Ǹjẹ́ O Mọ̀?
(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 22. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìtẹ̀jáde “Insight on the Scriptures,” tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.)
1. Ọ̀nà wo ni Ọlọ́run gbà ṣàṣeparí ìṣẹ̀dá àgbáálá ayé tí a lè fojú rí? (Jẹ́nẹ́sísì 1:2)
2. Kí ni Jèhófà fi àwọn ìṣẹ̀dá atànmọ́lẹ̀ lójú òfuurufú ṣe ìpìlẹ̀ fún? (Wo Jẹ́nẹ́sísì 1:14.)
3. Kí ni àwọn ìránṣẹ́ Senakéríbù fẹ́ láti ṣàṣeparí rẹ̀ nípa sísọ̀rọ̀ sókè sí àwọn Júù gba orí ògiri Jerúsálẹ́mù àti ní èdè àwọn Júù? (Kíróníkà Kejì 32:18)
4. Irin iṣẹ́ oko wo ni a fi ń roko ní ìgbà ìjímìjí? (Áísáyà 7:25)
5. Orúkọ wo ni a fún àpò mímọ́ ọlọ́wọ̀ tí wọ́n ṣiṣẹ́ ọnà sí, tí Úrímù àti Túmímù wà nínú rẹ̀, tí olórí àlùfáà ń gbé sáyà nígbà tí ó bá wọ Ibi Mímọ́? (Ẹ́kísódù 28:29, 30)
6. Gẹ́gẹ́ bí òfin Ọlọ́run ṣe sọ, ó kéré tán, ẹlẹ́rìí mélòó ni a nílò láti fìdí ọ̀ràn kan múlẹ̀? (Hébérù 10:28)
7. Kí ni orúkọ jagunjagun Ísírẹ́lì tí ó pa Láámì, arákùnrin Gòláyátì? (Kíróníkà Kìíní 20:5)
8. Ta ni olórí àlùfáà tí ó pàṣẹ pé kí a pa Ọbabìnrin búburú náà, Ataláyà? (Àwọn Ọba Kejì 11:15, 16)
9. Kí ni Bíbélì sọ pé ẹnì kan lè ṣe fún “ojú” Jèhófà nígbà tí ó bá ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú? (Ẹ́kísódù 32:11, NW)
10. Èwo lára àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù ni ó ní orúkọ̀ tí ó túmọ̀ sí “Ire,” ní ìbámu pẹ̀lú igbe iré dé tí Léà ké nígbà tí a bí i? (Jẹ́nẹ́sísì 30:11)
11. Kí ni orúkọ òkè ńlá fíofío tí Sólómọ́nì kọ́ tẹ́ḿpìlì Jèhófà lé? (Kíróníkà Kejì 3:1)
12. Kí ni orúkọ oyè Jésù náà, “Kristi,” túmọ̀ sí? (Ìṣe 4:26)
13. Kí ni Jésù sọ pé a gbọ́dọ̀ ṣe “láti gba ẹnu ọ̀nà tóóró wọlé”? (Lúùkù 13:24)
14. Orúkọ wo ni a fún ohun tí Bíbélì ròyìn pé Ọlọ́run dá kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé? (Jẹ́nẹ́sísì 3:20)
15. Ní àtètèkọ́ṣe, ìdiwọ̀n wo ni Ọlọ́run ṣe nípa ọkàn-àyà aráyé? (Jẹ́nẹ́sísì 8:21)
16. Ọmọbìnrin ọba Mídíánì wo ni Fíníhásì pa, tí èyí sì fòpin sí ìpọ́njú tí Ọlọ́run mú wá sórí Ísírẹ́lì? (Númérì 25:15)
17. Kí ni Míkálì, aya Dáfídì, lò láti tan àwọn ìránṣẹ́ tí Sọ́ọ̀lù rán láti pa Dáfídì? (Sámúẹ́lì Kìíní 19:11-16)
18. Orí kí ni áńgẹ́lì keje da àwokòtò ìbínú Ọlọ́run rẹ̀ sí? (Ìṣípayá 16:17)
19. Èdè ọ̀rọ̀ wo ni a lò nínú Bíbélì láti tọ́ka sí àwọn ènìyàn tí wọn kì í ṣe ara àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? (Ẹ́sírà 10:2)
20. Ìrandíran Júdà wo, tí kò bí ọmọkùnrin, ni ó fi ọmọbìnrin rẹ̀ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Jááhà láti lè mú kí ìlà ìran rẹ̀ máa wà nìṣó? (Kíróníkà Kìíní 2:34, 35)
21. Kí ló sún Úsà láti gbá àpótí májẹ̀mú mú nígbà tí wọ́n ń gbé e lọ? (Kíróníkà Kìíní 13:9, 10)
22. Àkọsílẹ̀ kan ṣoṣo wo nínú Bíbélì ni ó ní í ṣe pẹ̀lú kìkì ìyanṣẹ́fún wòlíì kan láti kéde ìhìn iṣẹ́ ìdájọ́ ìparun fún ìlú ńlá kan tí kì í ṣe ti Ísírẹ́lì?
23. Kí ni ohun tí Ọlọ́run kò lè ṣe? (Hébérù 6:18)
24. Bí Jèhófà bá ń bù kúnni, kí ni kì í fi kún un? (Òwe 10:22, NW)
25. Àwọn ohun wo ni Dáfídì kó lẹ́bàá orí Sọ́ọ̀lù nígbà tí Sọ́ọ̀lù ń sùn, láti fi hàn pé òun kò jẹ́ pa á lára? (Sámúẹ́lì Kìíní 26:12)
26. Kí ni Jésù ṣe kí wọ́n má baà sọ ọ́ lókùúta? (Jòhánù 8:59)
Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
1. Ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀
2. Kàlẹ́ńdà
3. Láti dẹ́rù bà wọ́n, kí wọ́n sì mú wọn dààmú
4. Ọkọ́
5. Ìgbàyà
6. Méjì
7. Elíhánánì
8. Jèhóádà
9. Tù ú (NW)
10. Gáàdì
11. Òkè Ńlá Mòráyà
12. Ẹni Àmì Òróró
13. “Ẹ fi tokuntokun tiraka”
14. Éfà
15. “Ibi ni láti ìgbà èwe rẹ̀ wá”
16. Súúrì
17. Ère àti tìmùtìmù onírun ewúrẹ́
18. Afẹ́fẹ́
19. Àjèjì
20. Ṣéṣánì
21. Àwọn màlúù kọsẹ̀
22. Ìwé Jónà
23. Pa irọ́
24. Ìrora (NW)
25. Ọ̀kọ̀ kan àti ìgò omi kan
26. Ó fara pamọ́