohun àrànṣe méjì: ètò ìyíkẹ́míkà-padà tí ń pèsè agbára ní ìwọ̀n yíyára, tí ó ń tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ara rẹ̀ móoru láti inú, àti irun ṣìkìtì tí ń mú kí ìmóoru náà wà nínú.
Àgógó Àgbàyanu Yẹn
Àgógó platypus rírọ̀, tí ó jọ rọ́bà náà díjú gan-an. Awọ ohun arùmọ̀lára sókè tí ń ṣiṣẹ́ fún ìfarakàn àti ìgbòkègbodò onímànàmáná wà lára rẹ̀. Ní ìsàlẹ̀ odò, platypus máa ń rọra fi àgógó rẹ̀ láti ẹ̀gbẹ́ kan sí èkejì bí ó ti ń ṣàyẹ̀wò, tí ó tilẹ̀ ń rí ohun onímànàmáná tí ó kéré jọjọ tí ìfúnṣanpọ̀ ẹran ìjẹ rẹ̀ ń tú jáde. Nígbà tí platypus náà bá wà lábẹ́ omi, àgógó rẹ̀ ni lájorí ohun tí ó fi ń mọ ohun tí ń lọ nínú ayé, nítorí pé ó máa ń di ojú, etí, àti imú rẹ̀ pinpin ni.
Ṣọ́ra fún Àwọn Ọ̀gàn Yẹn!
Bí ó bá jẹ́ akọ ni ọ̀rẹ́ wa kóńkó náà, ó máa ń ní ọ̀gàn méjì lọ́rùn ẹsẹ̀ ẹ̀yìn tí àwọn ihò so pọ̀ mọ́ ẹṣẹ́ oró méjì níbi itan rẹ̀. Yóò fi tagbáratagbára na àwọn ọ̀gàn méjèèjì sí ara ohun tí ń gbéjà kò ó lọ́nà kan tí ó jọra pẹ̀lú bí ẹlẹ́ṣin kan ṣe ń gún ẹṣin rẹ̀ ní kẹ́ṣẹ́. Lákòókò díẹ̀ lẹ́yìn ìgbọ̀nrìrì àkọ́kọ́, ẹni tí ó kọ lù náà yóò ní ìrora àti ìwúlé níbi tí ó ti ta á.
Bí ó ti wù kí ó rí, bí a bá mú platypus tọ́jú, ó lè di aláìlèṣèpalára gan-an bí ọmọ ajá. Ibi Ìdáàbòbo Healesville, ní Victoria, ti ń tọ́jú àwọn ẹran wọ̀nyí fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, wọ́n sì ròyìn pé ọ̀kan tí ń gbé ibẹ̀ látijọ́ máa ń “dá àwọn àlejò lára yá fún ọ̀pọ̀ wákàtí, tí yóò máa ṣíkaakà kí a lè máa fọwọ́ ra á níkùn . . . Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn àlejò máa ń rọ́ lọ síbẹ̀ láti wo ẹran kóńkó ṣíṣàrà ọ̀tọ̀ yìí.”
Platypus tí a ń wò mòòkùn tí ó kẹ́yìn fún ọjọ́ náà bí oòrùn òwúrọ̀ ti tàn gba orí òkè ńlá wá sí ìlà oòrùn wa. Lóru mọ́jú, ó ti jẹ́ ohun tí ó pọ̀ ju ìdá márùn-ún ìwọ̀n rẹ̀. Bí ó ti ń ti inú omi gòkè wá, àwọn abẹ̀bẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀ iwájú ń sá wọnú, wọ́n sì ń ṣí àwọn èékánná rẹ̀ ńláńlá síta. Ó wá forí lé ọ̀kan lára àwọn ihò rẹ̀, tí ó fọgbọ́n gbẹ́ sáàárín àwọn gbòǹgbò igi fún ààbò lọ́wọ́ ọ̀gbàrá àti ìbìṣubú. Àwọn ihò tí ó fi ṣètẹ́ sábà máa ń gùn tó nǹkan bíi mítà 8, ṣùgbọ́n àwọn ihò míràn lè jìn tó mítà 1, kí wọ́n sì fẹ́rẹ̀ẹ́ gùn tó 30 mítà, wọ́n sì lè pẹ̀ka lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́. Àwọn ihò tún ń pèsè ààbò lọ́wọ́ ìwọ̀n òtútù lílégbá kan, ní mímú kí wọ́n ní ibùba tí ó móoru fún àwọn abo láti tọ́jú ọmọ wọn.
Àkókò Ìyẹ́yin
Ní ìgbà ìrúwé, abo máa ń lọ sí ìyẹ̀wù kan tí ó fi ewéko ṣe ọhá rẹ̀ nínú ọ̀kan lára àwọn ihò tí ó gbẹ́ jinlẹ̀, yóò sì yé ẹyin kan sí mẹ́ta (ó sábà ń jẹ́ méjì) tí ó jẹ́ ìwọ̀n èékánná àtàǹpàkò. Ó máa ń sàba lé ẹyin rẹ̀ nípa wíwé wọn mọ́ ara àti ìrù rẹ̀ tí ó lọ́ràá. Láàárín nǹkan bí ọjọ́ mẹ́wàá, àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jáde láti inú èèpo ẹyin wọn tí ó jọ awọ àgùntàn, wọn óò sì máa mu wàrà tí ń wá láti inú ẹṣẹ́ ọmú ìyá wọn méjèèjì. Bákan náà, abo platypus máa ń dá tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ ni; àwọn ẹran afọ́mọlọ́mú wọ̀nyí kò fúnni ní ẹ̀rí pé wọ́n ń wà pọ̀ ní ìlákọ ìlábo fún ọjọ́ pípẹ́.
Ní nǹkan bíi February, lẹ́yìn ìdàgbàsókè olóṣù mẹ́ta ààbọ̀, àwọn ọmọ ti ṣe tán láti wọmi. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ìwọ̀nba díẹ̀ péré lára àwọn ẹran náà ni ó lè wà nínú àgbájọ omi kan, àwọn ọmọ lè wá omi tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní platypus púpọ̀ nínú, kódà wọ́n ń sọdá ní àwọn agbègbè ilẹ̀ tí ó léwu láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Nígbà tí a mú àwọn platypus tọ́jú, wọ́n gbé tó 20 ọdún, ṣùgbọ́n nínú igbó, ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn kì í pẹ́ tó bẹ́ẹ̀. Bí ọ̀dá àti ìkún omi ṣe ń pa wọ́n ni àwọn goanna (awọ́nrínwọ́n ńlá), kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, àwọn ẹyẹ apẹranjẹ ńlá, kódà àwọn ọ̀nì ń pa wọ́n jẹ ní àríwá Queensland jíjìnnà réré. Bí ó ti wù kí ó rí, ènìyàn ló ṣì ń wu àwọn platypus léwu jù lọ, kì í ṣe pé wọ́n ń mọ̀ọ́mọ̀ pa wọ́n (òfin ti wà fún dídáàbò bo àwọn platypus nísinsìnyí), ṣùgbọ́n nípa rírakaka lé ibùgbé àdánidá wọn láìdábọ̀.
Bí o bá ṣèbẹ̀wò sí Australia, o lè wo ọ̀rẹ́ wa kóńkó aláìlẹ́gbẹ́ tí ó jẹ́ àmúlùmálà ẹ̀dá alágòógó bíi ti pẹ́pẹ́yẹ ní ibùgbé àdánidá rẹ̀, nítorí pé o kò lè rí ọ̀kankan nínú igbó níbikíbi mìíràn lágbàáyé. Ìwọ yóò rí apá mìíràn nínú agbára ìṣẹ̀dá aláìlópin tí Ẹlẹ́dàá ní—àti ànímọ́ ìdẹ́rìn-ín pani pẹ̀lú—nípasẹ̀ platypus.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
“Platypus” ń fi àwọn abẹ̀bẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀ gbéra sọ síwájú
[Credit Line]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure Taronga Zoo
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
“Platypus” tí ó kéré ju ológbò ọ̀sìn lọ, wọ̀n tó kìlógíráàmù kan sí méjì àtààbọ̀
[Credit Line]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure Ọ̀mọ̀wé Tom Grant
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Àgógó rẹ̀ atètè-nímọ̀lára ń wá ẹran ìjẹ lábẹ́ omi. (Ibí Ìdáàbòbo Healesville ni “platypus” yìí wà)
[Credit Line]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure Healesville Sanctuary
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 16]
Fọ́tò: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure Ọ̀mọ̀wé Tom Grant