ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 5/15 ojú ìwé 8-9
  • Ni Ọwọ́ Ọtun Ọlọrun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ni Ọwọ́ Ọtun Ọlọrun
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ni Ọwọ́ Ọtun Ọlọrun
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Kristi Wà Lọ́wọ́ Ọ̀tún Ọlọ́run
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Lójú Ọ̀nà Damásíkù
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Ǹjẹ́ Àwọn Tó Ń Ṣe Ohun Búburú Lè Yí Padà?
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 5/15 ojú ìwé 8-9

Igbesi-aye ati Iṣẹ-ojiṣẹ Jesu

Ni Ọwọ́ Ọtun Ọlọrun

TÍTÚ ẹmi mimọ jade ni Pẹntikọsti jẹ ẹri pe Jesu ti pada de ọrun. Iran ti a fifun ọmọ-ẹhin naa Stefanu ni kete lẹhin naa tun fi ẹri han pe oun ti de si ibẹ. Bi a ti nsọ okuta lu Stefanu fun ijẹrii igbagbọ rẹ, oun kigbe soke pe: “Wòó, mo ri ọrun ṣí silẹ, ati ọmọ eniyan [“Ọmọkunrin eniyan,” NW] nduro ni ọwọ ọtun Ọlọrun.”

Nigba ti o wa ni ọwọ ọtun Ọlọrun, Jesu duro de aṣẹ lati ọdọ Baba rẹ pe: “Iwọ jọba laaarin awọn ọta rẹ.” Ṣugbọn laaarin akoko naa, titi di igba ti oun yoo gbe igbesẹ lodi si awọn ọta rẹ, ki ni Jesu nṣe? Oun nṣakoso tabi jọba lori awọn ọmọ-ẹhin rẹ ti a fàmì ororo yan, ni titọ wọn sọna ninu igbokegbodo ijẹrii wọn ati mimura wọn silẹ lati di ọba àjùmọ̀jẹ́ pẹlu rẹ ninu Ijọba Baba rẹ nipa ajinde.

Fun apẹẹrẹ, Jesu yan Sọọlu (ti wa a mọ daradara lẹhin naa nipa orukọ Roomu rẹ, Pọọlu) lati ṣe òléwájú ninu iṣẹ sisọni di ọmọ-ẹhin ni awọn ilẹ miiran. Sọọlu jẹ onitara fun Ofin Ọlọrun, sibẹ oun ni a mú ṣìnà nipasẹ awọn aṣaaju isin Juu. Gẹgẹbi iyọrisi rẹ̀, kii ṣe kiki pe Sọọlu lọwọ si pipa Stefanu nikan ni ṣugbọn oun lọ si Damasku pẹlu iwe-aṣẹ lati ọwọ alufaa agba Kiafa lati mú awọn ọkunrin ati obinrin eyikeyi ti oun ri nibẹ ti wọn jẹ ọmọlẹhin Jesu pada wa si Jerusalẹmu labẹ ifaṣẹ ọba muni. Bi o ti wu ki o ri, nigba ti Sọọlu wà loju ọna, imọlẹ titan yoo kan kọmànà yi i ka lojiji, o si ṣubu lulẹ.

Ohùn kan lati orisun aiṣeefojuri kan beere pe, “Sọọlu, Sọọlu, eeṣe ti iwọ fi nṣe inunibini si mi?” Sọọlu beere pe, “Iwọ ta ni, Oluwa?”

Idahun naa wa pe, “Emi Jesu ni, ẹni ti iwọ nṣe inunibini si.”

Sọọlu, ẹni ti a ti bùfọ́jú lù nipasẹ imọlẹ agbayanu naa, ni Jesu sọ fun lati wọ Damasku lọ ki o si duro de awọn itọni. Lẹhin naa Jesu farahan ninu iran si Ananaya, ọkan lara awọn ọmọ-ẹhin rẹ. Nipa Sọọlu, Jesu sọ fun Ananaya pe: “Ohun eelo ni ọkunrin yii jẹ fun mi lati gbé orukọ mi lọ si iwaju awọn keferi, ati awọn ọba, ati awọn ọmọ Israẹli.”

Nitootọ, pẹlu atilẹhin Jesu, Sọọlu (ti a mọ nisinsinyi gẹgẹ bi Pọọlu) ati awọn ajihinrere miiran rí agbayanu aṣeyọri si rere ninu iṣẹ iwaasu ati kikọni wọn. Niti tootọ, ni nǹkan bi 25 ọdun lẹhin ifarahan Jesu si i loju ọna si Damasku, Pọọlu kọwe pe “ihinrere” naa ni a ti “waasu rẹ ninu gbogbo ẹda ti nbẹ labẹ ọrun.”

Lẹhin lila ọpọlọpọ awọn ọdun kọja sii, Jesu pese ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ awọn iran fun apọsteli aayo olufẹ rẹ Johanu. Nipasẹ awọn iran wọnyii ti Johanu ṣapejuwe ninu iwe Bibeli Iṣipaya, oun nitori eyi, wàláàyè lati ri ipadabọ Jesu ninu agbara Ijọba. Johanu wipe “ninu ẹmi” a gbe oun rin siwaju ninu akoko lọ si “ọjọ Oluwa.” Ki ni “ọjọ” yii?

Ikẹkọọ kínníkínní ti awọn asọtẹlẹ Bibeli, ti o ni asọtẹlẹ Jesu funraarẹ nipa awọn ọjọ ikẹhin ninu ṣipaya pe “ọjọ Oluwa” bẹrẹ ni ọdun ọlọrọ itan naa 1914, bẹẹni, laaarin iran yii! Nitori naa 1914 ni Jesu padabọ lọna aiṣeefojuri, laisi ipokiki itagbangba ti o si jẹ pe kiki awọn iranṣẹ rẹ oluṣotitọ ni wọn mọ ipadabọ rẹ. Ni ọdun yẹn Jehofa fun Jesu laṣẹ lati maa jọba laaarin awọn ọta rẹ!

Ni ṣiṣegbọran si aṣẹ Baba rẹ, Jesu gbá Satani ati awọn ẹmi-eṣu rẹ mọ kuro ni ọrun, ni títì wọ́n sisalẹ si ilẹ-aye. Lẹhin riri ki eyi ṣẹlẹ ninu iran, Johanu gbọ ohùn ti ọrun kan ti o pokiki pe: “Nigba yii ni igbala de, ati agbara, ati ijọba Ọlọrun wa ati ọla nla ti Kristi rẹ.” Bẹẹni, ni 1914 Kristi bẹrẹ sii ṣakoso gẹgẹ bi Ọba!

Iru ihinrere wo ni eyi jẹ fun awọn olujọsin Jehofa ni ọrun! A rọ̀ wọn pe: “Ẹ maa yọ̀, ẹyin ọrun, ati ẹyin ti ngbe inu wọn.” Ṣugbọn ki ni ipo naa fun awọn wọnni ti wọn wa lori ilẹ-aye? Ohùn naa lati ọrun nbaa lọ pe, “ègbé ni fun aye ati fun okun! Nitori Eṣu sọkalẹ tọ yin wa ni ibinu nla, nitori o mọ pe igba kukuru ṣaa ni oun ni.”

A wà ni saa akoko kukuru yẹn gan-an nisinsinyi. Awọn eniyan ni a nya sọtọ ni lọwọlọwọ yala lati wọnu aye titun ti Ọlọrun tabi lati jiya iparun. Otitọ naa ni pe, kádàrá tirẹ funraarẹ ni a npinnu nisinsinyi nipa bi iwọ ti dahun pada si ihinrere Ijọba Ọlọrun ti a nwaasu rẹ̀ yika ilẹ-aye labẹ idari Kristi.

Nigba ti yiya awọn eniyan sọtọ ba ti pari, Jesu Kristi yoo ṣiṣẹsin gẹgẹ bi Aṣoju Ọlọrun lati dá ilẹ-aye silẹ lominira kuro lọwọ gbogbo eto igbekalẹ awọn nǹkan ti Satani ati gbogbo awọn wọnni ti wọn tii lẹhin. Jesu yoo ṣaṣepari imukuro gbogbo iwa buruku yii ninu ogun ti a npe ni Ha-magẹdọn, tabi Amagẹdọn ninu Bibeli. Lẹhin naa, Jesu, ti o jẹ ẹni giga julọ ni agbaye tẹle Jehofa Ọlọrun funraarẹ, yoo gbá Satani ati awọn ẹmi-eṣu rẹ mú yoo si dè wọn fun ẹgbẹrun ọdun ninu “ọgbun,” iyẹn ni ipo alaiṣiṣẹ bi oku. Ise 7:55-60; 8:1-3; 9:1-19; 16:6-10; Saamu 110:1, 2; Heberu 10:12, 13; 1 Peteru 3:22; Luuku 22:28-30; Kolose 1:13, 23; Iṣipaya 1:1, 10; 12:7-12; 16:14-16; 20:1-3; Matiu 24:14; 25:31-33.

◆ Lẹhin ti Jesu goke lọ si ọrun, ipo wo ni a ti ri i, ki ni o si nduro de?

◆ Lori awọn ta ni Jesu nṣakoso lẹhin ti o goke re ọrun, bawo si ni a ṣe fi iṣakoso rẹ han?

◆ Nigba wo ni “ọjọ Oluwa” bẹrẹ, ki ni o si ṣelẹ ni ibẹrẹ rẹ?

◆ Iṣẹ iyasọtọ wo ti ntẹsiwaju lonii ni o kan olukuluku ẹnikọọkan wa, lori ipilẹ wo si ni a fi nṣe iyasọtọ naa?

◆ Nigba ti iṣẹ iyasọtọ naa ba pari, awọn iṣẹlẹ wo ni yoo tẹle e?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́